Ọmọ ọ̀dọ̀ àti Dẹ́rẹ́bà fi àpólà igi, bàtà àti ‘Plier’ pa tọkọtaya òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì l’Eko

Femi ati Funmi Egbeoluwa

Oríṣun àwòrán, Femi Egbeoluwa

Ọpọlọpọ iwadii lo tí jẹyọ lori bí awọn abanisisẹ ṣe ṣekupa tọkọtaya kan, Femi Egbeoluwa ati Iyawo rẹ Funmi nile wọn.

Dẹrẹba awọn oloogbe naa si lo fi ara rẹ kalẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa lọsẹ to kọja lẹyin to ni oun ni oun pa tọkọtaya naa.

Agbegbe Afefolu, Allen Avenue ni ikeja nipinlẹ Eko ni isẹlẹ naa ti waye.

Dẹrẹba naa lo ti kọkọ na papa bora lẹyin to lẹdi apo pọ pẹlu ọkan lara awọn ọmọdọ wọn lati ṣekupa tọkọtaya naa.

Isẹlẹ naa lo waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹta ọdun 2023 lasiko ti tọkọtaya naa n mura lati lọ oke okun fun ayẹwo ìlera ọkọ, eyiun Femi.

Ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ti ni awọn ko ti le pe Dirẹba naa ni afurasi nitori iwadi si n lọ lọwọ.

Iwadii Ọlọpaa saaju tí fihan pe owo to to ẹgbẹrun marun-un owo ilẹ okere to wa fun eto ayẹwo ìlera Femi lo ti di awati.

“Ọmọ wọn to fẹ gbe wọn lọ papa ofurufu lo ri oku wọn”

Ọkan lara awọn mọlẹbi Egbeoluwa lo kede pe Dẹrẹba naa ti fara rẹ kalẹ fun Ileeṣẹ ọlọpaa lọsẹ to kọja.

“Dẹrẹba kọkọ lọ sí ọfisi ẹgbọn mi, ko ri ẹnikẹni lati ibẹ lo gba lọ ileeṣẹ ọlọpaa lati fara rẹ kalẹ.

“Awọn tọkọtaya yìí ni ko ni ọmọ kan kan layika wọn nitori awọn ọmọ tí dagba tí onikaluku si ti n da gbe.

“Ọmọ wọn to fẹ gbe wọn lọ papa ofurufu wa ṣawari wọn níbi tí isẹ ibi naa ti waye.”

“Igi apola ni wọn fọ mọ Funmi to jẹ iyawo lori”

“Iroyin ti a gbọ nipe awọn kọlọransi ẹda naa kọkọ kọlu Funmi to jẹ iyawo, wọn fọ apola igi mọ lori, kí wọn to fi Plier ṣe ni ijamba fun ọkọ.

“Lẹyin ni wọn lọ soke ile wọn lati lọ kọlu ọkọ, ẹni tí ko lagbara lati ba wọn ja nitori àìlera rẹ.

“Bakan naa ni wọn kọlu ọmọọdọ miiran sugbọn to sì wa laye ntiẹ.

“Nigba to taji, ni ọmọ ọdọ ti wọn se lese naa mu orukọ Dirẹba bọ ẹnu “

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ti fìdí iṣẹlẹ naa ati pe Dirẹba naa ti fara rẹ kalẹ tí iwadi sì ti bẹrẹ.

“Dẹrẹba ti wa ni atimọle ni Yaba sugbọn a ko ti le pe ni afurasi bayi nitori a ko ti ṣe iwadi wa tan lori iṣẹlẹ naa.

“Ọmọdọ tí wọn kọlu naa wa ni ile wosan nibi to ti n gba itọju lọwọ.”