Ijàmbá ọkọ̀ bàálù gbẹ̀mí Ọgagun Kenya, Francis Ogolla

Aworan

Oríṣun àwòrán, AFP

Ọga agba ileeṣẹ ologun orilẹede Kenya, Ọga agba Francis Omondi Ogolla jade laye lẹyin ti ọkọ baalu ja lulẹ ni ẹkun iwọ oorun orilẹede naa.

Aarẹ orilẹede Kenya, Williams Ruto naa lo kede isẹlẹ naa, to si sapejuwe isẹlẹ to mu ẹmi ọgagun gẹgẹ eyi to gba omije loju.

Ogolla ni Ọga ologun to lagbara ju lorilẹede Kenya, to si wa ninu baalu naa pẹlu eeyan mọkanla sugbọn meji ye ninu wọn.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Aarẹ Williams Ruto ni isẹlẹ naa waye ago 14.20 (11.20 GMT). IkỌ ologun ofurufu Kenya ti gbe bayii lati lọ ṣe iwadii ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Baalu naa ja ni agbegbe Elgeyo Marakwet, ilu ti ko jina si olu ilu Kenya ni isẹju diẹ to gbera.

Ninu oṣu kẹrin ọsun to kọja ni wọn yan Ogolla lẹyin to ṣe Ọga ileeṣẹ ologun ofurufu ati igbakeji ọga ologun.

Ruto sapejuwe ọga ologun to di oloogbe gẹgẹ bii akikanju to jade laye lasiko to n siṣẹ ilu.

“Orilẹede wa ti padanu awọn ọmọ ogun to jantọ, ẹyin ara ilu, lọkunrin, lobinrin,” Ruto sọ fun gbogbo

Orilẹede Kenya yoo bẹrẹ idaro ọlọjọ mẹta lati ọjọ Ẹti, ti wọn yoo si gbe asia orilẹede naa si idaji.

Ọdun 1984 ninu oṣu kẹrin ni Ogolla kọkọ darapọ mọ ileeṣẹ ologun gẹgẹ bii opo ayelujara ileeṣẹ ologun ṣe gbe sita.

Ọsẹ to n bọ ni yoo pe Ogoji ọdun to darapọ mọ Ileeṣẹ ologun.

Awọn eeyan mẹsan an to jade laye pẹlu ọga ologun naa ni Brig Swale Saidi, Col Duncan Keittany, Lt Col David Sawe, Maj George Benson Magondu, Capt Sora Mohamed, Capt Hillary Litali, Snr Sgt John Kinyua Mureithi, Sgt Cliphonce Omondi, ati Sgt Rose Nyawira.

Awọn meji ti wọn farapa nibi iṣẹlẹ naa lo wa ipo ki ko dara sugbọn ti wọn n gba itọju.

Awọn ologun lo gbera lati lọ si apa Ariwa Kenya nigba ti awọn agbebọn ti n sọsẹ.

Wọn fẹ lọ si Ile ẹkọ to wa ni titi pa nitori ikọlu awọn agbebọn ni agbegbe naa.

Ninu oṣu kẹfa ọdun 2021, o to ọmọ ologun mẹwaa to padanu ẹmi wọn nigba ti baalu wọn ja nigba to fẹ balẹ ni olu ilu, Nairobi.