Ooni sọ̀rọ̀ lórí bí ó ṣé ń ṣé ètò ìlú pẹ̀lú ètò àwọn ayaba l’ààfin

Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi sọrọ bi iṣẹ ilu ati iṣẹ inu Ile ko ṣe fi igba kankan di arawọn, to n si n ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bii ọkọ ati olori ilu.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Ooni ni Ọlọrun Olodumare atawọn oosa ilẹ Yoruba lo n ba oun ṣe ti ikankan ko fi di ara wọn lọwọ.

Bẹẹ ba gbagbe, nibi ọdun diẹ sẹyin ni Ooni fẹ awọn olori mẹfa ọtọọtọ, ti ọkan lara wọn si bi ibeji laipẹ yii.

Aworan

Oríṣun àwòrán, BBC/Others

“Ọlọrun lo n fun mi ṣe, Ọlọrun n feto si.

“Eto naa, o dẹ n lọ ni irọwọrọsẹ, ko si nnkan to le laye yii, ti ko ki n dẹrọ.

“Gbogbo kudiẹkudiẹ naa, Ọlọrun Olodumare n bami yanju ẹ.”

“Ọpọ n lo n fi mi pawo lori ayelujara ti wọn ba ti darukọ mi”

Ọba Adeyeye Ogunwusi ni bi ọpọ awọn eeyan ṣe n darukọ oun lori atelujara lo jẹ ọna atijẹ fun wọn, si jẹ pe pupọ wọn n fi orukọ oun pawo ni.

Ooni tẹsiwaju pe ohun ti ọpọ awọn eeyan to wa lori ayelujara ko mọ ni pe idakeji Ọọni ko dara pupọ, koda ko dara rara.

“Ti n ba ni ka bẹrẹ si n binu si gbogbo wọn lori ayelujara, ọpọlọpọ wọn lo n jẹẹja.

“Ọmọde bu iroko, o boju wo ẹyin, ko mọ igba ti Oluwẹri maa ja.

Ọọni Ogunwusi ni pupọ awọn eeyan yii ni ko mọ itumọ Oọni sugbọn o ṣe koko kan maa mu ilu dun lọ.

“Sugbọn wọn muludun ni, awọn naa ọna atijẹ ni.”

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí