Kí ló kan Ẹyin àti Ehoro nínú ìtàn àti ayẹyẹ ọdún Àjíǹde Jésú Krístì?

rabbits-in-a-basket-surrounded-by-colourful-eggs

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdun Ajinde Easter jẹ ọpọmulero igbagbọ awọn ọmọlẹyin Kristi to ti wa fun ẹgbẹgbẹrun ọdun.

Asiko ọdun Ajinde ni awọn onigbagbọ ma n ṣe ajọdun ajinde Jesu Kristi kuro ni ipo oku, ti Iwe Mimọ Bibeli sọ wipe Jẹsu Kristi ku lori igi agbelebu ni Ọjọ Ẹti rere, Good Friday.

Gẹgẹ bi bibẹli ṣe sọ, Jesu Kristi jinde ni ọjọ kẹta kuro ni ipo oku, ti o si jasi Ọjọ Ajinde.

Ni ọdọọdun, ọdun Ajinde ma n yatọ to si ṣeeṣe ko waye lọjọ kan laarin ọjọ kọkanlelogun, Oṣu Kẹta si Ọjọ karundinlọgbọn, Oṣu Kẹrin, eleyii ti awọn kan gbọgbọ wipe o niṣe pẹlu bi irawọ ba ṣe tan imolẹ si(Full Moon).

Lasiko ọdun Ajinde, awọn Kristẹni ma n darapọ lati gbadura ki wọn si jọ jẹun papọ. Toripe ṣaaju asiko naa, wn ti wa ninu awẹ Lẹnti Ọgbọn ọjọ gẹgẹ bi Jesu Kristi naa ṣe gba a ninu iwe mimọ.

Amọ, ajakalẹ arun Coronavirus le mu ki ọpọlọpọ eniyan ma lọ si ile ijọsin tabi ki wọn darapọ mọ isin ni ori ẹrọ ayelujara.

Ki lo wa n jẹ “Ẹyin” ọdun Ajinde?

Odun Ajinde

Oríṣun àwòrán, Google

Ni Ilẹ Yuroopu, ọpọlọpọ eniyan lo ma n jẹ ṣọkoleeti ẹlẹyin lasiko ọdun Ajinde lati fi ṣe ayẹyẹ ajinde Jesu Kristi.

Ni igba ti asa ẹyin bẹrẹ, awọn adari ẹsin ni igba naa lọhun kii gba ki awọn eniyan jẹ ẹyin lasiko ọṣẹ ijiya Jesu, ti awọn oloyinbo n pe ni Holy Week.

Nitori naa ohun ti awọn eniyan ma n ṣe ni lati lati ko awọn ẹyin ti adiye ba ye ni asiko yii pamọ, ti wọn a si ṣe e ni ẹsọ, ti wọn a si fun awọn ọmọde gẹgẹ bi ẹbun ni ọjọ Ajinde.

Easter chocolate

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Titi di oni ni awọn eniyan ṣi n ṣe e, ti wọn ṣi n fun awọn eniyan ni ẹbun ẹyin ni ọdun Ajinde.

Ehoro nkọ, kini wọn fi ṣe ni Ọjọ Ajinde?

Rabbits sitting behind some Easter eggs

Oríṣun àwòrán, iStock

Itan ehoro ajinde ni o wọpọ ni awujọ awọn eniyan ni ọdun 1900 lọhun.

Awọn ehoro ma n bi ọmọ to ma n tobi ti awọn oloyinbo n pe ni (kitten), ti awọn eniyan si ri wọn gẹgẹ bi ibẹrẹ igbeaye tuntun.

Itan sọ fun wa pe awọn ẹyin ti ehoro ba ye ni asiko yii, ehoro ma n ṣe e ni ẹsọ ti asi lọ gbe e pamọ.

Nitori naa awọn ọmọ kekeeke ma n wa ẹyin ehoro kaakiri lasiko ọdun ajinde.