A fẹ́ kí INEC sèwádìí àwọn gómìnà àti igbákeji wọn fún ìwà jàgídíjìgan lásìkò ìdìbò – SERAP

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ajọ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan, SERAP ti kesi alaga ajọ INEC lati ṣewadii iwa jagidijagan to waye lasiko idibo kaakiri lorilẹede Naijiria.

Ninu lẹta ti Serap kọ si alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu lati gbe igbimọ kalẹ ni kiakia lati ṣewadii ni finifini awọn to wa nidi iwa ipa naa.

Serap ni ki INEC ṣewadii ẹsun magomago naa ti wọn fi kan awọn oṣiṣẹ wọn lasiko idibo naa.

Bakan naa lo ni iwadii ọhun yoo ṣafihan awọn to ṣe agbatẹru awọn to fa rogbodiyan lasiko idibo naa lai fi ti ẹgbẹ oṣelu kankan ṣe.

‘’Iwe ofin to de ajọ INEC ẹSẹ 52 FUN inec ni anfaani lati gbe igbimọ iwadii kalẹ lati ṣewadii iwa magomago lasiko idibo naa.

‘’Lara awọn ẹsun ti wọn fẹ ki wọn ṣewadii ni gbigba riba lọwọ awọn gomina ipinlẹ ati awọn igbakeji wọn.’’

Gẹgẹ bi ọrọ ajọ Serap, ki INEC ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ ICPC ati awọn ajọ agbofinro miran lati le fi ọwọ ofin mu ẹnikẹni to ba ṣe magomago lasiko idibo naa.

‘’Wọn gbọdọ wa wọn ri, ki wọn fi panpẹ ọba mu wọn, ki wọn ṣe iwadii wọn, ki wọn si fi idi otitọ mulẹ.’’

‘’Gbogbo awọn to ṣe magomago tabi iwa jagidijagan lasiko idibo gbogboogbo ni Naijiria gbọdọ foju wina ofin.’’

Gẹgẹ bi awọn ajọ onwoye idibo bii Centre for Democracy and Development ṣe fi lede pe ọpọlọpọ iwa ipa lo waye ni awọn ibudo idibo kan ni awọn ipinlẹ ni Naijiria, ti wọn ko si gba ki awọn miran tilẹ dibo rara.

Àìgbọràn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló fa ìjákulẹ̀ rẹ̀, Ìhà Gúúsù orílẹ̀èdè yìí nípò Aarẹ tọ́ sì – Fayose

Aworan Fayose

Oríṣun àwòrán, AyodeleFayose/Facebook

Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri Ayodele Fayose ni ki awọn ọmọ orilẹede yi ye da ẹbi ru ajọ to se kokari eto idibo INEC mọ fun awọn rogbodiyan ati laasigbo to tẹle abajade esi idibo ọdun yii.

Ninu ifọrọwerọ to se pẹlu ile ise amohunmaworan Arise Tv, Fayose sọ taa lo jẹbi.

“Awọn oloṣelu orilẹede yii lo jẹbi iwa jagidijagan to ṣẹlẹ ninu eto idibo yii nitori ajọ INEC sa ipa rẹ lati rii wi pe eto idibo ọdun yii mu yanyan”.

Fayose ni awọn oloṣelu to fẹ gba ipo oṣelu tipatipa lo da kun laasigbo to waye nitori ajọ INEC kọ ni ile iṣẹ ọlọpa ati ologun ti yoo koju awọn oni jagidijagan.

Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri ni gbogbo ọmọ orilẹede yii lo jẹbi nitori bi adari wa ti ri naa ni awọn ọmọlẹyin na rii.

O ni: “Ọpọ awọn janduku ri eto idibo gẹgẹ bi ọna ati ri owo eyi to faa ti awọn iwa ipa se pọ sii ninu awọn eto idibo wa”.

Fayose ni lati ọdun 1979 ti oun ti gbọnju mọ nipa oselu Orilẹede yii ko tii si iyatọ kan kan.

Ki lo de too wa ni PDP too tun garuku ti Tinubu?

“Nitori ilana eto idibo to gbe e wọle, Aarẹ tuntun ti ilu dibo yan ninu ẹgbẹ oselu APC Bola Tinubu kun oju osunwọn”.

Ọpọ eeyan lo ti n fi ero wọn han lati igba ti eto idibo ti bẹrẹ lori bi Fayose ko ṣe da si ọrọ ẹgbẹ oṣelu tirẹ amọ ti wọn pada rii ti ko fi pamọ pe Bola Tinubu ni oludije aayo oun.

Fayose ni nigba ti Wike ati ẹgbẹ G5 ti PDP sọ wi pe o yẹ ki ipo Aarẹ pada si apa Guusu Orilẹede yii awọn kan fapajanu ṣugbon esi eto idibo yii ti fihan pe ẹgbẹ G5 ko parọ.

Gomina tẹlẹri naa ni, inu ẹgbẹ oṣelu PDP ni Peter Obi to ni ibo milliọnu mẹfa o le ati Musa Kwankwaso to ni ibo milliọnu kan o le ti jade kuro, ti wọn ba fi apapọ ibo ti wọn ni kun ti Atiku dajudaju ẹgbẹ oselu PDP lo yẹ ki o jawe olubori.

Fayose ṣalaye pe niwọn igba to jẹ pe iha Guusu ni agbara kan, ki lo wa ku.

Ṣugbon awọn to wa ni isakoso ẹgbẹ oselu PDP lọwọlọwọ ko ṣiṣẹ fun idagbasoke ẹgbẹ oṣelu naa nitori ọpọ wọn lo ti ṣiṣẹ tako ẹgbẹ ninu eto idibo ọdun 2019.

Fayose ni ọna abayọ si ilana eto oṣelu tuntun ni Orilẹede yii ni ki awopalẹ wa latori aladari ati awọn ọmọlẹyin wọn, aiṣe bẹẹ ipaniyan nigba eto idibo yoo tẹsiwaju titi ayipada rere yoo fi wa.