India di orílẹ̀-èdè kẹrin tí yóò wọ inú òṣùpá lágbàyé

Chandrayaan-3

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹ-ede India ti darapọ mọ awọn orilẹ-ede to ti tẹ oju oṣupa lagbaye lẹyin ti ọkọ ofurufu rẹ, Chandrayaan-3, balẹ sinu oṣupa.

Oṣu to kọja ni ọkọ Chandrayaan-3 naa gbera kuro ni India ko to balẹ sinu oṣupa naa ni nnkan bii aago mẹjọ abọ owurọ.

Aṣeyọri tuntun yii ti mu ki India di orilẹ-ede kẹrin lagbaye ti yoo wọ inu oṣupa lẹyin Russia, Amẹrika ati China ti wọn ti kọkọ debẹ ṣaaju.

Amọ ṣa, agbegbe ti India lọ loju oṣupa naa ni wọn n pe ni ‘lunar poles’ eyii to jẹ agbegbe ti orilẹ-ede kankan ko tii de ri.

Olootu ijọba India, Narendra Modi, wa lara ẹgbẹgbẹrun awọn eeyan to n wo bi ọkọ naa ṣe bale soju oṣupa lati ilu Johannesburg, ni South Africa, nibi to ti n kopa ninu ipade ajọ BRICS to n lọ lọwọ nibẹ.

O ni “Fun gbogbo eeyan to wa lagbaye, fun gbogbo eeyan lawọn orilẹ-ede agbaye, aṣeyọri yii kii ṣe ti India, aṣiyọri gbogbo agbaye ni.”

Modi fi kun pe “Gbogbo wa ni a le tiraka lati de inu oṣupa ki a si tun kọja ibẹ.”

India lọ si agbegbe lunar south yii lẹyin ti iwadii kan sọ pe omi tutu wa nibẹ.

Ẹwẹ, ọdun 2019 ni India kọkọ gbiyanju lati lọ sibẹ amọ ẹrọ kan ninu ọkọ ti wọn n gbe lọ kọṣẹ, eyii to mu ki ọkọ naa jabọ loju ofurufu.

Ṣaaju ki ọkọ Chandrayaan-3 ti orilẹ-ede India yii to balẹ sinu oṣupa, Russia naa gbiyanju lati lọ sibẹ, eyii to jẹ igba akọkọ ni aadọta ọdun amọ ọkọ ti wọn ran lọ ja lulẹ.

Bakan naa ni igbiyanju Japan lati lọ sinu oṣupa ja si pabo nigba ti ọkọ oun naa ja lulẹ.