Ta ló ni ₦9bn tí EFCC ká mọ́ ọwọ́ olùṣirò owó àgbà l‘Oyo?

Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlọgbọn osu keji ọdun 2022 niroyin fidi rẹ mulẹ pe awọn agbofinro lati ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ ni Naijiria, EFCC, wa fi panpẹ ofin gbe olusiro owo agba nipinlẹ Oyo, ọgbẹni Gafar Bello, ni ọfiisi rẹ ni sẹkitariati ijọba nipinlẹ Ọjọ.

Iroyin naa tun fidi rẹ mulẹ pe ẹka ajọ naa to wa nilu Ibadan ni wọn ti ranṣẹ wa mu u ki wọn to tu u silẹ lọjọ Aje.

Ki ni olusiro owo agba ni Oyo se ti EFCC se mu:

Lara awọn iroyin akọkọ to jade ni ti iwe iroyin ori ayelujara kan to ni pe biliọn mẹsan owo ijọba ibilẹ ti oluṣiroowo agba naa pa mọ abẹ igbanu rẹ ni awọn oṣiṣẹ EFCC fi wa gbe e ati pe owo ti wọn re lori awọn ijọba ibilẹ lowo naa.

Iwe iroyin ori ayelujara naa ṣalaye pe ninu iwadii awọn ni oṣiṣẹ kan ni ọfiisi oluṣiroowo agba naa lo lu awo ọrọ naa fun awọn pe ” owo naa dabi owo ti wọn n rejọ fun nina lasiko eto idibo apapọ ọdun 2023.”

Iroyin yii ko se fọkan le nitori aile e darukọ ni san an ẹni to ṣoju rẹ, ṣugbọn ohun kan ti BBC le fidi rẹ mulẹ ni pe, EFCC gbe olusiro owo agba nipinlẹ Ọyọ, wọn si ti fi silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

EFCC n dun mọhuru mọ awọn oṣiṣẹ ijọba wa lasan ni – Ijọba ipinlẹ Ọyọ

Nigba ti ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo fi sọrọ lori rẹ, O ni ọrọ naa kii ṣe ọrọ isinyi rara ati pe ọrọ ọjọ to ti pẹ ni ti ajọ EFCC ti wa n ko awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ laya jẹ lati lee dukoko mọọ.

Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna feto iroyin nipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Wasiu Ọlatubọsun fi sita, eyi to tẹ BBC lọwọ, ijọba ipinlẹ Ọyọ ni

“gbọnmọgbọnmọ idunkokomọni Ajọ EFCC mọ oluṣiroowo agba nipinlẹ Ọyọ atawọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ miran tako ofin, ijọba si ti n fi ọrọ naa sun niwaju ile ẹjọ lọwọ yii.”

O ni lati nkan bi ọdun kan sẹyin lawọn oṣiṣẹ ajọ EFCC ti n tẹ ipinlẹ Ọyọ atawọn oṣiṣẹ rẹ lọfun lati gba awọn iwe ijọba ro da lori bi wọn ṣe n pin owo ati bi wọn ṣe n na owog ogbo tiri kan owo eto abo, security votes ti ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa ti buwọlu fun nina labẹ ofin iṣuna tipinlẹ Ọyọ.

“Wọn n ṣe eyi pẹlupẹlu bi ileẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria ti ṣe gbe idajọ kalẹ pe ajọ EFCC ko laṣẹ lati yọ suti eti si ohun ti ko ba jọ mọ ikowojẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nibo lọrọ de duro bayii?

Wọn ti tu Ọgbẹni Gafar Bello silẹ lọjọ Aje, ọjọ kejidinlogbon osu keji ọdun 2022.

Sugbọn ijoba ipinlẹ Ọyọ ni oun ti gba ile ẹjọ giga apapọ lọ lati pe “ẹjọ laa-han-mi” lori ibi ti agbara ajọ EFCC mọ lori isuna ipinlẹ ati agbara owoona fun eto abo, security votes to wa lọwọ gomina.

Bakan naa ni kọmiṣọna feto iroyin, Wasiu Ọlatubosun tun ṣalaye pe nibi igbẹjọ naa to waye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kini oṣu kẹta ọdun 202w ni adajọ ti paṣẹ ki wọn tẹwọ gba iwe ipẹjọ wọn ni ita gbangba.