Ilé ẹjọ́ rán ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjíríà lọ ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta, ọ̀gá ọlọ́pàá ní òun kò mọ̀ sí ìdájọ́ náà

Aworan ọga ọlọpaa NAijiria ati aworan eto idajọ

Oríṣun àwòrán, Nigeria police/ other

Ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja ti ran ọga agba ọlọpaa Naijiria, Usman Baba Alkali lọ si ẹwọn oṣu mẹta fun ẹsun iwa kotọ si ile ẹjọ.

Ile ẹjọ naa ran ọga ọlọpaa Alkali lọ si ẹwọ fun bi o ṣe kọ lati tẹle idajọ ile ẹjọ kan to ni ko da Patrick Okoli pada si ẹnu iṣẹ rẹ gẹgẹ bi ọlọpaa.

Ki ni adajọ sọ?

Onidajọ Bọlaji Ọlajuwọn, ninu idajọ kalẹ ninu igbẹjọ ẹjọ ti agbẹjọro fun Okoli, Amofin Arinze Egbo pe, kilọ fun ọgaagba ọlọpaa Naijiria pe ko ṣọ fun aibikita si idajọ ile ẹjọ.

Onidajọ Ọlajuwọn ni bi ọga ọlọpaa Alkali ko ba tete wẹ ara rẹ mọ ninu ẹsun aibikiti si idajọ ile ẹjọ naa, oun yoo tun baa fi ẹwọn oṣu mẹta miran lee.

 Ẹjọ wo ni Okoli pe taki Ọga Ọlọpaa Naijiria?

Aworan ileeṣẹ ọlọpaa NAijiria ati aworan eto idajọ

Oríṣun àwòrán, Nigeria police/other

Patrick Okoli pe ọga ọlọpaa Naijiria lẹjọ ninu ipẹjọ kan, FHC/ABJ/CS/637/2009 pe ki ile ẹjọ da oun pada si ẹnu iṣẹ oun gẹgẹ bi ọlọpaa lẹyin to ni wọn yọ oun ni iṣẹ lọna ti ko ba ofin mu lọdun 1992.

O ni igbimọ to ga julọ lẹnu iṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria lo yọ oun niṣẹ lasiko naa ti oun wa nileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Bauchi gẹgẹbi CSP.

O ni bi wọn ṣe fi ipa fi ẹyin oun ti lọdun naa labẹ ofin ologun decree 17 ti ọdun 1984 ko ba ofin mu.

Onidajọ Okorowo to gbọ ẹjọ naa  lọdun 2011 paṣẹ fun ọga agba ọlọpaa Naijiria o da a pada si ẹnu iṣẹ rẹ ni ibamu pẹlu ofin.

A ko mọ ohunkohun nipa idajọ to ni ki wọn da Okoli pada si ẹnu iṣẹ – Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria

Aworan ọga ọlọpaa NAijiria, Usman Baba Alkali

Oríṣun àwòrán, Nigeria police

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa idajọ ile ẹjọ to ni ki wọn da ọlọpaa ti wọn da durio lẹnu iṣẹ lọpọ ọdun sẹyin pada si ẹnu iṣẹ.

Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, CSP Olumuyiwa Adejọbi fi sita sọ pe ọdun 199 ni wọn ti da ọlọpaa naa duro, to jẹ ọdun diẹ lẹyin ti ọga ọlọpaa funrarẹ gan darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa.

 O ni “ọdun 2011 ni idajọ akọkọ lori rẹ waye ti kii si iṣe labẹ akoso adari ọlọpaa to wa nipo bayii nitori naa iyalẹnu nla lo jẹ.”

O ni ọga ọlọpaa Naijiria ti wa ke si ọga ọlọpaa to n mojuto ọrọ ofin lati ṣe iwadii si ọrọ naa lati mọ itgbesẹ to kan