Olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP jáde láyé

Ọ̀jọ̀gbọ́n Uche Ikonne

Oríṣun àwòrán, IKONNE’S MIND

Olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ní ìpínlẹ̀ Abia, Ọ̀jọ̀gbọ́n Uche Ikonne ti jáde láyé.

Kọmíṣọ́nà fétò ìdókoòwò ní ìpínlẹ̀ Abia, John Okiye Kalu fìdí rẹ̀ fún BBC pé lónìí ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kìíní ọdún 2023 ni olùdíje náà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ àìsàn kan tó ti máa ń ṣe é láti kékeré.

Ó ní nǹkan bíi aago mẹ́rin ìdájí ni olóògbé .ọ̀hún mí mímí ìkẹyìn ní ilé ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Abuja.

Kalu ní olóògbé náà ti kọ́kọ́ gba ìtọ́jú ní orílẹ̀ èdè United Kingdom kí àìsàn tó tún padà sí lára èyí.

Ìròyìn ní inú oṣù Kọkànlá ọdún 2022 ni olóògbé náà ti kópa níbi ìpàdé ìta gbangba kẹ́yìn kó tó wá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lónìí.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Kalu ló yẹ kó wà lára àwọn tí yóò kópa níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ láàárín àwọn olùdíje sípò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Abia èyí tí BBC Igbo ṣe lónìí.