‘Dírẹ́bà ọkọ̀ BRT tó pa èníyàn mẹ́fà ní Eko yóò jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìpànìyàn’

Aworan

Ijoba ipinlẹ Eko ti gbe dirẹba ọkọ BRT to pa eniyan mẹfa nipinlẹ Eko lọ si ileẹjọ.

Direba ọkọ naa lo lọ kosi ẹnu ọkọ oju irin ni agbegbe Ikẹja nilu Eko, ti eniyan mẹfa si ku ninu ijamba naa, amọ eniyan mẹrindinlọgọrun lo fi arapa.

Ọkọ ojurin naa ni o gbe ọkọ BRT naa ha ẹnu pẹlu awọn to wa ninu ibẹ titi to fi de agbegbe Sogunlẹ ni Ikeja.

Ẹka eto idajọ nipinlẹ Eko ninu atẹjade ti wọn fi lede ni gbogbo eto ti to lati gbe oluwaseun Osibanjo lọ si ileẹjọ lori ẹsun ipaniyan ati awọn ẹsun oniga mẹrindinlogun miran ti wọn fi kan an.

Ẹka eto idajọ naa ni lẹyin ti awọn wo iṣẹlẹ naa finifini ni awọn ri pe dirẹba gbọdọ foju wina ofin.

Ẹsun oniga mẹrindinlogun ni yoo koju, mẹfa fun ipaniyan ati mẹwaa fun ṣiṣe eniyan leṣe yanna-yanna.

Awọn ẹsun naa si tako ẹka Sections 224 and 245 ti ofin to de iwa ọdaran ni ipinlẹ Eko, ti ọdun 2015.

Amọ ẹka idajọ naa ni igbẹjọ rẹ ko ni bẹrẹ ni kiakia nitori oun naa farapa ninu ijamba ọkọ naa.

Ijọba ni were ti ara rẹ ba ti da ni yoo bẹrẹ igbẹjọ ọhun.