Ìyá-ìyàwó kọ ọkọ sílẹ̀ láti fẹ́ ọkọ-ọmọ rẹ̀ ni ariwo bá ta

Loootọ, a maa n gbọ orisirisi iroyin lojoojumọ sugbọn pẹlu gbogbo iriri mi nidi isẹ yii, iroyin yii kamilaya pupọ.- Ọga Hisbah

Aworan ibi igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn mọlẹbi kan nipinlẹ Kano ti fi igbeta lẹyin ti iya kan to jẹ ara mọlẹbi naa kọ ọkọ rẹ silẹ lati fẹ ọkọ ti ọmọ bibinu rẹ fẹ fẹ.

Bakan ni awọn mọlẹbi naa pe akeyesi Hisbah si ọkan lara wọn to jẹ Ọga Hisbah ni ijọba ibilẹ Rano pe oun lo buwọlu igbeyao lai jẹ ki awọn mọlẹbi mọ si

Ọga agba ileeṣẹ agbofinro, Hisbah ipinlẹ Kano, Sheik Harun Ibn Sina sọ BBC pe awọn ti gbe igbimọ kalẹ lati ṣe iwadii lori ẹsun pe obinrin kan kọ ọkọ silẹ lati fẹ ọkọ ọmọ rẹ.

“Ọjọ meji sẹyin ni iroyin naa tẹmilọwọ pe obinrin kan fẹ ọkọ ọmọ rẹ. Ẹsẹkẹsẹ ni mo gbe igbimọ kalẹ lati wadi isẹlẹ naa.

“A ti ransẹ si awọn mọlẹbi mejeeji lati wa wi tẹnu wọn. Awọn igbimọ naa ko nipẹ pari iwadi wọn.

“Lotitọ, a maa gbọ orisirisi iroyin lojojumọ sugbọn pẹlu gbogbo iriri mi nidi isẹ yii, iroyin yii kamilaya pupọ.”

Ki gan lo sẹlẹ?

Ni asalẹ ọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun ọdun 2023 ni ọkunrin kanto orukọ rẹ n jẹ Abdullahi Musa Rano pe wọle si ori redio Freedom nipinlẹ Kano lati bu ẹnu atẹlu bi ọmọ mọlẹbi, Mallam Khadijah ṣe kọ ọkọ rẹ silẹ lati fẹ ọkọ ọmọ rẹ.

Gẹgẹ bi Abdullahi ṣe sọ, ohun itiju gba ni isẹlẹ naa jẹ fun mọlẹbi wa, ti awọn ko si ni fi aye gba rara.

“O mu ọkọ rẹ lọrun lati silẹ, eeyi ti yoo fun ni anfani lati fẹ ọkọ ọmọ rẹ.”

Abdullahi ni iya ọmọ naa fi tipatipa mu ọkọ rẹ lati kọ silẹ lati fun anfani lati fẹ ọmọ rẹ. O ni oun itiju gba lo jẹ fun mọlẹbi naa, ti awọn si ni lati kan si Ọga agba Hisbah ati ijọba ipinlẹ naa lati da si isẹlẹ naa

“Iya ko fẹ ki idile wọn padanuọkunrin gidi lo fi fẹ ọkunrin naa.”

Sabiu Sani, ẹni to jẹ olugbe ijọba ibailẹ naa to mọ nipa isẹlẹ naa ba ileeṣẹ BBC sọri pe nnkan ti oun mọ nipe ọmọbinrin ko fi gbogbo ara nifẹ ọkunrin to dẹnukọ lati fẹ pẹlu gbogbo igbinyanju ọkunrin naa.

“Iya ko fẹ ki idile wọn sọ ọkunrin gidi nu lo fi fẹ ọkunrin naa.”

Sani tẹsiwaju pe nigba ti iya ọmọ ri pe ọmọ oun ko fẹran ọkunrin naa nitori pe o ri ọkunrin naa gẹgẹ ọkunrin gidi, yoo dara ki oun kuku fẹ gẹgẹ bi ọkọ.

Sabiu ni awọn le sọ pato ni bi ti tọkọtaya tuntun naa wa bayii