Ẹ wo orílẹ̀-èdè tí àlùbọ́sà ti wọ́n ju ẹran lọ

Onions

Oríṣun àwòrán, ROLEX DELA PENA/EPA-EFE/REX/Shutterstock

Kaakiri awoͅn orileͅede kọọkan ni agbaye ni aluboͅsa ti jeͅ ohun elo ounjeͅ sise, ti kii sͅe pe o poͅn dandan, amoͅ ni orileͅede Philipine, aluboͅsa ti di oͅwoͅngogo de ibi pe o woͅn ni iye oͅna meji ju eͅran maluu ati eͅran adiyeͅ loͅ.

Bi o tileͅ jeͅ pe ati igba laelae ni lilo aluboͅsa ti jeͅ oͅkan gboogi lara ohun elo ounjeͅ sise ni awoͅn orileͅede Asia, oͅwoͅngogo to mu ki iye ti woͅn ta aluboͅsa naa loͅ soke ju iye ti woͅn n ta eͅran loͅ.

Ni bayii, kilo kan alubosa funfun abi pupa to jeͅ eleyii to woͅpoͅ nibeͅ ti woͅn to dọla moͅkanla owo ileͅ okeere, nigba ti woͅn n ta  odidi adiyẹ ni doͅla meͅrin owo ileͅ okeere.

Aluboͅsa woͅn de ibi pe o ju iye ti awoͅn osͅisͅeͅ n gba lojumoͅ loͅ, eleyii ti ko ju doͅla meͅsan owo ileͅ okere loͅ.

Peͅlu bi aluboͅsa sͅe woͅngogo naa ni ijoͅba orileͅede naa ti beͅreͅ si ni fi oͅwoͅ sinkun ofin mu awoͅn ti woͅn n ko aluboͅsa woͅle lati ileͅ okeere loͅna aitoͅ.

Iye ti woͅn ri gba le ni oͅoͅdunrin loͅna eͅgbeͅrun owo ileͅ okeere, eleyii ti woͅn feͅ gbe woͅle peͅlu oͅgboͅn alumoͅ-koͅroͅyii lati orileede China, ti woͅn si di sinu asͅoͅ.

Onions

Oríṣun àwòrán, ROLEX DELA PENA/EPA-EFE/REX/Shutterstock

‘’A ko feͅ chocolates moͅ, alubosa la feͅ…’’

Lori eͅroͅ ayelujara ni awoͅn araalu ti n dapara lori iye ti woͅn n ta aluboͅsa, ti awoͅn eniyan si n da eͅbi ru ijoͅba ileͅ naa wi pe woͅn ko sͅe to lori oͅroͅ oͅwoͅngogo aluboͅsa oͅhun.

Ohun ti woͅn n soͅ ni wi pe nigba ti iji lile tiba irugbin jeͅ lo ti yeͅ ki ijoͅba gbiyanju oͅna lati ri pe woͅn ko awoͅn ounjeͅ woͅle fun awoͅn araalu, paapaa alubosa ti woͅn moͅ wi pe awoͅn eniyan feͅran lati maa jeͅ.

Loju opo Twitter ni awoͅn ara ilu ti koͅ wi pe, o di gbere fun ṣokoleeti, alubosͅa la feͅ bayii’’

‘Eͅbun ti o ni iyi ti a le mu loͅ si ile bayii ni aluboͅsa kii sͅe ṣokooletii..’’

Oͅkan ninu awoͅn omoͅ ileͅ Philippine to wa ni Ameͅrika ni awoͅn n mu aluboͅsa boͅ  wa fun awoͅn eniyan woͅn ni ile geͅgeͅ bi eͅbun ti awoͅn ba ti Saudi Arabia de.

Bakan naa ni eͅlomiran tun ra igo aluboͅsa to si koͅ oͅ wi pe ‘’ nisinyii ti aluboͅsa ti di goolu, maa ra eyi loͅ si ile lati fun awoͅn moͅleͅbi ati awoͅn ara mi geͅgeͅ bi eͅbun.’’

  Kini nkan miran ti a le lo yatoͅ si aluboͅsa to woͅn gogo?

Nibayii, awoͅn ile ounjeͅ n wa oͅna miran tabi oun elo miran lati lo yatoͅ si alubosa nitori woͅn ko rira ni oͅja.

Bakan naa ni awoͅn miran n wa aluboͅsa ti woͅn n pese labeͅle, eleyii ti woͅn n pe ni lasona to si yatoͅ si eleyii to woͅpoͅ ni awujoͅ woͅn.

Woͅn ni ati ile itaja kekere ati nla ni aisi aluboͅsa yii de ba, ti olukaluku si n wa oͅna miran lati fi sͅe ounjeͅ aladun.

‘’Aluboͅsa sͅe pataki si ounjeͅ ibileͅ wa, ko si ounjeͅ ti a le sͅe lai fi aluboͅsa si, o sͅe Pataki si ounjeͅ awa ara ileͅ Philipines.

Onions

Oríṣun àwòrán, ROLEX DELA PENA/EPA-EFE/REX/Shutterstock

Ki lo fa oͅwoͅngogo aluboͅsa ni agbegbe Philipine?

Awoͅn miran ti da eͅbi ru ijoͅba ati aibikita ti woͅn fi mu oͅroͅ aluboͅsa naa lati ile, eleyii ti woͅn ni o fa iya ati isͅeͅ lorileͅede naa.

Woͅn ni aareͅ to tun di ipo minisita fun oͅrọ eto oͅgbin naa kun peͅlu eͅni to sͅakoba fun ipese aluboͅsa nitori ko moͅ nkankan nipa eto oͅgbin.

Onimoͅ nipa eto oroͅ Aje, Cindy Van Rijswick ni orileͅede Philipines maa n jeͅ aluboͅsa ju bi woͅn sͅe n gbin si loͅ.

Nitori naa oͅpoͅloͅpoͅ igba ni woͅn ma n ko awoͅn ohun elo yii wa lati oke okun.

Ni ọdun 2011, milioͅnu marun-un aluboͅsa ni woͅn ko woͅlu, amoͅ ni oͅdun 2016 nikan, o kere ju , woͅn gbe aluboͅsa to le ni iye 132 million kilos lo ko woͅle.

Lara ohun ti ijoͅba ni o fa oͅwoͅngogo yii ni aisi ilẹ lati gbin aluboͅsa ni reͅpeͅteͅ si iye ti awoͅn eniyan sͅetan lati ra ni ojoojumoͅ.

Bakan naa ni awoͅn ohun elo oko woͅn gogo nitori ogun to n loͅ loͅwoͅ ni Ukraine, ti woͅn ko si le ko awon ohun elo apakokoro, fertilizer woͅle fun idagbasoke eto oͅgbin.