Ọ̀dọ́ márùn-ún forí la ikú nínú oko lọ́wọ́ agbébọn tó tún ṣèkọlù l’Ondo

Ilu Arimogija

O kere tan, eeyan máàrún lo ti kagbako iku ojiji lẹyin ti awọn agbebọn ṣe ikọlù sí ilu wọn ni Arimogija ni ijọba ibilẹ Ọsẹ ni ipinlẹ Ondo.

Awọn agbebọn naa ni iroyin sọ pe wọn jẹ afurasi Fulani darandaran.

Ọpọlọpọ eniyan lo farapa latari ikọlu yii.

Akọwe ẹgbẹ awọn ọdọ ni ilu Arimogija, Nweke Izuchukwu Jude ṣalaye fun ile-iṣẹ BBC News Yoruba pe awọn marun lo ku ninu akọlu meji ni ọjọ kan ṣoṣo.

O ni pe, awọn agbebọn yii kọkọ ṣe akọlu si awọn to wa ninu oko ti wọn si pa eeyan meji ko to di pe wọn ke gbajare fun awọn to wa ni igboro.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O fi kun pe eleyi lo mu ọpọlọpọ ọdọ lati lọ ṣe iranlọwọ fun awọn akẹgbẹ wọn, amọ ti awọn agbebọn yii dawọn lọna ti wọn si pa ọdọ mẹta miran.

Jude ni pe ibẹru bojo ti wa de ba awọn ara ilu nitori kosi abo to peye fun wọn fun ọpọlọpọ ọdun.

O tun sọpe kosi ọlọpa abi amọtẹkun ninu ilu naa botilẹjepe awọn Fulani darandaran yii ti gba gbogbo oko wọn.

Bi ako ba gbagbe, laipẹ ni awọn agbebọn ṣe akọlu si ilu Mọlẹgẹ ni agbegbe Arimogija ti wọn si pa eeyan mẹta lẹyin ti wọn jo ọpọlọpọ ile ati dukia.

Gomina Oluwarotimi Akeredolu ti ọga Ọlọpa ati Amọtẹkun ba kọwọ rin lọ ṣe abẹwo si ilu Mọlẹgẹ fi idaniloju ijọba rẹ han lati ri pe awọn to ṣe akọlu naa fi oju ba ofin.

Ọlọ́pàá kàgbákò ikú òjijì lọ́wọ́ àwọn agbébọn l’Ondo

Gunmen Kill Police Officer In Ondo

Oríṣun àwòrán, @thecableng

Awọn agbebọn kan, ti igbagbọ wa pe wọn jẹ adigunjale ti yinbọ pa ọlọpaa kan niluu Oka-Akoko, ni ipinlẹ Ondo.

Wọn yinbọn pa ọlọpaa naa, ti wọn ko tii fi orukọ rẹ lede lagbegbe Oke Maria, niluu naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun, DSP Oluwafunmilayo Odunlami lo fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun.

Iroyin ni iṣẹlẹ naa ti mu ipaya ba ọpọ awọn eeyan agbegbe ọhun.

Gẹgẹ bii ohun ti Odunlami sọ, ori alupupu ni awọn agbebọn naa ti yinbọn fun ọlọpaa ọhun, ti wọn si fẹsẹ fẹẹ.

O fi kun un pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ okodoro bi iṣẹlẹ naa ṣe jẹ.

Ẹwẹ, wọn ti gbe oku ọlọpaa ọhun lọ sile igbokupamọsi nile iwosan ti ko jina si agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ