Àwọn wo ní olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó ń gbèrò láti rọ́pò Ààrẹ Buhari

  • Victor Ezeama
  • Broadcast Journalist

Aworan awọn oludije tikẹẹti PDP

Aaya ti bẹ silẹ bayii tawọn to ndu tikẹẹti lati dije ipo aarẹ lọdun 2023 ni Naijiria ti bẹ si aare.

Pupọ ti n ferongba han lati dije ipo to gajulọ ni Naijiria.

Amọ ninu ẹgbẹ oṣelu alatako PDP ni Naijiria, awọn to ti ferongba silẹ fun tikẹẹti oludije ipo aarẹ ti le ni mẹwaa

Mẹrin ninu wọn jẹ gomina to wa lori oye ninu mọkandinlogun ti ẹgbẹ naa ni ni Naijiria.

Awọn to ferongba silẹ lati du tikẹẹti PDP

Yatọ si akẹgbẹ wọn APC to ti lawọn yoo tẹle ilana ”zoning” lori ipo oludije aarẹ, PDP ko ti sọ iha Naijiria ti oludije ti gbọdọ wa

Eleyi lo jẹ ki awọn oludije jakejado Naijiria maa fẹrongba han.

Ninu awọn oludije yi la ti ri Atiku Abubakar,Bukola Saraki, Ayo Fayose, Peter Obi Mohammed Hayatu-Deen, Sam Ohabunwa ati Pius Ayim.

Awọn miran ni Nyesom Wike, Aminu Tambuwal, Bala Mohammed, Nwachukwu Anakwenze Emmanuel Udom ati Dele Momodu.

Gbogbo awọn taa ka silẹ yii lo ti gba fọọmu lati kopa ninu idibo abẹnu ti yoo waye loṣu to n bọ.

2px presentational grey line

Atiku Abubakar

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar

Igba ẹlẹẹkẹfa ree ti igbakeji aarẹ tẹlẹ yii yoo du ipo Aarẹ.

Ipinlẹ Adamawa lo ti wa ni ila oorun Ariwa Naijiria.

Oloṣelu ati oniṣowo ni Atiku. O ṣaaju dije dupo gomina Adamawa lẹẹmeji, 1990 ati ni 1998 ko to pada di igbakeji aarẹ ni 1999.

Ni 1993 o du ipo aarẹ labẹ asia Social Democratic party nibi to ti fidirẹmi lọwọ Moshood Abiola ati Baba Gana Kingibe.

Ni bayi to pe ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin, Atiku ṣi loun ni igbagbọ pe o yẹ ki wọn fun oun laaye lati dari Naijiria.

Lasiko to n kede erongba rẹ lati du ipo Aarẹ, Atiku sọ pe koko marun un loun yoo gbajumọ, aabo, ọrọ aje, ẹkọ, isọkan Naijiria ati gbigbe agbara fawọn ipinlẹ.

2px presentational grey line

Bukola Saraki

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, Bukola Saraki

Idile oloṣelu ni Bukola Saraki ti wa.

O fi igba kan jẹ Gomina ni ipinlẹ Kwara to si ṣe saa meji ni ijọba laarin 2003-2011.

Lẹyin igba naa o di aarẹ ile aṣofin agba Naijiria ldun 2015.

Inu ẹgbẹ PDP lo ti kọkọ bẹrẹ irinajo rẹ ko to pada si APC ko tun to pada si PDP ṣaaju idibo 2019.

Saa kan lo lo lori ipo aarẹ ile aṣofin agba ko to fidi rẹmi ninu idibo to waye lẹyin.

Ẹni ọdun mọkandinlọgọta ni Saraki ṣe to si jẹ onimọ nipa ilera ko to di oloṣelu.

2px presentational grey line

Sam Ohabunwa

Sam Ohabunwa

Oríṣun àwòrán, Sam Ohabunwa

Sam Ohabunwa ni oludije ti ọjọ ori rẹ dagba julọ ṣikeji ninu awọn to n wa tikẹẹti PDP.

Ipinlẹ Abia lo ti wa ni ilẹ Igbo Naijiria.

O jẹ akọṣẹmọṣ apoogun to si tun jẹ oloṣelu.

Saaju asiko yi o ti jẹ alaga igbimọ to n risi ọrọ aje Naijiria oun si ni alaga akọkọ fawọn ẹgbẹ awọn to peelo nkan ni Naijiria.

Ohabunwa sọ pe oun ni iriri toun fi le sọ Naijiria di orileede ti yoo maa da pese ohun elo gbogbo to ba nilo.

O ni Naijiria ti yapa bayi ati pe oun fẹ mu isọkan pada wa ki nkan si burẹkẹ fawọn eeyan orileede Naijiria.

2px presentational grey line

Aminu Tambuwal

Aminu Tambuwal

Oríṣun àwòrán, Aminu Tambuwal

Tambuwal ti ṣe Gomina lẹẹmeeji ni ipinlẹ Sokoto.

Ṣaaju lo jẹ ipo olori ile aṣojuṣofin Naijiria laarin ọdun 2011-2015.

O gbero lati jẹ Aarẹ Naijiria lọdun 2019 ṣugbọn o kuna. Ninu awọn alatilẹyin rẹ nigba naa ni ọrẹ rẹ Gomina Nyesom Wike ipinlẹ Rivers.

Amọ bayi ẹni ọdun mẹrindinlọgọta yi n wa tikẹẹti ipo aarẹ PDP pẹlu ọrẹ rẹ Wike.

O ni erongba oun ni lati wa ojutu si gbogbo ipenija to n koju Naijiria,

2px presentational grey line

Nyesom Wike

Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, Nyesom Wike

Gomina lọwọlọwọ ni Nyesom Wike j ni ipinlẹ Rivers.

Agbẹjọro ni Wike to si di alaga ijọba ibilẹ Obio-Akpor lọdun 1999.

Lọdun 2007 o riṣẹ gẹgẹ bi olori oṣiṣẹ ile ijọba fun Gomina Rotimi Amaechi

Nigba ti yoo fi di 2011, Aarẹ tẹlẹ Goodluck Jonathan yan sipo Minisita feto ẹkọ.

Lọdun 2015 lo di Gomina Rivers to si n ṣe saa keji rẹ lọwọ bayii.

O ni ijọba oun gẹgẹ bi aarẹ yoo wa ojutu si gbogbo ipenija didari Naijiria toun yoo si sọ eto ọrọ aje ji pada.

2px presentational grey line

Bala Mohammed

Bala Mohammed

Oríṣun àwòrán, Bala Mohammed

Gomina lọwọ bayi ni ipinlẹ Bauchi ni Bala Mohammede jẹ.

Ṣaaju o ti jẹ Sẹnẹtọ laarin ọdun 2007-2010.

Ni 2010 o di Minisita fun olu ilu Naijiria, FCT ti eleyi si tan irawọ rẹ soke gẹgẹ bi oloṣelu.

Lọdun 2019 o jawe olubori ninu idibo to si wọle sipo Gomina Bauchi

Ẹni ọdun mẹtalelọgọta yii sọ pe oun nigba pe oun le mu iyipada ba Naijiria

2px presentational grey line

Peter Obi

Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Peter Obi

Oloṣelu ati oniṣowo ni Peter Obi jẹ.

O fi igba kan jẹ Gomina ni ipinlẹ Anambra to si lo saa meji laarin 2008-2018

Obi jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Grand Alliance (Apga) ki o to darapọ mọ PDP ni 2017.

O tun jẹ eeyan kan to nimọ nipa eto ọrọ aje.

Lọdun 2019 o jade gẹgẹ bi igbakeji Atiku Abubakar fun ipo aarẹ. Amọ lọdun 2022 o ni oun gaan loun f du ipo aarẹ.

Ipese iṣẹ, mimu agbega ba eto ọrọ aje Naijiria ati eto ẹkọ ni afojusun Peter Obi to ba jẹ aarẹ Naijiria.

2px presentational grey line

Ayo Fayose

Ayo Fayose

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka

Oṣokomọlẹ Gomina nigba kan ri ni Ayodele Fayose jẹ.

O ṣe Gomina ni saa meji. Igba akọkọ ni laarin ọdun 2003 si 2006.

O fipo silẹ ko to tun pada wa di Gomina ni igba ẹlẹẹkeji iyẹn laarin ọdun 2014-2018.

Ẹni ọdun mejilelọgọta ni Fayose n ṣe.

O ni oun ni iriri lati le mu iyipada ba Naijiria.

2px presentational grey line

Bi wọn yoo ṣe pada yan oludije ipo aarẹ PDP

Laarin ọjọ Kẹrin oṣu Kẹrin si ọjọ Kẹta oṣu Kẹfa lawọn ẹgbẹ oṣelu ni lati ṣeto idibo abẹnu kiwọn si yanju aawọ kankan to ba tẹyin rẹ wa.

Eyi lọrọ to wa ninu ilana idibo ti ajọ eleto idibo INEC gbe jade. Wọn le lo ilana taarara, ẹlẹburu tabi ki wọn fẹnu ko lati yan oludije to ba wu wọn.

Amọ ṣa INEC ni gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ lo gbọdọ buwọlu ki wọn sikopa ninu eto afẹnukoyan aṣoju yi taa mọ si “consensus.”

Gbogbo awọn aṣoju yi yoo si peju lati ipinlẹ mẹrindinlogoji si ibudo ti wọn ba yan lati ṣe ipade apero gbogboogbo ẹgbẹ wọn.

A o maa fi orukọ awọn oludije mii sọwọ lori apilkọ yi bi wọn ba ti ṣe n yọju.Ẹ maa ba wa fkan ba eto naa bọ.