UK gba 8,737 Dókítà láti Nàíjíríà síṣẹ́ láàrin ọdún kan

Awọn dokita to n sisẹ

Oríṣun àwòrán, UCH

O kere tan, awọn dokita onisegun oyinbo bii ọtalelọọdunrun o din meje (253) ni wọn ti fi orukọ silẹ laarin ọgọrun ọjọ lati sisẹ pẹlu ijọba ilẹ United Kingdom.

Gẹgẹ bi oju opo itakun agbaye fun ajọ to n se akoso isẹ isegun nilẹ UK, to maa n fawọn dokita niwe asẹ lati sisẹ ti kede rẹ.

Laarin ọjọ Kẹwa osu Kẹfa si ogunjọ osu Kẹsan ọdun 2021, dokita ọmọ Naijiria bii ọtalelọọdunrun o din meje lo ti gba iwe asẹ lati sisẹ nilẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa, gẹgẹ bi iwe Punch ti salaye, laarin osu keje ọdun 2020 si osu Kẹsan ọdun 2021, awọn dokita to to ọtalelẹgbẹrin ati meji (862) lo ti gba iwe asẹ lati sisẹ ni UK lai naani arun Coronavirus to gbilẹ nibẹ nigba naa.

Lọwọ lọwọ bayii, dokita bii ẹgbẹrun mẹjọ ati ọrinlelẹẹdẹgbẹrin o din mẹta (8,737) ti wọn gba idanilẹkọ nipa isẹ dokita lorilẹede Naijiria, lo ti n sisẹ nilẹ UK.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nigba to n ba iwe iroyin naa sọrọ, igbakeji aarẹ ẹgbẹ awọn dokita to n gba imọ kun imọ ni Naijiria, Julian Ojebo ni o seese ki alekun ba bi awọn dokita se n lọ soke okun laarin ọsẹ melo kan si.

Ojebo ni ti ijọba ko ba san owo osu ati ajẹmọnu to yẹ fawọn onisegun oyinbo naa, o seese ki iye awọn ti yoo gba orilẹede Saudi Arabia lọ gan ju ti UK lọ.

O fikun pe o se ni laanu pe ijọba kuna lati wa ojutu si ohun tawọn dokita naa n beere fun lati ọjọ Kinni osu Kẹjọ ọdun 2021 ti wọn ti bẹrẹ iyansẹlodi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ