Akẹ́kọ̀ọ́ Seminary tó ń kópa nínú eré “Passion for Christ” kú lórí ìtàgé, bó ṣe ṣẹlẹ̀ nìyí

Suel Ambrose

Ọmọ ile ẹkọ awọn Alufaa ti ọpọ mọ si Seminary ti jẹ ọlọjọ nipe lasiko to n kopa ninu ere ori itage to sọ nipa ijiya Jesu Kristi lati fi ṣaami ọdun Ajinde.

Ọmọ ile ẹkọ naa, Suel Ambrose jẹ ẹni ọdun mẹẹdọgbọn.

Ṣe ni Ambrose dede wo lulẹ wọọ lasiko ti wọn n ṣe ere naa lọwọ amọ titi di asiko yii, ko tii sẹni to mọ pato ohun to fa iku rẹ.

Alaye ohun to ṣẹlẹ

Suel Ambrose lasiko ọdun Ajinde

Akẹkọ imọ ẹkọ ẹka Institute of Philosophy ni Ambrose ni Fasiti Claratan, Nekede ni ipinlẹ Imo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Gẹgẹ bi ọpọlọpọ ọmọlẹyin Kristi ṣe maa n ṣe ni gbogbo ọdun Ajinde, ile ẹkọ ti ij Katoliki ṣe agbekalẹ ere ori itage lati sọ itan iku ati ajinde Jesu Kristi.

Ipa Peteru ni oloogbe Ambrosee n ko lasiko to ṣubu lulẹ

Iroyin ni ṣe ni iṣẹlẹ da idarudapọ silẹ ninu ile ẹkọ naa. Gbara toṣubu lulẹ ni wọn ti sare gbe e digba – digba lọ ile iwosan FMC ilu Owerri.

Amọ ọrọ ko ba mọ, o ṣe ni laanu pe wọn kede pe o ti ku ni ile iwosan.

Ọkan lara awọn Alufaa nile ẹkọ naa, Chukwuemeka Iheme fi aridaju han pe lootọ ni iroyin yii amọ o ni awọn alaṣẹ yoo sọ ọrọ sii lori iṣlẹ naa to ba ya.

“Ẹjẹ bẹrẹ si ni da lara Ambrose bo ṣe ṣubu”

Awọn alaṣẹ Fasiti Claratian ti fagile gbogbo eto ọdun Ajinde bayii nitori iṣẹlẹ naa.

Eeyan kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe “Lasiko ere naa, ibi ti awọn Sọja ti bẹrẹ si ni le awọn ọmọde to wa nibẹ ni Ambrose ṣubu to bẹrẹ si ni da ẹjẹ lara”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“A gbe e lọ si ileewosan ile ẹkọ wa nibi ti awọn dokita ti gbiyanju lati doola rẹ amọ ko fesi”

Asiko naa la gbee lọ si Federal Medical Centre, Owerri nibi ti wọn ti ni pe o ti ku”, ẹni naa sọ fun oniroyin.

Kí ni itan ere Passion for Christ lasiko Ajinde?

Eeyan to n ko ipa Jesu ninu ere ọdun Ajinde

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI

Ere “ijiya Jesu Kristi” (Passion for Christ) jẹ eyi ti awọn Kristẹni maa n fi ranti iku ati ajinde Jesu Kristi to wa ni akọsilẹ ninu bibeli bi o ṣe ku fun ẹṣẹ araye lẹyin ti wọn kan an m igi agbelebu to si jinde ni ọjọ kẹta.

Ere yii gan ni wọn ma fi n sọ ita ajinde.

Ọrọ naa “Passion” to tumọ si “itara” ni wọn lo lati fi ṣe apejuwe ifẹ ti Jesu ni fun araye to mu u jọwọ aye rẹ fun awọn ẹlẹṣẹ.