Mi ò tíì kú o, àyè ni mo wà! – Akeredolu

Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti sọ pe oun ko tii ku, tako iroyin ka to n lọ laarin ilu pe o ti jade laye.

Akeredolu lo fi ọrọ naa lede lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Richard Olabode.

Ninu atẹjade kan ti Olabode fi lede loju opo Facebook rẹ lo tabuku iroyin iku gomina naa, to si tun bu ẹnu atẹ lu awọn to gbe iroyin naa jade.

O ni “Awọn eeyan ko jẹ ki ẹrọ ibaraẹnisọrọ mi sinmi lati nnkan bii wakati kan sẹyin.”

“O si jẹ ohun iyalẹnu fun mi pe eeyan kan le wa nibikan ko si maa ro iku ro ẹnikeji rẹ.”

“Gẹgẹ bii ohun ti mo sọ fun gbogbo awọn to ti pe mi ṣeyin, gomina Akeredolu ko tii ku, aaye lo wa, ko si ṣaisan kankan.”

Lẹyin naa lo rọ awọn araalu lati ṣora fun awọn gbọyi-sọyi, ki wọn si sọra nipa bi wọn ṣe n lo oju opo ikansiraẹni lori ayelujara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nibo ni iroyin iku gomina Akaredolu ti jẹyọ?

Ṣaaju ni gbajumọ ‘blogger’ ti ọpọ mọ si Gistlover ti kọkọ jabọ pe gomina ọhun ti dagbere faye.

Ninu atẹjade ti Gistlover fi lede loju opo Instagram rẹ, o ni aisan jẹjẹrẹ ‘postrate cancer’lo n ba Akeredolu finra, wọn si ti gbe lọ soke okun fun itọju.

Gistlover sọ pe ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni gomina naa wa.

Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, Gistlover

O fi kun pe iroyin to tẹ oun lọwọ fi han pe gomina naa kọkọ daku amọ o tun ji pada.

Lẹyin iroyin Gislover yii ni ọpọ awọn ololufẹ Akeredolu n woye ohun to ṣẹlẹ si gomina naa ti wọ si bẹrẹ iwadii ti wọn, amọ iroyin naa ko dun mọ awọn amugbalẹgbẹ gomina ọhun ninu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ