Ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa òṣèré Funke Akindele lẹ́yìn ìtàgé rèé

Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, funkejennifaakindele

Sulia kan, Ayetoro kan!

Ọrọ yii kii ṣe ajoji si ẹnikẹni to ba mọ fiimu to gbe Funke Akindele saye gẹgẹ bi ẹni gbogbo eniyan wa mọ lagbaye bayii kaakiri ede ati ẹya.

Ọjọ ikẹrinlelogun oṣu kẹjọ ọdun 1977 ni wọn bi Funke Akindele ni idile Akindele, baba rẹ jẹ adari ile iwe girama ti iya rẹ si jẹ dokita.

Oṣere ni, olukọtan ni, o tun jẹ olootu to ṣe wi pe bi awọn eniyan ṣe bẹrẹ si ni mọ ọ jẹ ara ọtọ paapaa pẹlu ere rẹ to fi gba orukọ, Jennifer.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ohun ti a fi lee pe e ni oniroyin ni wi pe iṣẹ to fi bẹrẹ ẹkọ kika ni ibẹrẹ ile iwe giga rẹ̀ ni imọ nipa iṣẹ iroyin.

Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, funkejenifaakindele

Kii ṣe ere yii ni akọkọ rẹ gẹgẹ bi oṣere, ati igba ti ọjọ ori rẹ ṣi din ni ogun ọdun lo ti kopa ninu ere to n kọ ni lẹkọ kan ti ajọ UNICEF ṣe onigbọwọ, “I Need to Know”.

Lẹyin ile iwe girama, Funke kawe gboye OND ni ile ẹkọ akọṣẹmọṣẹ Moshood Abiola Polytechnic ninu imọ iṣẹ iroyin lẹyin eyi to tun kawe gboye ninu imọ ofin ni ile ẹkọ fasiti ilu Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ibi ti Funke Akindele ti di gbajugbaja ni ninu ere rẹ to ṣe ni ọdun 2008, “Jennifer” eyi to tan kari aye kari oko.

Lẹyin eyi, Funke tun ṣe agbejade sinima agbelewo to ṣi n han lọwọ lori ẹrọ amohunmaworan, “Jennifer’s Diary”, eyi jẹ bii amọle ere “Jennifer”.

Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, funkejennifaakindele

Lẹyin eleyi lo tun ṣe afikun pẹlu agbejade “Return of Jennifer”.

Yatọ fun awọn ere tirẹ, Funke ti kopa ninu ọpọlọpọ ere mii yala lede Yoruba tabi Gẹẹsi eyi ti ko ṣee darukọ tan.

Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, funkejennifaakindele

Chief Daddy, Industreet, Isoken, Moms at War, A Trip to Jamaica, Pretty Liars, The Hero, Sheri Koko, Married But Living Single.

Ojo Ketala, Akorede, Maami, Apaadi, Aje Meta 1 and 2, Asiri Nla, Apaadi 1 and 2, Koosefowora, Iro Funfun, Taiwo Taiwo, Omo Ghetto, Agbara ife, Agbefo, Iro funfun, Awa Obinrin.

Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, Funkejennifaakindele

Funke Akindele ni oludasilẹ ati alakoso Scene One Film Production ti wọn ti n kọ nipa ere tiata. Bakan naa o ni ile iṣẹ ti ko rọgbọku le ijọba eyi to fi n kọ awọn ọdọ niṣẹ ọwọ.

Latari iṣẹ takun takun rẹ ninu ere tiata, Funke ti gba ọpọlọpọ ami ẹyẹ o si ti ṣe awọn iṣẹ akanṣe bii ipolowo fun oriṣiriṣi ọja ati ile iṣẹ.

Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, funkejennifaakindele

Lara wọn ni African Movie Academy Award (AMAA) gẹgẹ bi oṣerebinrin to dantọ ju, AfroHollywood fun oṣerebinrin to n ṣatilẹyin ju; awọn ami ẹyẹ mii to gba gẹgẹ bi oṣerebinrin to tayọ ju ni Future Awards, Dynamix Awards, City People, City People fiimu to dara ju lọdun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Igbeyawo

Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, funkejennifaakindele

Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, funkejennifaakindele

Funke Akindele pẹlu ọkọ aarọ rẹ, Adeola Kehinde Oloyede pinya lọdun 2013 latari ohun ti wọn pe ni aibaramu iwa. Lẹyin eyi ni o fẹ olorin takasufe ọmọ Naijiria Abdul Rasheed Bello niluu London.

Yatọ fun awọn ọmọ ti Funke n tọ gẹgẹ bii ọmọ tirẹ gangan, Ọlọrun fi ibeji ọmọ ọkunrin ta oun ati ọkọ rẹ lọrẹ ninu oṣu kejila ọdun 2018.