Supreme Court ló máa bá wa yanjú ẹ nítorí màá gba ẹ̀tọ́ mi padà – Oyetola

Oyetola àti Adeleke

Oríṣun àwòrán, Collage

Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola ti rọ àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ní ìpínlẹ̀ Osun láti fọkàn balẹ̀ lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Oyetola ní òun ní ìgbàgbọ́ tó dúró ṣinṣin nínú Ọlọ́run pé òun ṣì máa padà sípò gómìnà Osun nítorí òun yòó gba ẹ̀tọ́ òun padà.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kẹta, ọdún 2022 ni ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ̀rùn ní ìdájọ́ tí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò gómìnà Osun kò tọ̀nà.

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní Ademola Adeleke ló jáwé olúborí ìbò gómìnà Osun tó wáyé ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje ọdún 2022.

Ṣaájú ni ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò dájọ́ pé Gboyega Oyetola ló jáwé olúborí ìbò náà, tí wọ́n sì ní kí Ademola Adeleke yẹ̀bá kúrò lórí àga náà àmọ́ tí gómìnà Adeleke pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn láti fi pe ìdájọ́ náà níjà.

Gómìnà àná náà nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn gbé kalẹ̀ ní òun kò ní jẹ́ kí ìdájọ́ náà kó ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá òun láti tẹ̀síwájú láti bèèrè fún ẹ̀tọ́ òun.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Oyetola, Ismail Omipidan fi léde ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn gbé kalẹ̀ kò lọ bí àwọn ṣe rò, òun ṣì ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀ka òfin orílẹ̀èdè yìí.

Ó fi kún un pé “A ti gbọ́ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn àmọ́ a ò tíì rí ẹ̀dà rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí à ń gbọ́ fi yé wa pé a ní ẹjọ́ táa lè gbé síwájú ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ìyẹn Supreme Court”.

“Mo ni ìgbàgbọ́ pé dídùn ni ọsàn máa so fún wa tí màá sì gbà ẹ̀tọ́ mi padà ní ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ”, Oyetola sọ bẹ́ẹ̀.

Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn?

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, ADEMOLA ADELEKE/FACEBOOK

Abala kejì lórí ìfaǹfà tó máa ń wáyé lẹ́yìn ètò ìdìbò ní ilé ẹjọ́ ni pípe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lẹ́yìn tí olùdíje kan kò bá gba èsì tí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò bá gbé kalẹ̀.

Ní ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola ló wọ́ gómìnà Ademola Adeleke lọ sí iwájú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun kò gbà èsì ìbò tí INEC kéde pé ó gbé Adeleke wọlẹ́ gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Osun.

Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ti ṣaájú dájọ́ pé Oyetola ló gbégbá orókè ìbò náà lòdì sí ìkéde INEC tó kéde Adeleke gẹ́gẹ́ bí ẹni tó bórí ìbò nítorí dídi àwọn àlékún ìbò wáyé ní àwọn ibùdó ìdìbò kan.

Àmọ́ ìdájọ́ yìí kò tẹ́ Adeleke lọ́rùn tí òun náà sì gba ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lọ.

Ní ọjọ́ Ẹtì ni ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà èyí ti adájọ́ Mohammed Shuaibu ṣaájú rẹ̀ gbé ìdájọ́ Tribunal sí ẹ̀gbẹ́ kan, tó sì kéde pé Adeleke ni ojúlówó gómìnà tí àwọn ènìyàn dìbò yàn.

Oyetola àti Adeleke

Oríṣun àwòrán, Collage

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní kò yẹ kí Tribunal gbé ìdàjọ́ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan bíkoṣe láti ṣe àyẹ̀wò BVAS lórí èsì ìbò náà nítorí òhun ló ṣe é fìdí rẹ̀ múlẹ̀ dáádáa.

Abala mẹ́ta ni pípe ẹjọ́ lẹ́yìn ìbò máa ń pín sí: Tribunal, pípe ẹ̀jọ́ kòtẹ́milọ́rùn àti lílọ sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ.

Ipele méjì sì ti wáyé lórí ìbò gómìnà Osun, ohun tó kàn ní kí ẹni tí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kò bá dùn mọ́ gba ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lọ.

Abiodun Layonu tó jẹ́ agbẹjẹ́rò Oyetola ní ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti gbé ìdájọ́ ti wón kalẹ̀ àmọ́ àwọn ń dúró láti gba ẹ̀dá ìdájọ́ náà kí àwọn tó gbé ìgbésẹ̀ tó kàn.

Layonu ní ó dá òun lójú pé pẹ̀lú bí àwọn ṣe borí nínú àwọn ẹjọ́ kan tí àwọn pé, àwọn kò ní dúró nítorí àwọn mọ̀ pé àwọn ní ẹjọ́ tó dára láti gbé síwájú ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ.