INEC bẹ̀rẹ̀ dídán ẹ̀rọ BVAS wò ṣáájú ètò ìdìbò gbogbogboò

BVAS

Oríṣun àwòrán, Others

Àjọ to n ri si eti idibo Naijiria, INEC ti bẹrẹ ayẹwo ẹrọ BVAS eyi ti wọn yoo ṣamulo lati fi ṣeto idibo gbogbogbo ọdun yii.

Ṣaaju ni INEC ti kọkọ kede lọsẹ to kọja wi pe awọn maa dan awọn ẹrọ BVAS naa wo ni ọjọ kẹrin Oṣu keji ọdun yii.

Alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ni gbogbo awọn ẹrọ ti awọn ba lo lati fi ṣe idanwo naa ni awọn maa da pada si bi o ṣe wa tẹlẹ.

Igba akọkọ ti INEC yoo maa ṣe amulo BVAS nibi eto idibo gbogbogboo ni eyi ti yoo waye lọtẹ yii bi o tilẹ jẹ pe wọn ti lo o nibi awọn eto idibo to waye ni awọn ipinlẹ kan laipẹ yii.

Gẹgẹ bi ijabọ awọn akọroyin to ṣe amojuto ayẹwo ọhun ni ni agbegbe Majidadi to wa ni ipinlẹ Bauchi, àwọn oṣiṣẹ ajọ INEC ń lo oju lati ṣe idanimọ wọn ti ẹrọ BVAS ba kuna lati da ika wọn mọ.

Irufẹ idanwo naa waye ni agbegbe Dorayi Karama ni ijọba ibilẹ Gwale, ipinlẹ Kano nibi ti ayẹwo awọn olukopa ko ju iṣẹju kan lọ.

Ni ipinlẹ Rivers ẹwẹ, awọn eniyan tu jade lati kopa nibi idanwo ni wọọdu kẹẹdogun Okwuruozu Playground, Rumuosi, Port Harcourt ni ijọba ibilẹ Obio-Akpor.

Awọn oṣiṣẹ INEC lo wa nibi eto naa lati ṣe ayẹwo bi eto naa yoo ṣe lọ.

Bakab naa ni aṣoju igbimọ to n ṣe agbeyẹwo eto idibo ajọ iṣọkan Yuroopu (EU) naa pejupesẹ nibi eto naa.

Awọn eniyan yo kopa nibi ayẹwo ọhun kan saara si ajọ INEC fun bi ẹrọ BVAS ọhun ṣe n ṣiṣẹ si.

aworan

Oríṣun àwòrán, Others