Ẹnikẹ́ni tí kò bá ní káàdì NIN kò ní gba ”passport” àti ìwé-àṣẹ ìwakọ̀ ní Nàìjíríà- NCC

Kaadi idanimọ

Oríṣun àwòrán, NATIONAL IDENTITY MANAGEMENT COMMISSION

Ajọ NCC to n ri ileeṣẹ eto ibaraẹnisọrọ lorilẹede Naijiria ti sọ pe ẹnikẹni to ba kuna lati gba kaadi idanimọ NIN ko ni lanfaani lati iwe irinna ati iwe-aṣẹ iwakọ mọ.

Adari ẹka to n ri si ọrọ to kan araalu fun ajọ NCC, Ọmọwe Ikechukwu Adinde ṣalaye pe ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹwaa si ni awọn eeyan ni lati gba kaadi NIN wọn.

Ọmọwe Adinde ni ijọba apapọ si wa lori ẹsẹ rẹ pe ọjọ yii lawọn araalu ni da lati so nọmba kaadi idanimọ wọn pọ mọ opo ẹrọ ibanisọrọ wọn.

Ọmọwe Adinde ni ”laipẹ lai jina, awọn ti wọn ko tii ni kaadi idanimọ NIN ko ni lanfaani lati lo ọpọ nkan mọ ni Naijiria.

Lara awọn nkan ti wọn ko ni lanfani lati maa lo mọ ni iwe irinna ati iwe-aṣẹ iwakọ wọn.”

Ti ẹ ko ba gbagbe, lọjọ kẹẹdogun oṣu kejila, ọdun 2020 ni ijọba apapọ paṣẹ fawọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ lati ju oju opo gbogbo awọn eeyan ti ko tii so opo wọn pọ mọ nọmba kaadi idanimọ wọn.

Lati igba naa ni ijọba ti n sun gbedeke ọjọ tawọn eeyan ni lati so nọmba kaadi NIN wọn pọ mọ oju opo ẹrọ ibanisọrọ wọn.

Nigba ti o n sọ nipa iwulo kaadi idanimọ fawọn araalu, Ọmọwe Adinde ni kaadi NIN yoo jẹ ki eto abo gberu sii ni Naijiria.

Bakan naa lo sọ pe kaadi idanimọ NIN jẹ ọkan lara ọna ti ijọba apapọ fẹ lo lati ri pe awọn araalu ri ipa ijọba lara wọn.

Efosa Idehen to jẹ ọkan lara awọn eekan lajọ NCC naa ṣalaye pe o maa ṣoro fawọn agbofinro lati mu awọn ọdaran ti ko ba ni kaadi idanimọ.

Ọga agba ajọ to n ṣakoso kaadi idanimọ, NIMC nipinlẹ Eko, Funmi Opesanwo, sọ pe siso nọmba kaadi NIN mọ oju opo ẹrọ ibanisọrọ yoo daabo bo araalu lọwọ gbajuẹ.