Ọ̀gá ọlọ́pàá pàṣẹ kí àwọn ẹ̀sọ́ ààbò tó wà lẹ́yin Yahaya Bello kúrò

Aworan Yahaya Bello ati awon osise aabo

Oríṣun àwòrán, Others

Ọga ọlọpaa patapata lorileede yii, Olukayọde Ẹgbẹtokun ti paṣẹ pe ki gbogbo oṣiṣẹ aabo ti wọn jẹ ọlọpaa to wa lẹyin gomina ana nipinlẹ Kogi, Yahaya Bello kuro.

Yahaya Bello ni ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria fi ẹsun jibiti owo to le ni diẹ ni ọgọrin biliọnu (80.2n) naira kan, ti wọn si ti kede rẹ gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa.

Ọga ọlọpaa lo kede pe ki awọn ọlọpaa to n ṣọ gomina ana naa kuro lẹyin rẹ ninu atẹjade ti nọmba rẹ jẹ CB:4001/DOPS/PMF/FHQ/ABJ/VOL.48/34, eyi ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe jade laarọ oni, ọjọ Ẹti, gẹgẹ bi iwe iroyin PUNCH ṣe kọ ọ.

Atẹjade ọhun sọ pe “Ọga ọlọpaa ti paṣẹ pe ki gbogbo ọlọpaa to wa lẹyin gomina nipinlẹ Kogi, Alaaji Yahaya Bello kuro.

“Ẹ gba atẹjade yii, ki ẹ si ṣiṣẹ lee lori bi eyi to ṣe pataki. Ẹ jọwọ, ohun to wa loke yii, fun ohun ti ẹ ni lati tẹle ni.”

Ṣaaju asiko yii ni ileeṣẹ aṣọbode orileede yii ti sọ pe awọn ti bẹrẹ sii tọpinpin gbogbo igbesẹ gomina tẹlẹri naa lẹyin ti ajọ EFCC ti kede rẹ gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa.

Atẹjade ti ileeṣẹ aṣọbode gbe jade naa lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin la gbọ pe igbakeji ọga agba, DS Umar buwọ lu lorukọ ọga patapata, Kẹmi Nandap.

Nibẹ ni wọn ti ṣapejuwe idanimọ Yahaya Bello, orukọ rẹ, nọmba iwe irinna rẹ (B50083321).

“Wọn ti fun mi ni aṣẹ lati jẹ ki ẹ mọ pe ẹni ti orukọ rẹ wa loke yii ti di ẹni ti a gbọdọ maa tọpinpin rẹ.

“Mo fẹ sọ fun un yin pe ẹni yii ni wọn fẹẹ fi oju rẹ ba ile-ẹjọ giga apapọ to wa niluu Abuja lori ẹsun igbimọpọ ati ṣiṣẹ owo mọkumọku ninu ẹsun ti nọmba rẹ jẹ CR; 3000/EFCC/LS/EGCS.1/ TE/Vide/1/279, eyi ti wọn gbe jade lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2024.

“Bi ẹ ba rii ni ẹnu ọna abawọle tabi abajade kankan, ẹ ni lati fi ofin gbe e, ki ẹ si tare rẹ si alakoso to n ri sọrọ iwadii tabi ki ẹ pe awọn nọmba wọnyi 08036226329/07039617304 fun igbesẹ to kan.”