Iṣẹ́ fíìmù ló sọ mi di Babaláwo, Wòlíì Ọlọ́run ni mi – Adewale Alebiosu

Gbajumọ Babalawo ninu fiimu Yoruba ni Adewale Alebiosu amọ ti gbogbo eeyan maa n pe ni “Awo lọjọ”.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pẹu BBC Yoruba, o ṣalaye idi ti awọn eeyan ṣe maa n ro pe Babalawo gaan ni loju aye tabi ki baba rẹ jẹ bẹẹ.

“Igba ti mo ṣetan lọdọ ẹni to kọkọ kọ mi niṣẹ ni mo lọ ba gbajumọ oṣere ti gbogbo eeyan mọ si Lalude, ibẹ ni mo ti bẹrẹ si ni kọ bi wọn ṣe n pa ọfọ”.

Adewale Alebiosu

Bawo lo ṣe jẹ to di Wolii?

Alebiosu ṣalaye pe Musulumi ni baba ati iya to bi oun lọmọ toun funra oun gan tẹlẹ si jẹ ẹlẹsin musulumi.

“Wọn n ṣe ikore ni ṣọọṣi kan ni ti wọn o si rẹni ba wọn lu ilu ni alagba kan wa tọka si mi ladugbo pe oni tiata ni mi o si yẹ ki n le lu ilu”.

Alebiosu ni ibi ilu ni inu ile ṣọọṣi ti n yipo loju to si ba ara rẹ nilẹ gẹgẹ bi ẹlẹmii to n jiṣẹ iranṣẹ fawọn eeyan ninu ijọ lọjọ naa.

“Igba ti mo dide ni wọn sọ gbogbo ohun ti mo sọ fun, aṣe mo ti n sọ “bayii ni Oluwa wi.”

O sọ bi awọn eeyan ṣe maa n ro pe oun gbona ninu iṣẹ awo amọ to ni ko ri bẹẹ.

Adewale Alebiosu

‘Bí àwọn oṣere ẹgbẹ mi ba ran mi lọwọ ni, o yẹ ki emi naa ti di olowo’

“Ti wọn ba pe mi sode, wọn a rii pe ọkọ ero tabi ọkada lo gbe mi wa, a wa ya wọn lẹnu pe bi mo ṣe to, mi o ni mọto, amọ emi o nifẹ igbe aye “fake”.

O ṣalaye pe awọn ti oun kọ niṣẹ gan ti ra ọkọ ti wọn fi n ṣe ẹsẹ rin.

Bakan naa lo sọ idi ti awọn oṣere obinrin fi lowo lọwọ ju awọn ọkunrin lọ.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí