Ìdí tí mi ò fi kópa níbi ìpàdé ìpẹ̀tùsááwọ̀ láàárín èmi àti Aregbesola nìyìí – Tinubu

Aregbesola àti Tinubu

Oríṣun àwòrán, others

Tinubu ti sọ̀rọ̀soke lori idi ti ko fi wa sibi ipade ipltusááwọ́ náà

Yorùbá ní ònpe ni ló ń ṣọlá, Adarí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti ṣàlàyé ìdí tí kò fi sí níbi ìpàdé ìpẹ̀tùsááwọ̀ láàárín òun àti Mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé, Rauf Aregbesola.

Ìpàdé ọ̀hún ló láyé láàárín Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Adeyemi, Ọọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀, Ọba Ẹnitan Adeyeye Ogunwusi àti Mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé, Rauf Aregbesola ní ilé Aláàfin lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kìíní oṣù kẹta.

: Ìdí tí mi ò fi kópa níbi ìpàdé ìpẹ̀tùsááwọ̀ láàárín èmi àti Aregbesola nìyìí – Tinubu

Olùbádámọ̀ràn Tinubu lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Tunde Rahman nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìpàdé náà ní wọn kò pe ọ̀gá òun síbẹ̀ ni kò ṣe báwọn péjú níbẹ̀.

Rahman ní bí àwọn ènìyàn ṣe ń rí àwòrán ibi ìpàdé náà lórí ẹ̀rọ ayélujára ni àwọn náà ri ṣùgbọ́n òun ní ìgbàgbọ́ pé àwọn Ọba náà yóò kan sí Asiwaju láìpẹ́.

Tinubu bọ̀wọ̀ fórí adé

Rahman tẹ̀síwájú pé Tinubu ní ọwọ́ tó pọ̀ fún àwọn orí adé àti ọrùn ìlẹ̀kẹ̀, kò sì ní kóyán wọn kéré rárá pàápàá Aláàfin àti Ọọ̀ni.

Ó fi kun pé láìpẹ́ yìí ni Tinubu ṣe àbẹ̀wò sí àwọn Ọba méjéèjì yìí láti fi èròńgbà rẹ̀ láti díje dupò Ààrẹ̀ Nàìjíríà lọ́dún 2023 tó wọn létí ní ààfin kóówa wọn.

Ó ní èyí ṣàfihàn ipò tí Tinubu fi àwọn Ọba wọ̀nyìí sí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Inú Tinubu yóò dùn láti kopá nínú ìpàdé yìí tí wọ́n bá pè é si.

Bákan náà ló sọ síwájú pé inú Tinubu yóò dún láti kópa nínú ìpàdé ìpẹ̀tùsááwọ̀ náà tí wọ́n bá pè é si.

Rahman ní “Ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà ni Tinubu àti Aregbesola, ọdún mẹ́jọ ni Aregbesola fi ṣe Kọmíṣọ́nà fún iṣẹ́ òde nígbà tí Tinubu ń ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Eko.”

“Bẹ́ẹ̀ náà ni Asiwaju ṣe àtìlẹyìn fún un láti di gómìnà ìpínlẹ̀ Osun fún ọdún mẹ́jọ. Mo rò wí pé tí wọ́n bá pe Asiwaju síbi ìpàdè náà, gbogbo nǹkan wọ̀nyìí ni yóò rò pọ̀ láti kópa.”

Alaafin, Aregbesola ati Ooni

Yoruba ni agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ, bi aye ba si tori awọn agbaagba bajẹ, a jẹ pe aimọ iwa wu wọn ni.

Idi ree ti awọn agbaagba Yoruba kan, to fi mọ awọn ọba alaye atawọn agba oselu se n gbe igbesẹ lati yanju aawọ to n waye laarin awọn agba oselu meji.

Awọn agba oselu naa ni Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, tii se oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC ati Minisita fun ọrọ abẹle, Rauf Aregbesola.

Bawo ni ipade alaafia naa se waye:

Awọn oriade to se kokari ipade naa ni Alaafin tilu Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi ati Ooni tilu Ile Ife, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi.

Ile Alaafin to wa nilu Ibadan si ni Ipade naa ti waye naa ti waye.

Ipade yii si ni igbesẹ akọkọ lati mu oju aja ko ẹkun, ki wọn si bẹrẹ idoola aawọ laarin wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Iroyin kan ni Rauf Aregbesola lo se okunfa ipade naa, ki wahala to n waye laarin oun ati Tinubu le di ohun igbagbe.

Nibi ipade akọkọ naa si ni Aregbesola ba wọn peju si.

Lẹyin ipade naa si ni awọn agbaagba naa ti fi ẹnu ko pe ki wọn tun pe ipade mii laipẹ laijinna.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki lo fa aawọ laarin Aregbesola ati Tinubu:

Lasiko ipalẹmọ fun idibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Osun, ni ariwo ta laarin gomina ipinlẹ naa, Adegboyega Oyetola ati auf Aregbesola.

Asiko naa si ni Aregbesola ti n kede pe Adeoti ni oun fa kalẹ bii oludije ti yoo gba asia ẹgbẹ APC lati soju ipinlẹ Osun ninu ibo gomina ni osu kẹfa ọdun yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Eyi fihan pe aregbesola ko fara mọ saa keji gomina Oyetola, ẹni to ni atilẹyin asaaju ẹgbẹ APC, Bola ahmed Tinubu.

Ọrọ naa di ogun, o di ọdẹ, koda, se ni wọn n fi ibọn le ara wọn kiri saaju ibo abẹnu naa.

Asiko yii naa si ni Aregbesola n fi oko ọrọ ati kobakungbe ransẹ si Oyetola ati Tinubu, eyi to n se ọpọ eeyan ni haa hin.

Amọ lẹyin o rẹyin, Gomina Oyetola lo bori ninu ibo abẹnu naa, to si bori ẹni ti Aregbesola fa kalẹ, lati gba asia ẹgbẹ APC ni Osun lati dije fun ipo gomina ni saa keji.