Orílèèdè Ameͅrika àti Germany ti sͅe ìrànwóͅ ohun ìjà fún Ukraine

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Leͅyin ijiriroro fun bii oͅpoͅloͅpoͅ osͅu, orileͅede Ameͅrika ati Germany ti kede pe awoͅn yoo sͅeranwoͅ ohun ija 30 M1 Abrams tanks fun orileͅede Ukraine to n koju ogun peͅlu Russia.

Aareͅ orileͅede Amerika Joe Biden ni ireti wa pe yoo kede iranwoͅ ati awoͅn ohun ija naa fun Ukraine.

Adari orileͅede Germany, Chancellor Olaf Scholz ni iroyin tig be pe o ti ran ohun ija Leopard 2 tanks  loͅ si Ukraine.

Ireti si wa pe yoo salaye igbeseͅ naa fun Ile Asͅofin ni nkan bi aago moͅkanla ni igba ti woͅn.

Amoͅ orileͅede Russia ni igbiyanju lati bi awoͅn ninu si ni bi woͅn se n fi ohun ija ransͅeͅ si Ukraine.

Bakan naa ni Russia fesi pe igbeseͅ ileͅ Amerika ati Germany yoo mu ki ogun naa tunboͅ gbooro si ni, ti yoo si mu ifaseͅyin ba ibasepoͅ woͅn peͅlu awoͅn orileͅede miran.

Amoͅ orileͅede Ukrain ni awoͅn nilo ohun ija ti yoo mu woͅn koju Russia, ki woͅn le gba awoͅn ilu ti woͅn ti gba loͅwoͅ woͅn pada.

Britain, Poland, Amerika sͅetan lati ran Ukraine peͅlu ohun elo ijagun

Aworan

Titi di asiko yii orileͅede Ameͅrika ati Germany ti koͅ lati dasi ija naa nipa sͅisͅe iranwoͅ ohun ija fun Ukraine.

Bakan naa ni ijoͅba Amerika fikun un pe woͅn nilo oͅpoͅloͅpoͅ imoͅ lati le lo awoͅn ohun ija naa.

Ohun ti o fa ifasͅeͅyin nipa riranwoͅn loͅwoͅ ni lati mase kopa ninu ogun naa, ki Ajoͅ Nato ma ba faragba ninu ogun to n loͅ loͅwoͅ naa.

Amoͅ iroyin fi lede pe o seese ko je Oͅjoͅru ni iranwoͅ fun orileͅede Ukraine naa yoo de ibeͅ.

Woͅn tileͅ fikun un pe o kere tan oͅkoͅ ijangun to feͅreͅ to oͅgboͅn ni woͅn yoo ran loͅ si oju ogun.

Igba ti woͅn yoo gbe awoͅn ohun ija yii de Ukraine ko I tii han si gbangba amoͅ onimoͅ ni oseese ko to bi osu tabi oͅdun ki gbogbo reͅ to yanju.

Iroyin miran lati orileͅede Ameͅrika ni awoͅn osͅisͅeͅ ijoͅba ileͅ Germany ni o digba ti Amerika ba ran ohun ija ti woͅn si Amerika, ki awoͅn to ran ti woͅn naa.

Ni oͅseͅ yii ni Poland kede pe awoͅn yoo ran ohun ija Leopard 2 si Ukraine, amoͅ nitori pe orileͅede Germany lo sͅe ohun ija naa, woͅn gboͅdoͅ buwoͅlu gbigbe lati orileͅede kan si omiran.

Ileͅ Geͅeͅsi ninu oͅroͅ tireͅ ni awoͅn yoo fi ohun ija Challenger two tanks ransͅeͅ si Ukraine.

Ileeͅkoͅ imoͅ nipa eto osͅelu, International Institute for Strategic Studies ni o kere tan orileͅede mͅeͅrindinlogun to fi moͅ Ajoͅ Nato lo ni ohun elo ijagun Leopard 2 tanks naa.

Amoͅ kii se gbogbo woͅn lo sͅetan lati fi ransͅeͅ si Ukraine, amoͅ aaye wa fun awoͅn ti woͅn ba setan lati gbe igbeseͅ naa.