Sanwo-Olu buwọ́lu sísan ₦5m fún ọkùnrin kan tàwọn ọlọ́pàá fìyà jẹ lásìkò #Endsars

Adedotun Clement lásìkò táwọn ọlọ́pàá fìyà jẹ nígbà náà

Oríṣun àwòrán, Twitter

Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti buwọ́lu sísan mílíọ̀nù márùn-ún náírà gẹ́gẹ́ bí owó gbà má bínú fún dẹ́rẹ́bà kan, Adedotun Clement lórí ọ̀rọ̀ #Endsars.

Ní ọdún 2021, nígbà tí wọ́n ń ṣèrántí ọdún kan #Endsars ni Clement kó sí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá àtàwọn òṣìṣẹ́ Lagos State Neighbouhood Safety Agency tí wọ́n sì dá bátànì ìyà fún-un ní Toll-Gate Lekki.

Ṣaájú ni ilé ẹjọ́ gíga tí ìjọba àpapọ̀ ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹta ọdún 2023 ti dájọ́ pé kí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko àti iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà san mílíọ̀nù márùn-ún náírà fún Clement gẹ́gẹ́ bí owó gbà mábínú fún ìyà tí wọ́n fi jẹ́ lásìkò náà.

Ilé ẹjọ́ tún bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn ọlọ́pàá àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Eko ṣe fìyà jẹ arákùnrin náà.

Clement, tó jẹ́ awakọ̀ ló ń gbé èrò láti Island lọ sí agbègbè Mainland ní ìpínlẹ̀ Eko ní ogúnjọ́ oṣù Kẹwàá ọdún 2021 nígbà tó kó sọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Eko lásìkò tí àwọn kan ń ṣe ìwọ́de láti ṣèrántí ọdún kan #Endsars.

Níbẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá náà àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Eko ki bẹ́ńdẹ́ ìyà fun tí wọ́n sì tún fín tajútajú si lójú.

Adájọ́ Ambrose Lewis-Allagoa nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ ní àwọn ọlọ́pàá àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Eko tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn Clement lójú mọ́lẹ̀ nítorí náà kí wọ́n san mílíọ̀nù márùn-ún náírà fún-un.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdàjọ́ ọ̀hún, gómìnà Babajide Sanwo-Olu ní láìpẹ́ yìí ni òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́ sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé ní kíákíá ni àwọn máa san owó náà.

Sanwo-Olu nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí Twitter rẹ̀ ní òun ti dárí agbẹjẹ́rò àgbà ìpínlẹ̀ Eko láti ṣèpàdé pẹ̀lú Clement kí wọ́n sì san owó rẹ̀ fún.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba Eko ti pé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tako ìdájọ́ náà síbẹ̀ òun ìbọ̀wọ̀ fún òfin àti pé òun máa tẹ̀lé ìdàjọ́ ilé ẹjọ́.

Ó fi kun pé bíbọ̀wọ̀ fún òfin jẹ́ nǹkan tí òun kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú rárá, tó sì kan sáárá sí ọmọkùnrin náà bó ṣe fi ìlànà òfin bèèrè fún ẹ̀tọ́ rẹ̀.

Bákan náà ló ní òun ní ìfarajìn sí bíbọ́wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko.