Kíni òfin Nàìjíríà sọ nípa kí ààrẹ kéde dúkìá rẹ̀ fáráyé?

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Facebook

O ti pe oṣu mẹfa bayii ti aarẹ orileede Naijiria Bola Tinubu gun ori aleefa ti ko si ti kede dukia to ni faraye gbọ.

Ọrọ tawọn ọmọ Naijiria kan n mu bẹnu ree ti wọn si ni aarẹ tapa si ofin ilẹ Naijiria pẹlu ohun to ṣe yi.

Ṣaaju ki a to bẹrẹ apilẹkọ yi to da lori mimọ ohun ti ofin sọ lori kikede dukia lati ọwọ aarẹ tabi ẹlomiran to dipo mu, o ṣe koko ka ṣe alaye kekere kan.

Labẹ ofin Naijiria, ajọ to n mojuto ihuwasi awọn to dipo mu labẹ ijọba ati oṣiṣẹ ijọba bakan naa,CCB, ti la kalẹ pe ki awọn to dipo mu maa kede iye dukia ti wọn ni ki wọn to bẹrẹ iṣẹ.

Eredi eleyi ni ki wọn baa le mọ ti onitọhun ba ko ọrọ jọ lọna aitọ lasiko to wa lori ipo taa n wi yi.

Bi a ba ni pe ẹni to dipo mu gbọdọ kede dukia rẹ, alaye wa lori rẹ.

Ẹ jẹ ka gbọ nkan tawọn to mọ nipa ofin sọ.

Ofin ko ni ki aarẹ kede dukia rẹ faraye gbọ -Amofin

BBC ba Amofin kan to fi ilu Eko ṣe ibudo, iyẹn Monday Ubani.

O ni bi a baa n sọrọ nipa ikede dukia gẹgẹ bi ofin CCB ti ṣe sọ, o yẹ ka yanana rẹ daada.

”Ikede taa n wi yi ni pe ko kọ akọsilẹ ninu fọọmu ti CCB ba gbe le lọwọ eyi ti yoo ṣe atupalẹ iye dukia to ni.”

O ṣalaye pe ko si eeyan kankan to le di ipo aarẹ mu lalae ṣe pe o kọ iye dukia rẹ to ni silẹ.

”Ofin ni.Wọn ko le burawọle sipo fun un gẹgẹ bi aarẹ ti koba kọ iye dukia to ni kalẹ.O le ma wa fi eleyi ṣọwọ saraalu ti ko ba wu lọkan tori pe ofin ko pọn dandan ko kede faraaye gbọ.”

”Ẹni to ba wu ni o le polongo. Bi ko ba wu aarẹ to wa lori oye lati fihan si ọmọ orileede yi, ko si nkankan taa le ṣe fun nitori ofin kii ba ero ọkan ṣiṣẹ bi kii ṣe nkan to ba wa ninu akọsilẹ.Ni akọsilẹ ofin Naijriia lonii, ko ṣe dandan ki o kede dukia rẹ”

Iha wo ni ajọ CCB kọ si ọrọ yii?

BBC kan si Agbẹnusọ fun ajọ CCB, Abilekọ Veronica Kato.

O sọ fun wa ni nkan bi oṣu meloo kan sẹyin nigba ti aarẹ Tinubu de ori oye pe jijẹwọ ohun ini awọn ti araalu dibo yan wa lara eto iburawọle sipo fun wọn.

O ni ọpọlọpọ awọn ti wọn dibo yan naa lo ti wa gba fọọmu ikede ohun ini wọn ni awọn olu ile iṣẹ wọn ni awọn ipinlẹ Naijiria.

O tẹsiwaju pe ikede yi wa ni ibamu pẹlu ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999.

Bẹẹ lo sọ pe iwe ofin Naijiria fi lede pe gbogbo oṣiṣẹ ijọba ni yoo kede awọn ohun ini rẹ kete ti wọn ba ti bẹrẹ iṣẹ ijọba wọn ati lẹyin saa wọn ni ipo.

”Labẹ ofin naa, ẹnikẹni to ba kọ lati kede ohun ini rẹ lo ṣeesẹ ki wọn yọọ ni ipo, ki o si ma lee di ipo miran mu lorilẹede Naijiria.”

Bakan naa ni ajọ ọhun fikun un pe ẹnikẹni to ba kọ lati kede ohun ini rẹ ni wọn ko ni bura wọle fun.

Wọn fikun un pe ofin Naijiria paṣẹ pe ọkan lara eto iburawọle ni ki awọn ti wọn ba dibo yan kede awọn ohun ini wọn.

Yar’Adua, Buhari, Osinbajo kede dukia wọn lasiko ti wọn wa lori oye

Aworan aarẹ tẹlẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Lẹyi taa le yara tọka si gẹgẹ bi apẹrẹ awọn aarẹ ati igbakeji wọn ti wọn kede dukia wọn nigba ti wọn wọle sipo ati lẹyin ti wọn fipo silẹ ni aarẹ to jẹ tẹlẹ ri wa Umaru Musa Yar Adua.

Ninu apẹrẹ to fi lelẹ nigba naa lọhun oun ati igbakeji rẹ Goodluck Jonathan kede faraye gbọ iye dukia ti wọn ni.

Ki aarẹ Buhari to de ori ipo o ṣeleri lati kede dukia rẹ.

Amọ ọrọ ṣebi ni yi pada to si mu ki awọn araalu kan kesi lati ṣika adehun rẹ to ṣe nipa kikede dukia rẹ.

Ni idahun nigba naa lọhun, agbẹnusọ aarẹ Femi Adesina kọkọ sọ pe ko ṣe dandan ki aarẹ jẹwọ dukia rẹ nita gbangba faraalu.

O ni bi o ba wu aarẹ o le sọ ni ikọkọ bo baa si wu o le sọ ni gbangba.

Alaye to ṣe ni pe sisọ tabi kikọ lati sọ ku si ọwọ aarẹ.

Aarẹ Buhari pada yi ipinnu rẹ pada ti awọn agbẹnusọ rẹ si kede rẹ faraaye gbọ.

Tinubu ati awọn eekan mii ti ṣaaju jẹjọ ọrọ dukia lọdọ CCT

Aarẹ lonii Bola Tinubu kii ṣe ajoji si awuyewuye ọrọ kikede dukia lọdọ CCT.

Nigba naa lọhun lọdun 2007 lẹyin to pari saa rẹ gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Eko, ajọ yi pe lẹjọ lati wa sọ idi ti ko fi kede gbogbo dukia rẹ labẹ ofin.

Ninu ẹsun ti wọnfikan Tinubu ni pe o lawọn akoto owo ilẹ okere kan ti ko jẹwọ rẹ gẹgẹ bi tiẹ lasiko to wa lori oye gẹgẹ bi Gomina.

Ẹjọ yi fori sanpọn ti adajọ si ni ki Tinubu maa lọ sile layọ ati alaafia tori pe ko si ẹri wipe oun lo ni akoto owo mẹwaa ti awọn to pe e lẹjọ s pe o kọ lati jẹwọ rẹ.

Yatọ si Tinubu awọn eekan miran ree tawọn naa jẹjọ niwaju ajọ CCT lori ọrọ aikede dukia wọn.

  • Bukola Saraki aarẹ ile aṣofin agba Naijiria tẹlẹ
  • Ike Ekweremadu- Sẹnẹtọ ati igbakeji aarẹ ile aṣofin agba nigba kan ri
  • Sylvester Ngwuta- Adajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria
  • Godsday Orubebe-Minisita fọrọ agbegbe Niger Delta tẹlẹ ri
  • Walter Onoghen- Adajọ agba lorileede Naijiria tẹlẹ ri