Ṣé òtítọ́ ní pé Ọlọ́pàá ṣekúpa èèyàn kan ni ààfin Ọba Ikirun?

Aworan

Niluu ikirun, nipinlẹ Osun lana, wahala Ọlọbade gba ọna miran yọ lẹyin ti awọn janduku kan ṣe ikọlu si aafin Akinrun ti ilu Ikirun, ti wọn si dana sun un.

Ọpọlọpọ awuyeawuye lo ti tẹyin ikọlu naa jade, ti awọn eeyan si fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe wọn ṣekupa ọmọba kan, ti orukọ rẹ n jẹ Lukman Olatunji.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe bii osẹ diẹ sẹyin ti awọn eeyan ilu ọhun ṣe ifẹhonuhan lori bi wọn ṣe yan ọba tuntun, wọn gbe adagagodo si ẹnu ọna aafin, eyi ti ko fun Ọba tuntun ni anfani lati wọle si aafin.

Bakan naa ni iroyin ọhun ni awuyewuye miiran bẹ silẹ lana lẹyin ti Ọba ati awọn ọlọpaa fẹ wọle si aafin, ti wọn si ṣina bolẹ lati ṣeruba awọn olufẹhonuhan ṣugbọn ti ibọn ba Olatunji, to si jade laye.

O to eeyan mẹrin miiran to farapa yanayana nigba ti awọn ọlọpaa fẹ gba akoso Aafin naa.

Igbesẹ awọn ọlọpaa yii ni o bi awọn ọdọ ilu ninu, ti wọn si dana sun Aafin Ọba lana, eyi to tun da kun rogbodiyan naa.

Oṣojumikoro, Gboyega Adebayo, nigba to ba ikọ oniroyin Punch sọrọ salaye pe oun fẹ lọ ran nnkan ni oun ṣalabapade awọn ọlọpaa ti wọn lọ si aafin, ti ọkan lara wọn yin si lọ ṣekupa ọmọba Olatunji.

“Ọta ibọn awọn ọlọpaa lo ṣekupa Olatunji, to si gbẹmi mi lẹsẹkẹsẹ.

“Awọn ọlọpaa lọ pe jorinjorin pe ko wa si ilẹkun aafin ọhun. Wọn bẹrẹ si maa yinbọn bolẹ lati sẹruba awọn eeyan, eyi ti ibọn ọhun ti wọn yin ṣe eeyan mẹrin miiran leṣe.

Ẹgbọn Olatunji, Tajudeen Gboleru ba ikọ oniroyin Punch sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ, o ni nigba ti awọn ọlọpaa gbinyanju lati wọ aafin ni wọn yin ibọn fun aburo.

“Eeyan kan lo wa si aafin pẹlu awọn ọlọpaa ati awọn ọmọ ologun, ibọn lara ọkan lara si lọ ba aburo mi”.

Ẹwẹ, nigba ti akọroyin BBC Yoruba, Olasunkanmi Ogunmoko yoo fi de ibẹ, awọn ọlọpaa tun ti gbakoso gbogbo agbegbe naa ti wọn ko si jẹ ki awọn oniroyin sunmọ ibẹ.

Kini ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ naa?

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Yemisi Opalola ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin ni ileeṣẹ ọlọpaa ko le ṣekupa ẹnikẹni ati pe awọn lọ sibẹ lati lọ daabo bo awọn to ṣe atunṣe si aafin naa ni.

“Kọmiṣana ileeṣẹ ọlọpaa fẹ pe akiyesi awọn si iroyin ofege kan pe awọn ọlọpaa ṣina bolẹ fun eeyan niluu ikirun.

“Otitọ ibẹ ni pe nigba ti awọn ọlọpaa kan lọ daabo bo awọn to n ṣe atunṣe si aafin Akinrun, awọn afurasi agbebọn janduku ṣina bolẹ fun awọn ọlọpaa, ti ibọn si ba meji laarin wọn, Obajobi ati Raji Abiodun.

“Ti wọn si gbe wọn digbadigba lọ si ile iwosan fun itọju. Awọn janduku yii wa gbera lati lọ dana sun aafin, ti wọn si tun kọlu awọn osisẹ panapana meji, Orunwumi Roseline ati Abel Olayinka .

Opalola ni Kọmiṣana ti wa rọ awọn obi ati alagbatọ lati kilọ fun awọn ọmọ wọn ki wọn dẹkun iwa ibajẹ ati jadijagan. O ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ko ni muu ni kekere fun ẹnikẹni ti iwadii ba fihan pe o lọwọ ninu ikọlu naa.