MC Oluomo, ilá rẹ fẹ́ máa ga ju onírè lọ – NURTW

MC Oluomo

Oríṣun àwòrán, @MC Oluomo

MC Oluomo, ilá rẹ fẹ́ máa ga ju onírè lọ – NURTW

Nnkan ko dan mọran laarin awon adari apapọ ẹgbẹ ọlọkọ ero ni Naijiria, NURTW ati Ọgbẹni Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluọmọ to jẹ alaga ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Eko.

Rugudu to n lọ laarin igun mejeeji yii jẹyọ ninu lẹta kan ti olu ileeṣẹ naa kọ si MC Oluọmọ pẹlu ẹsun pe ila rẹ fẹ maa ga ju onire lọ.

Awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ naa kọwe ifisun si Oluọmọ pe o n tẹ ofin ẹgbẹ naa mọlẹ ati pe gbogbo iṣesi ati ihuwasi rẹ n tako ilakalẹ ẹgbẹ NURTW.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki lo wa ninu iwe ifisun ti NURTW apapọ kọ si MC Oluọmọ?

Olu ileesẹ ẹgbẹ awakọ ero NURTW koro oju ninu iwe naa si bi MC Oluọmọ ṣe da ofin ẹgbẹ naa danu ninu eyi ti wọn ni wọn ti fi too leti pe Alhaji Azeez Abiọla ni alaga tuntun fun ẹgbẹ awọn oni kẹkẹ Marwa labẹ ẹgbẹ NURTW ni ipinlẹ Eko.

Lẹta naa, eyi ti akọwe apapọ ẹgbẹ NURTW lorilẹ-ede Naijiria, Alhaji Kabiru Ado Yau fọwọ si tun fi ẹsun kan MC Oluọmọ.

O ni pe kaka ko tẹle ofin ẹgbẹ lẹyin ipade ti wọn ba oun atawọn ọmọ igbimọ NURTW nipinlẹ Eko se lọjọ kẹsan an, osu keji ọdun 2022, nṣe ni Oluọmọ “bẹrẹ si ni ko awọn tọọgi rẹ lọ dun mọhuru mọ alaga tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan fawọn oni kẹkẹ marwa naa.”

Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan an pe o kọ lati fa iṣakoso ileeṣẹ ẹgbẹ NURTW to wa lagbegbe Abule Ẹgba le igbimọ alakoso fidihẹ to wa fun awon omikẹkẹ Marwa lọwọ.

Ẹsun miran ti wọn tun fi kan MC Oluọmọ ni pe o n lo awọn janduku lati lọ fipa gba awọn ẹka ẹgbẹ naa to wa labẹ akoso awọn ti ko si labẹ igun tirẹ n’ipinlẹ Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

NURTW fun Oluọmọ ni gbedeke ọjọ meji:

Aṣẹ ti igbimọ alaṣẹ apapọ ẹgbẹ NURTW wa fun MC Oluọmọ bayii no pe ko tete tẹle aṣẹ rẹ nipa fifa akoso sẹkitariati ẹgbẹ naa tẹlẹ le alaga tuntun fun ẹgbẹ onimarwa, Azeez Abiọla lọwọ ki wakati mejidinlaadọta to pe.

Wọn tun paṣẹ pe ki o si tun ko awọn janduku to ko sawọn ẹka ẹgba naa to wa labẹ awọn ti ko ṣe tirẹ kuro ko si tọrọ aforiji lọwọ olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki ni MC Oluọmọ sọ si awon ẹsun wọnyi o?

Agbẹnusọ fun MC Oluọmọ Jimoh Buari la gbọ pe o salaye fun awon oniroyin kan lọjọ Aiku pe lootọ lẹta awọn adari ẹgbẹ naa ti de ọdọ wọn ṣugbọn aisi nile MC Oluọmọ ko ti jẹ ko tii fesi sii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ