Ṣé lóòótọ́ ni pé omi mímu kò já ààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn kan?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

  • Author, Akinlabi Afolabi
  • Role, Broadcast Journalist

Bi oṣu Ramadan ṣe wọle de yii jẹ ohun idunu fun ọpọlọpọ musulumi kaakiri agbaye pe oṣu alapọnle ti ọdun yii wọle tọ wọn wa.

Bi awẹ naa ṣe wa bẹrẹ, ọpọlọpọ ibeere lo ti jẹyọ lori awọn nnkan ti eeyan, paapaa awọn musulumi gbọdọ lodi si lasiko awẹ lati le gba laada to pe lati ọwọ Ọlọrun.

Lara awọn ibeere naa ni , “N jẹ mimu omi ba awẹ jẹ?”, “N jẹ mo lẹtọ lati sun mọ iyawo mi tabi ọkọ mi lasiko awẹ? ati awọn ibeere miiran to ti n jẹyọ.

Ileeṣẹ BBC Yoruba kan si agba alfa ninu ẹsin Islam lati ṣe idahun si awọn ibeere naa.

Ninu alaye rẹ, Sheikh Taofeek Akewugbagold ni ọkan lara awọn nnkan ti Islam pa laṣẹ ni pe ki awọn musulumi ma ṣe ni fifi nnkan si ẹnu de ọna ọfun rara lasiko awẹ.

Akewugbagold ni ti eniyan ba ti fi nnkan sẹnu lati jẹ tabi mu ti ba awẹ jẹ lẹsẹkẹsẹ.

O ni irọ ni pe omi mimu ko ba awẹ jẹ lasiko awẹ ti awọn eeyan kan n sọ kiri.

“Ohunkohun to ba de ibi gogongo ni awọn wakati ti a fi n gba awẹ, ni yoo ba awẹ jẹ.”

“Yala omi ni tabi ounjẹ, a ko ni anfani lati jẹ ki ohunkohun kọja si ọna ọfun wa.”

“Nnkan keji to ba awẹ jẹ ni nnkan ti a ba fi abẹ ṣe”

Sheikh Taofeek Akewugbagold tẹsiwaju pe nnkan keji to ba awẹ musulumi jẹ lasiko awẹ ni ohun ti ẹni to n gba awẹ ba fi abẹ rẹ ṣe lasiko ti awẹ n lọ lọwọ.

O ni ẹsin Islam lodi si ki tọkọtaya sun mọ ara wọn ni ọsan gangan lasiko awẹ nitori ẹṣẹ nla ni ṣugbọn wọn ni anfani lati sun mọ ara wọn lẹyin ti wọn ba ṣinu lalẹ.

Bakan naa ni Akewugbagold ni nnkan to wa ninu ki tọkọtaya maa ba ara wọn lopọ lẹyin awẹ ni pe o ṣeeṣe ki awẹ maa gbo ọkọ lasiko awẹ nitori nnkan to fi ara rẹ ṣe lẹyin awẹ.

“Ẹṣẹ nla lo wa ninu ki ọkunrin ati obinrin ba ara wọn lopọ lasiko awẹ, nnkan ti ofin Ọlọrun sọ niyẹn.

“Ẹnikẹni to ba ṣe bẹẹ, ọsu mẹji ati ọjọ kan ni yoo fi gba awẹ miiran pada.”

“Ikẹta ni nnkan ti a ba fi oju wo”

Akewugbagold ni o ti di dandan fun awọn musulumi lati ṣọ ohun ti wọn maa n fi oju wọn wo lasiko aawẹ nitori o ṣeeṣe ki wọn fi oju ri nnkan ti yoo ba awẹ wọn jẹ.

O ni ki ọkunrin maa wo obinrin tabi ronu nipa obinrin titi abẹ rẹ yoo fi tutu tabi ki obinrin naa ma ronu nipa ọkunrin titi abẹ yoo fi tutu ni o jẹ ohun to ba awẹ jẹ.

“Awẹ ọjọ yẹn ti bajẹ, iru eeyan bẹẹ le ma ba awẹ ọgọta pada sugbọn yoo gba ẹyọ kan yẹn pada, ko si gbọdọ jẹun.