Iye ìgbà tí àyípadà ti bá orúkọ, àmì ìdánimọ̀ àti àsìá ìpínlẹ̀ Osun

Àmì ìdánimọ̀ ipinlẹ Osun

Oríṣun àwòrán, Osun state government

Kete ti Gomina tuntun fun ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, kede pe ayipada ti ba orúkọ ipinlẹ naa, ati awọn ami idanimọ rẹ, to fi mọ orin ipinlẹ ni ẹnu ti n kun lori rẹ.

Ọjọ Aiku, ọjọ́ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, ni Gomina Adeleke kéde àṣẹ naa, lasiko to n sọ ọrọ akọsọ rẹ lẹyin ti wọn bura fun un tan niluu Osogbo.

Ọdun 2011

Gomina tẹlẹ fun ipinlẹ Osun, Rauf Aregbesola, lo yi orúkọ ipinlẹ naa, ‘Osun State’, pada si ‘State of Osun’ ni ọdun 2011.

‘Osun State’ ni ipinlẹ naa ti n jẹ lati ọdun 1991 ti wọn da a silẹ kuro lara ipinlẹ Oyo.

Yatọ si orúkọ, Rauf Aregbesola tun yi awọn ami idanimọ, ti wọn n pe ni ‘Emblem’ ati ‘Coat of Arms’ ni èdè Gẹ̀ẹ́sì padà.

Bakan naa lo yi orúkọ inagijẹ ipinlẹ naa pada si ‘Land of Virtue’ to túmọ̀ si ipinlẹ Ọmọluabi, dipo ‘State of the Livingspring’, eyi to tumọ si ‘orisun iye’.

Ọpọlọpọ awuyewuye lo waye lori igbeṣẹ Aregbesola, ṣugbọn o mu erongba rẹ ṣẹ.

Ile aṣòfin ipinlẹ Osun lasiko naa buwọlu igbeṣẹ Gomina Aregbesola.

Ọdun 2017

Ni ọdun 2017, ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun, to wa nílùú Ilesa, da ẹjọ́ pe ayipada orúkọ naa ko ba ofin mu.

O si wọgile orúkọ tuntun naa.

Wọn si fi sinu ofin ipinlẹ naa lọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2012.

Abala marun-un si ni wọn pín sí.

Abala akọkọ – Orin ipinlẹ

Abala kejì – Ami idanimọ

Abala kẹta – Àwọn itumọ ati nkan ti eroja to wa ninu asia ipinlẹ naa tumọ si

Lẹyin ikede ti Gomina Ademola Adeleke fi sita lọjọ Aiku lori dida orúkọ, asia ati awọn ami idanimọ ipinlẹ Osun pada si bo ṣe wa tẹ́lẹ̀, iroyin sọ pe ile aṣòfin ipinlẹ naa ti tako o.

Iroyin kan ti BBC ko tii fi mulẹ sọ pe ile aṣòfin ipinlẹ naa ti sọ nibi ijoko wọn pe igbeṣẹ Adeleke ko le ṣẹ.

Ẹni to jẹ alaga igbimọ fun eto iroyin nile aṣòfin naa, Kunle Akande, ni iroyin sọ pe o fi ikede naa sita.

Sugbọn iroyin mii tun sọ pe aṣòfin kan, to jẹ ọmọ ẹgbẹ́ oṣelu PDP, Adewumi Adeyemi, sọ pe ayederu ni nkan ti wọn ni àwọn aṣòfin sọ.

Aṣofin sọ pe ilé aṣòfin ipinlẹ Osun ko tii ṣe ipade kankan tabi jiroro lori ọrọ àkọ́sọ Gomina Adeleke.