Nǹkan mẹ́wàá tí o kò mọ̀ nìyí nípa Oladipo Diya tó dolóògbé

Dipo Diya

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ńṣe ni ikú ọ̀gágun Dipo Diya tó jẹ́ igbákejì olórí orílẹ̀ èdè yìí tẹ́lẹ̀ rí bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ lójijì bí àwọn rẹ̀ ṣe kéde ikú rẹ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú.

Láti ìgbà tí wọ́n ti kéde ikú rẹ̀ ọ̀hún ni àwọn ènìyàn ti ń kan sáárá sí àgbà ológun náà tó fi ilẹ̀ ṣe aṣọ bora.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn ènìyàn kò mọ̀ nípa ọ̀gágun Diya pàápàá àwọn ọmọ òde òní.

Ìdí nìyí tí BBC News Yorùbá fi ṣe àkójọ àwọn mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa olóògbé Dipo Diya.

Àwọn nǹkan mẹ́wàá ọ̀hún nìyí

  • Ní ọjọ́ kẹta oṣù Kẹrin, ọdún 1944 ni wọ́n bí Oladipo Donalson Diya ní Odogbolu, ìpínlẹ̀ Ogun.
  • Ọ̀dọ́ ló fi darapọ̀ mọ́ ilé ẹ̀kọ́ ológun ìyẹn Nigerian Defence Academy, Kaduna tó sì wà lára àwọn ológun tó abẹ́lé orílẹ̀ èdè yìí láàárín ọjọ́ Kẹfà oṣù Keje ọdún 1967 sí ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kìíní ọdún 1970.
  • Olóògbé Diya kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ahmadu Bello University, Zaria tó sì tún lọ sí Nigerian Law School níbi tí tó ti gboyè aṣojú ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà ìyẹn oyè Solicitor and Advocate of Supreme Court of Nigeria.
  • Kó tó di wí pé Diya gboyè gẹ́gẹ́ igbákejì Abacha, ó ti ṣe olórí àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà, tó sì tún ti fìgbà kan ṣe gómìnà ológun fún ìpínlẹ̀ Ogun láàárín oṣù Kìíní ọdún 1984 sí oṣù Kẹjọ ọdún 1985.
  • Ní ọdún 1993, ni wọ́n yàn-án gẹ́gẹ́ bí igbákejì ìjọba ológun Abacha kí wan tó tún fun ní igbákejì Provisional Ruling Council lọ́dún 1994.
  • Ní ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kejìlá ọdún 1997, ìjọba Abacha gba àwọn àgbà ológun kan bíi ọ̀gágun Tunji Olanrewaju, Abdulkarim Adisa àtàwọn mẹ́sàn-án mìíràn tí Diya náà wà lára wọn fẹ́sùn wí pé wọ́n ń gbèrò láti dìtẹ̀gbàjọba lọ́wọ́ Abacha.
  • Ọ̀sẹ̀ kan kí wọ́n tó gbá wọn mọ́lé, Diya móríbọ́ lọ́wọ́ ikú nígbà tí àdó olóró bú gbàmù ní pápákọ̀ òfurufú ìlú Abuja nígbà tó ń lọ ṣojú Abacha níbi òkú ìyá ọ̀gágun Lawrence Onoja ní ìpínlẹ̀ Benue.
  • Diya pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Bamaiyi àtàwọn àgbà ológun mìíràn ń bèèrè nǹkan mẹ́rin lọ́wọ́ Abacha lẹ́yìn tí wọ́n ń ṣe àkíyèsí pé ó fẹ́ sọ ara rẹ̀ di ààrẹ títí láé. Àwọn nǹkan mẹ́rin ọ̀hún ni:
  • Wọ́n ṣe ìwádìí Diya níwájú ìgbìmọ̀ àwọn ológun tí wọ́n sì dájọ́ ikú fun àmọ́ lẹ́yìn ikú Abacha, Abdulsalami Abubakar tó gba ipò lẹ́yìn jáwé oríjì fún-un, tí wọ́n sì tu sílẹ̀.
  • Lẹ́yìn tí wọ́n tu sílẹ̀, wọ́n gba ipò ọmọ ogun tó wà lọ́wọ́ rẹ̀, le kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ológun, tó sì tún di èèwọ̀ fún-un láti máa lo ipò rẹ̀ nínú ológun síwájú orúkọ rẹ̀.

Ikú Diya dùn mí nítorí akínkanjú tó jà fitafita fún Naijiria ni – Bola Tinubu

AWORAN TINUBU/DIYA

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gomina ipinlẹ Eko nigba kan ri, to tun jẹ aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Bola Tinubu ti fi iwe ikẹdun ransẹ si idile Ọgagun Oladipo Diya, ẹniti o di ologbe ni Ọjọ Kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2023.

Ninu iwe ikẹdun rẹ ni Tinubu ti yin Diya fun ipa pataki to ko fun orilẹede Nijiria gẹgẹ bi ologun ati si orilẹede yii lapapọ.

Tinubu ni “Iroyin iku ọgagun Diya bami ninu jẹ laarọ yi ti mo gbọ,mo n ki awọn iyawo ati ọmọ wọn ku ara feraku”.

“Ọgagun Diya gbe igbe aye to dara ṣaaju gẹgẹ bi gomina ologun fun ipinlẹ Ogun ati ninu awọn ipo ti wọn dimu ninu iṣẹ ologun titi ti wọn fi di igbakeji olori orilẹede yii labe ologbe Sani Abacha”.

Aarẹ tuntun teṣiwaju wi pe ”a ko le gbagbe akitiyan rẹ nigba ifẹhonuhan June 12 ati ilakaka rẹ ati ifarasin fun orilẹede yii”.

Tinubu ninu iwe ikẹdun rẹ ki gomina ipinlẹ Ogun Dapo Abiodun ku ara fẹ ra ku, o si gbadura ki Olorun duro ti idile naa.

Dapo Abiodun kọrin arò lẹ́yìn ikú Dipo Diya

Aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Dapo Abiodun ti kọrin arò lẹ́yìn ọ̀gágun Oladipo Diya tó dolóògbé.

Abiodun nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fétò ìròyìn, Kunle Somorin ní ìpínlẹ̀ Ogun àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀ ti pàdánù akínkanjú ológun tó fi gbogbo ìgbé ayé rẹ̀ sin Nàìjíríà.

Bákan náà ló gbà á ládùrá kí Ọlọ́run tẹ́ olóògbé sí afẹ́fẹ́ rere kó sì fún àwọn ẹbí rẹ̀ ní ọkàn láti gba àdánù wọn.

Olórí òṣìṣẹ́ ìjọba Abacha, Oladipo Diya dágbére fáyé

Ọgagun Oladipupo Oyeyinka Diya ẹni ti o ti fi gba kan ri jẹ igbakeji olori orilẹ ede yii Ọgagun Sani Abacha ti jade laye lẹni ọdun mejidinlaadọrun-un.

Ninu atẹjade ti Amofin Oyesinmilola Diya fi lede lorukọ gbogbo ẹbi lowurọ oni lo ti kede iku Ọgagun Diya.

Gẹgẹ bi atejade naa ṣe sọ, Diya jade laye ni owurọ kutukutu ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kẹta, ọdun 2023, to ku ọjọ mẹjo si ọjọ ti kọ ba se ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mọkandinlaadọrun-un.

Tani Ọgagun Oladipupo Oyeyinka Diya?

Dipo Diya

Oríṣun àwòrán, Facebook

Diya ni wọn bi ni ọjọ kẹta osu Kẹrin ọdun 1944, ti o si di gomina ologun fun ipinlẹ Ogun lẹyin ti Buhari ati Idiagbon gba ijọba ni ọjọ kọkanlelọgbọn osu kejila ọdun 1983.

Diya darapọ mo iṣẹ ologun ni Kaduna ti o si wa lara awọn ologun to ja ninu ija ogun abẹle orilẹ ede yii.

Ogagun Diya tẹsiwaju ninu ẹkọ lọ si ile ẹkọ awọn Ologun ni orilẹede Amẹrika ati ile ẹkọ ti wọn ti n kọ nipa eto ati ọgbọn inu ni Kuru.

Nitori ifẹ to ni si imọ ẹkọ, Diya tun tẹsiwaju lati lọ si ile ẹkọ ti wọn ti n kọ nipa ofin ni fasiti Ahmadu Bello ti ilu Zaria ti o si di agbẹjọro agba fun ile ẹjọ ti wọn ti n gbọ ẹjọ kotẹmilorun Orilẹede yii.

Diya di olori ikọ ologun GOC ọwọ ẹka mejilelọgorun-un ko to di igbakeji olori orilẹ ede labẹ iṣejọba Ologbe Sani Abacha.

Wọn fẹsun iditẹgbajọba kan-an, ti wọn si dajọ iku fun ni ọjọ kejindinlọgbon oṣu kẹrin ọdun 1998.