NÍ YÀJÓYÀJÓ Èèyàn 26 ló ti pàdánù ẹ̀mí wọ́n nínú ìṣẹ̀lẹ̀ Ìjì lílé ní Amẹrika

Copyright: Reuters

Okere tan eeyan mẹrindinlọgbọn
lo ti padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ iji lile
to waye ni ilu Mississippi ati Alabama, lorilẹede Amẹrika.

Awọn oṣiṣẹ pajawiri ni
agbegbe mejeeji ti iji lile naa ti ṣọṣẹ ju, ni wọn ti n ṣa ipa wọn lati dola ẹmi awọn eniyan ni agbegbe naa.

Bakan naa ni awọn gomina ipinlẹ naa ti kede nkan ofararọ ni awọn agbegbe ti isẹlẹ iji lile naa ti waye.

Ni agbegbe
Rolling Fork ni a ti ri awọn ọkọ ti iji lile ti ba jẹ,akufọ gilasi,orule ti ategun gbe palapala
ara ile lo, wa ni gbogbo opopona ilu ọhun.

Lara awọn to ba
ile iṣẹ Akọroyin BBC sọrọ ni ori lo ko awọn yọ,nitori inu baluwẹ ni awọn sa
pamo si nigbati iji lile naa bẹrẹ .

Lara awọn ilu to
wa ni igbẹriko to ni olugbe ẹgbẹrun meji ni opo ile ti wo palẹ nibẹ.

Iji lile na lo bẹrẹ
ni aarin oru nigba ti awọn eeyan n sun lọwọ, ti wọn o si gbọ nigba ti aago ikilọ n dun.

Francisco
McKnight sọ fun ile iṣẹ BBC wi pe ariwo aago ikilọ to dun lo ta oun ji, lai jẹ bẹẹ o ṣeeṣe ki oun ma ye, nitori gbogbo ile oun ni afẹfẹ iji lile na gbe
lo.

Iji lile na lo fẹ
laarin isẹju marun si mẹwa to si fa ile
Fransisco ya.

Fransisco ti n gbe ninu ọkan lara yara ti ijọba pese fun awọn ti ko
nile lori lẹyin isẹlẹ naa.

Gomina Mississippi, Tate Reeve nigba ti oun se abẹwo si agbegbe Silver City ati Winona ni, isẹlẹ
iji lile yii jẹ nkan to bani lọkan jẹ to si seleri lati mu ohun iranwọ adoju tofo wa fun
awọn to padanu dukia wọn.

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden ni ijọba yoo pese iranwọ fun awọn to padanu dukia wọn ni kiakia.