Mọ̀ nípa ìlú tí àwọn òbí ti n ta fídíò bí wọ́n ṣe ń fipá bá ọmọ tí wọ́n bí lòpọ̀

Ile  ajọ alaanu ni Eric ati awọn ẹ̀gbọ́n rẹ n gbé bayii

Ìyá wọn, baba wọn, ìbátan wọn ọkùnrin kan ati obinrin, lo ma n fi ipa ba wọn lòpọ̀, ti wọn o sì tun maa ya fidio wọn.

Ọmọ ọdun mẹwaa ni Eric, o si ti n gbe pẹlu awọn oṣiṣẹ ajọ alaanu fun ọpọlọpọ oṣu.

Ìjọba gba Eric ati ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin, Maria, ati ẹ̀gbọ́n wọn agba meji tó jẹ́ ọkùnrin, nitori bi awọn obi wọn ṣe n fi wọn ṣe iṣẹ́ aṣẹwo.

Fun ọpọlọpọ ọdun, ti gbogbo ara adugbo wọn ba ti sùn, ní ṣe ni wọn ma n fi ipá mu wọn lati ni ibalopọ, ti àwọn to fẹ́ràn ibalopọ pẹlu ọmọdé yoo si maa wo wọn kaakiri agbaye.

Iya wọn lo jẹ oludari iwa burúkú yii.

Baba àwọn ọmọ naa lo pada lọ tu àṣírí iyawo rẹ ati awọn ẹbi rẹ fun awọn ọlọpaa, lẹyin ti aarin wọn daru.

Iwadii awọn ọtẹlẹmuyẹ tu asiri bi ẹbi naa ṣe n gba owo lati orile-ede UK ati Switzerland, lọwọ àwọn to n wo fidio ìbálòpọ̀ àwọn ọmọ naa.

Oṣù diẹ lẹyin ti ọwọ tẹ àwọn ẹbí wọn, ni awọn ọmọ naa di èèrò ile ajọ alaanu Charity Preda, to n ṣe itọju àwọn ọmọ to ti la ifipa banilopọ kọja.

Ọmọdé kan ninu marun-un ni wọn fi n se òwò ibalopọ ni Philippines

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iru nkan bayii wọpọ ni orile-ede Philippines, obitibi biliọnu Dọla si ni wọn fi n pa.

Ìwádìí fihan pe orile-ede naa ni lilo àwọn ọmọdé fun òwò ibalopọ, pọ si julọ ni agbaye.

Ìṣẹ́, ẹ̀rọ ayelujara ati gbigbọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, lo tun n mu ko pọ si.

Ajakalẹ aarun COVID-19, to fa isede fun bi ọdun meji tun mu ko pọ si, nitori pe àwọn ọmọde ko raaye lọ si ile ẹ̀kọ́, ti wọn si n wa nile pẹlu awọn obi to nílò owo.

Iwadii ti ajọ Unicef ati Save the Children ṣe, fihan pe ọmọdé kan ninu marun-un ni orile-ede Philippines, lo wa ninu ewu òwò isẹ aṣẹwo.

Nitori eyi, Aarẹ Bongbong Marcos ti kede ‘ogun’ lori biba ọmọdé ni ibalopọ, ati ẹka ọrọ aje tó ti da silẹ.

Ori ilẹ̀ ìsìnkú ni ọwọ ti tẹ mọ́lẹ̀ bí míì

Nílùú Manila, aarin òru ni awọn oṣiṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ National Bureau of Investigation, yabo ilẹ isinku kan.

Àwọn pẹlu ìbọn ati ẹ̀rọ ayaworan ni wọn lọ, lati le ri ẹri pe lootọ ni wọn n fi awọn ọmọ naa ṣe iṣekuṣe.

Ori ilẹ isinku naa ni ẹbi yii n gbe. Wọn kọ́ ile kekere kan ti wọn fi igi ṣe si ara ògiri iboji kan.

Lasiko ti àwọn agbofinro de ibẹ, iya wọn, to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlogoji, n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ lori ẹ̀rọ ibanisọrọ si onibaara kan ni Australia.

Onibaara naa n beere fun afihan fidio bi ìbálòpọ̀ àwọn ọmọ rẹ mẹtẹẹta ṣe n waye.

Sugbọn obinrin yii ko mọ pe ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni oun n ba duna-dura.

Bo ṣe tan ẹ̀rọ ayaworan lati ma safihan àwọn ọmọ naa, ni awọn ọlọpaa yabo ẹnu ọ̀nà rẹ.

Lara awọn nkan ti wọn ba ninu ile naa ni irinsẹ ibalopọ (sex toys), foonu, akọsilẹ àwọn owo ti wọn san fun lati ilẹ̀ okeere.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Australia sọ fun BBC pe ọwọ wọn tẹ ọkùnrin kan ni papakọ ọkọ ofurufu, fun pe o ni ẹ̀rọ kan to kun fun fidio ifipa ba awọn ọmọde lopọ.

Wọn ní foonu rẹ naa ni awọn atẹjiṣẹ ti oun ati obinrin kan ni Philippines, fi n duna-dura owo lori àwọn fidio naa.

Ìjọba orile-ede Australia sọ pe akọsilẹ ti àwọn ní nípa fifi awọn ọmọde ṣe òwò ibalopọ, ti le ni ìdá mẹrindinlaadọrin, laarin ọdun kan.

Wọn si ti n ṣiṣẹ́ pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ajọ

International Justice Mission, UK National Crime Agency ati awọn ọlọpaa orile-ede Netherlands ati Philippines, ki ọwọ le tẹ àwọn to n fi fidio ibalopọ ọmọdé ṣe owo.

Ti ọwọ ba ṣe n tẹwọn, ni wọn n wadii orisun àwọn fidio ti wọn n wò.

Ni ọpọ igba, ọna kan ṣoṣo ti àṣírí fi n tu, ni ti ọmọdé kan ba jade sọ nkan ti oju rẹ n rí. Àmọ́ eyi jẹ nkan ti kii sábà waye.

Ogunlọgọ àwọn òṣìṣẹ́ ajọ alaanu sọ pe ọpọlọpọ ọ̀sẹ̀ ati wahala lo ma n gba ki awọn ọlọpaa agbegbe to o gba lati dóòlà awọn ọmọde, ati lati fi ẹ̀sùn kan àwọn obi wọn.