Ìyàwó Adogan tí DSS pa nílé Sunday Igboho ń fi ẹkún bèèrè òkú ọkọ rẹ̀

Adogan ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, iSokan omo Oodua TV

Yoruba ni eeyan mi ko sẹni, eeyan mi ko se eniyan, ko ni jọ̀ alaroo lasan.

Nibayii to ti pe ọjọ mọkanlelọgọrin ti DSS kọlu ile Oloye Sunday Igboho nilu Ibadan, ti wọn si pa eeyan meji, eyiun Alhaji Fatai ati Adogan, ti wọn si gbe oku wọn lọ, ọrọ ti n jẹ jade lori rẹ.

Lasiko yii, iyawo Adogan, Abisola Adisa ti rọ ijọba orilẹede Naijiria pe ki wọn jọwọ oku ọkọ oun silẹ, ki oun le ṣe idaro rẹ bo ṣe yẹ lẹyin iku rẹ.

Ileesẹ Isokan Omo Odua TV lo fi fidio kan sori ayelujara nibi ti iyawo Adogan ti n sun ẹkun kikoro, ti ko si le e sọ ọrọ pupo nipa ọkọ rẹ.

Ọjọ Kini, Osu Keje, ọdun 2021 ni awọn oṣiṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣekọlu si ile Sunday Igboho ni ilu Ibadan, ti wọn si pa Saheed Adisa ti ọpọ eniyan mọ si Adogan.

Adogan to fi aye silẹ naa ni iya, ọmọ mẹta ati iyawo rẹ to fi mọ awọn mọlẹbi miran.

Awọn to wa nibẹ nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni igba mẹjidinlaadọta ni DSS yin ibọn fun Adogan ti ko si ran an, ki wọn to ṣẹṣẹ fọ ọmọ odo mọ lori, ti o si ku.

Ninu atẹjade ti ilana Ọmọ Oodua fi sita lẹyin iku Adogan ni asiko ti awọn DSS n pa Adogan ni Oloye Sunday Igboho ri aaye sa kuro ni inu ile rẹ ni ọjọ naa lọhun.

Wọn ni Ajọ DSS n bẹru lati fi oku rẹ silẹ nitori bi wọn ṣe pa a ko ba oju mu, to si ba ni loju jẹ pẹlu ni wọn ṣe gbe oku rẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Ẹ saanu mi, mo bẹ yin ni o, Adogan ko pa eniyan kii si ṣe onijagidijagan”

Amọ nigba ti wọn kan si iyawo Adogan, oun to ṣọ pẹlu omije loju ni pe oun fẹ ri ọkọ oun boya o wa laaye ni abi o ti ku.

”Oun ti mo fẹ ni pe ki wọn jẹ ki n ri baba awọn ọmọ mi, o tilẹ ni oṣu mẹta bayii ti mo ti ri ọkọ mi gbẹyin”

”Eleyii to ba jasi fun mi, mo sa a fẹ ri ọkọ mi, boya laaye ni tabi oku rẹ.”

”O ni ọmọ mẹta, o si ni iya, ẹ jọwọ ẹ jẹ ki n ri ọkọ mi, oun ti mo fẹ niyẹn.”

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

”Ẹ saanu mi, mo bẹ yin ni o, Adogan ko pa eniyan kii si ṣe onijagidijagan, oniṣowo karakata ọkọ ni ni Osogbo.”

”Ọrọ aje lo ba lọ si ilu Eko, to si ya si ọdọ Oloye Sunday Igboho ni ọjọ ti iṣẹlẹ ibi yii ṣẹlẹ.”

”Mo fẹ ri baba awọn ọmọ mi, ko pa eniyan ri, ẹ saanu mi.”

Isokan Omo Odua TV ni ko si ẹni to mọ ibi ti awọn mọlẹbi naa wa, lọna ati ri pe wọn wa ni ailewu.

Aworan Adigun Oosa ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

Ọjọbọ ọjọ kinni osu Keje ọdun 2021 ni awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS se ikọlu sile ajijagbara to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Sunday Igboho.

Nibẹ si ni wọn ti jẹwọ pe eeyan meji ni awọn pa ninu ile naa nitori wọn di awọn lọwọ lati sisẹ awọn ninu ile ọhun.

Bakan naa ni wọn sọ pe Adogan ko doju ibọn kọ awọn osisẹ DSS gẹgẹ bi wọn se sọ̀