Kí ló fa wàhálà láàrín ọlọ́pàá àti Portable, tó fi já ara rẹ̀ sí ìhòòhò?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti fesi si fidio to n ja ranyin lori ayelujara nibi ti gbajugbaja olorin takasufe, Alan Abraham ti ọpọ mọ si Portable, ti fi ẹsun kan awọn ọlọpaa pe wọn fẹ fi panpẹ mu oun ni ọna aitọ.

Ninu Fidio naa, ti Portable funra rẹ gbe sori afẹfẹ Twitter ati Instagram rẹ, lo ti bọ asọ kruo lọrun, to si n laagun bọyọ.

O ni awọn ọlọpaa wa da ile igbafẹ oun ru, ti wọn si fẹ fi panpẹ mu oun ni ọna aitọ.

Ninu fidio naa lo ti n beere ni ọwọ awọn ọlọpaa naa pe ki ni oun ṣe fun awọn ọlọpaa ti wọn ti wa fi panpẹ mu oun.

Ki ni Portable sọ ninu fidio?

Ọmọ ijọba ni mi, ijọba APC ni mo n sisẹ fun – Portable figbe ta fawọn ọlọpaa

Ninu fidio to wa lori Twitter naa ni wọn ti ri Portable to ni awọn ọlọpaa ti wọle tọ oun wa lai nidi, ti wọn si ni awọn fẹ fi panpẹ mu oun.

O fi ẹsun kan wọn pe wọn fẹ wa da ileeṣẹ oun ru ,ki wọn si ko awọn eniyan nibẹ

‘’Ki ni mo ṣe fun ẹyin ọlọpaa, ṣe mo jọ ọmọ Yahoo ni, gbogbo nkan ti mo ni lo gba aṣẹ ijọba, lẹgit ni.

Ki lẹ wa ṣe ni ọfisi mi, ki lo de ti ẹ ni mo wa under arrest? Ki ni mo ṣe fun yin?

Ẹ kan wọle wa lai ro tẹlẹ, kini mo ṣe ti ẹ fi fẹ panpẹ ọba mu mi?

Bakan naa ni Portable n sọ fun awọn ọlọpaa ninu fidio naa pe ọmọ ijọba ni oun, ti oun si ṣiṣẹ fun ijọba APC.

Ohun ti Ọlọpaa sọ ree…

Nigba to n ba BBC sọrọ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, ninu ọrọ rẹ ni Portable n da wahala silẹ ni agbegbe rẹ, ni awọn ṣe fẹ fi panpẹ ọba mu.

Oyeyemi ni igba marun un ni awọn ti kọ iwe ipẹjọ sii lati wa si agọ ọlọpaa amọ o kọ lati yọju si wọn.

O ni awọn tun fi iwe ipẹjọ ranṣẹ si baba rẹ, ti Portable tun kọ lati yọju si agọ ọlọpaa.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa ni ọga ọlọpaa ni ẹka agbegbe Portable, lo ni ẹkunrẹrẹ iroyin ti wọn fi kan an.

O ni ọpọ igba ni Portable ti ran awọn onijagidijagan lati lọ maa lu awọn eniyan, to si n da alaafia agbegbe naa jẹ.

“A ti gba asẹ nile ẹjọ lati fi agbara ofin gbe Portable”

Amọ Oyeyemi ni Baba Portable ti ni ki awọn fun oun di opin ọṣẹ lati mu Portable wa si agọ ọlọpaa lati yọju si wọn.

‘’Portable n da wahala silẹ ni agbegbe rẹ, a si ti gba iwe lati ileẹjọ lati fi panpẹ mu nitori o kọ lati yọju si agọ ọlọpaa.’’

‘’A wa ọlọpaa ko dede lọ si ibẹ, wọn fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa ni to si kọ lati yọju.’’

‘’Niṣe ni Portable bọ ara rẹ si ihoho nigba ti a de ibẹ lati wa fi panpẹ mu, to si bẹrẹ si ni pariwo.’’

‘’ Baba rẹ ti fi da wa loju pe yoo jọju si agọ ọlọpaa titi opin ọṣẹ.’’

‘’Amọ̀ ti ko ba yọju, a o fi tipatipa mu lọ si agọ ọlọpaa lati wa ro ti ẹnu rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an.’’