Ìjọba Nàìjíríà gbọ́dọ̀ tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ Sunday Igboho, Nnamdi Kanu àti gbogbo àjìjàngbara tí wọ́n fìyà jẹ- Sowore

Aworan Sowore, Igboho ati Nnamdi Kanu

Ajafẹtọmọniyan ati oloṣelu lorileede Naijiria ni Omoyele Sowore.

Oni pe oun ko ṣe ipolongo tabi dibo fun oloṣelu kankan ri afi ara oun lọdun 2019.

O fidi ọrọ yii ati awọn ọrọ mii to ni ṣe pẹlu ọrọ oṣelu Naijiria mule ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Naijiria Punch.

Sowore sọ pe oun ko ṣẹṣẹ bẹrẹ ipolongo iṣejọba lọna to tọ ni Naijiria ati pe ko si ootọ ninu ọrọ tawọn kan n gbe kaakiri pe ija lode torin fi di owe laarin oun ati ijọba Buhari.

Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu

Ni idahun si ibeere pe ki lo ro pe ijọba apapọ Naijiria le ṣe lati yanju yanju aawọ to n waye lori awọn ajijangbara bi Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu to wa ni ahamọ ni Sowore fesi.

Sowore ni Ijọba gbọdọ tọrọ aforijin lọwọ wọn, wọn si gbọdo tu wọn silẹ ni kiakia.

O ni ẹtọ wọn ni lati beere fun iṣejọba arawọn ati pe ijọba Naijiria ko lẹtọ̀lati fi wọn si ahamọ tabi ko fiya jẹ wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kini Sowore tun so ninu ifọrọwanuilẹ́nuwo náà?

Oludije ipo aarẹ lọdun 2019 yi sọ pe oun ko fi igba kankan ṣe ipolongo fun aarẹ Buhari ati pe itako ijọba toun n se ko ṣẹṣẹ bẹrẹ lasiko ijọba Buhari.

O ni pe: ”Nigba ti Obasanjo wa nibẹ to fẹ fi ọgbọn ṣe saa kẹta; Mo tako o.

Mo tun tako ijọba Jonathan nigba ti oun naa ko ṣe ohun to yẹ.

Koda nigba ti Yara Adua ati ijọba ologun Babangida ti ko fẹ gbe ijọba kalẹ fun MKO Abiola, mi o dakẹ’.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọgbẹni Sowore sọ pe oun ko fi igba kankan polongo idibo fun aarẹ kankan ni Naijiria bi kii ba ṣe igba toun funra rẹ dije dupo aarẹ Naijiria.

”Oludije kan ṣoṣo ti mo polongo lati gba ti mo tidaye ni ara mi lọdun 2018 si 2019.

Bẹẹ mi o dibo fun ẹlomiran ri.

Lati igba ti mo ti daye, 2019 ni igba akọkọ ti maa dibo.

Mo si dibo fun ara mi ni”.

Kini Sowore tun so lori ọ̀rọ̀ Igboho ati Nnamdi Kanu?

Omoyele Sowore tun tesiwaju pe:

”Ijọba kan n poori kaakiri ni ti wọn si ro pe fifi Kanu ati Igboho si ahamọ bi wọn ṣe ṣe fun emi naa le jẹ ki ipe fun iyipada ma waye.”

O ni o yẹ ki ijọba pe gbogbo awọn ti ọrọ kan yi si ipade tubi n nubi nitori lilo ipa ko le jẹ ki eeyan jẹ ọmọ orileede Naijiria tabi ko ni oun kọ fẹ jẹ bẹ mọ.

”Iṣedede nikan lo le mu ki eyi waye.Bi ko ba si iṣedeede,ki ẹ pami, ki pa Igboho tabi Kanu, awọn ọmọ ogun mii yo gbori dide ko si si nkan ti ijọba le ṣe si”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ta ni Omoyele Sowore?

Ajafẹtọmọniyan to jẹ gbajugbaja ni Omoyele Sowore jẹ ni Naijiria. Oun ni oludasilẹ ipe fun igbajọba taa mọ si #RevolutionNow.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Omoyele jẹ alaṣẹ ileeṣẹ iroyin taa mọ si Sahara Reporters ṣaaju ko to gbe apoti ibo lati dije ipo aarẹ Naijiria lọdun 2019 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC.

Lọpọ igba ni Sowore ati awọn alaṣẹ Naijiria ti n figa gbaga ti itimọle ati idunkoko si a maa waye lati ọwọ awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria, DSS.

Wọn ba ṣe ẹjọ nigba kan ri ṣugbọn adajọ pada ni ki wọn tu silẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Laipẹ yi ni awọn to wọ aṣọ bi agbofinro tun mu ni Abuja lori ẹsun ti wọn ko darukọ.

A gbọ pe wọn gbe lọ si ahamọ awọn ọtẹlẹmuyẹ DSS tawọn eeyan mọ si Abbattoir ni Abuja.