Ewé sunko fàwọn oníjìbìtì ayélujára mẹ́ta, wò dúkìá tí wọ́n jọwọ fún ìjọba

Awọn onijibiti ori ayelujara

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ile ẹjọ giga niluu Ibadan ti ran awọn onijibiti ori ayelujara mẹta taa mọ si ọmọ yahoo yahoo lẹwọn lori ẹsun gbajuẹ ori ayelujara.

Awọn mẹtẹẹta naa ni Elegushi Mumuni Abiodun, Abdullahi Umar Faruq ati Abiola Gabriel Oladimeji.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn wa ni sise atako si ofin orileede Naijiria to tako iwa gbajuẹ ori ayelujara pẹlu ijiya to tọ labẹ ẹsun yi.

Awọn afẹsunkan wọn yii gba pe awọn jẹbi ẹsun ti ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, EFCC fi kan wọn.

Bẹẹ naa ni agbẹjọro ijọba rọ adajọ lati gbe idajọ to yẹ kalẹ fun wọn.

Nitori eyi, adajọ Agomoh ni ki wọn ran arakunrin Abiodun lẹwọn osu meje, Faruq ni osu mejidinlogun ki Oladimeji si lọ fi asọ penpe roko ọba fun osu mẹsan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Owo itanran ti ileẹjọ ni ki wọn san:

Ile ẹjọ giga naa pasẹ ki Elegushi san owo itanran ẹgbẹta din aadọta dọla, ko si jọwọ foonu iPhone X rẹ fun ijọba Naijiria.

Ni ti Abdullahi, ijọba ni ko san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira fun ẹni to lu ni gbajuẹ.

Yatọ si eleyi, wọn ni ko jọwọ foonu iPhone11 Pro Max rẹ ati N1, 679, 845.44 to wa ninu akoto owo rẹ fun ijọba apapọ Naijiria.

Ẹwẹ, Abiola la gbọ pe wọn ni ko jọwọ ẹẹdẹgbẹta dọla pada fun ẹni to lu ni gbajuẹ ko si jọwọ foonu iPhone 11 Pro rẹ fun ijọba apapọ Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Gbajuẹ ori ayelujara Yahoo Yahoo ati Naijiria:

Ninu awọn to n tabuku orileede Naijiria ni iwa jibiti ori ayelujara taa mọ si yahoo yahoo.

Ojojumọ ni awọn to n hu iwa yii n pọ si, ti ọpọ lawujọ si ti n ke gbajare si awọn obi ati ijọba lati wa wọrọkọ fi sada lori isẹlẹ yii.

Pupọ ninu awọn to n kopa ninu aidaa yii jẹ ọdọ to si se pe wọn ko bikita nipa ẹni ti wọn ba lu ni gbajuẹ.

Bi a ko ba gbagbe, ogbologbo oni jibiti ayelujara Ramoni Abbas taa mọ si Hushpuppi ati awọn ikọ rẹ kan lọwọ agbofinro FBI tẹ nilu Dubai laipẹ yi.

Toun ti bi awọn wọn yi se ko si panpẹ agbofinro, ajọ EFCC si n fojojumọ kede pe awọn ọdọ ko dẹyin ninu iwa ibanilorukọ jẹ yi.

Amin iyasọtọ kan

Èèmọ̀ wọ̀lú! Ọmọ ọdún méjìdínlógún jí ènìyàn gbé

Blessing

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọwọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Adamawa ti tẹ ọmọbìnrin, ọmọ ọdún méjìdínlógún tó fẹ́ ta ọmọ tó jí gbé ní ìpínlẹ̀ náà.

Ọmọbìnrin náà, Blessing John tó ń gbé ní ìjọba ìbílẹ̀ Michika jẹ́wọ́ pé òun jí Elkanah Samuel, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án gbé pẹ̀lú èròńgbà láti tà á fún ẹnìkan tó ti bá sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀.

Blessing ní òun jí Elkanah gbé nítorí tí òun fẹ́ tà á sí Mubi, tó jẹ́ ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Adamawa bákan náà, láti fi owó rẹ̀ ra ọkọ̀ àti ilé.

Ìròyìn ní láti bí ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni àwọn òbí Elkanah ti kéde pé àwọn ń wá Elkanah tí gbogbo ìgbìyànjú láti rí i jásí pàbó kí wọ́n tó rí lọ́jọ́ kọkànlélógún oṣù kejì níbi tí Blessing John ti fẹ́ tà á ní Mubi.

Báwo ni ọwọ́ ṣe tẹ Blessing?

Blessing, gẹ́gẹ́ bí àlàyé rẹ̀, ti parí ìdúnàdúrà pẹ̀lú ẹnìkan ní Mubi wí pé òun fẹ́ ta Elkanah fún un ṣùgbọ́n tí nọ́mbà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ẹni náà kò lọ mọ́ nígbà tí òun máa fi dé Mubi pẹ̀lú ọmọ lọ́wọ́.

Ó ní òun bá wọ kẹ̀kẹ́ Unguwan Kara ní Mubi bákan náà níbi ti ẹni náà júwe fún òun wí pé òun ń gbé ṣùgbọ́n tí òun kò tún dá ibẹ̀ mọ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bákan náà ló ní nígbà tí òun kò rí ẹni tó gbé òun dé Mubi ní òun wá lọ bá ọkùnrin kan láti bèèrè bóyá ó mọ ẹni tí òun ń wá tí òun sì ṣàlàyé fún ọkùnrin náà pé ẹni tí òun ń wá fẹ́ ra ọmọkùnrin tó wà lọ́wọ́ òun ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọkùnrin yìí lówá ké gbàǹjarè sí àwọn ènìyàn tí wọ́n sì fi ẹjọ́ náà lọ sùn ní àgọ́ olọ́pàá tó wà ní Mubi kí wọ́n tó ráńṣẹ́ sí àgọ́ ọlọ́pàá Michika níbi ti wọ́n ti fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kini o sele ni aago olopaa?

Nígbà tí wọ́n gbé Blessing àti Elkanah dé àgọ́ ọlọ́pàá Michika, Blessing tó jẹ́ alábágbé àwọn òbí Elkanah jẹ́wọ́ pé òun jí ọmọ náà gbe láti tà á ni.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Adamawa, Suleiman Nguroje ní [wádìí ti ń lọ lọ́wọ́ lórí ọmọbìnrin náà tí àwọn yóò si gbe lọ ilé ẹjọ́ ní kété tí àwọn báti parí ìwádìí.