Èmi ni mo fi ẹjọ́ Portable sun ọlọ́pàá, ìwà ìkà tó hù fún mi rèé – Manny Monie

Aworan Portable ati Manny Monie

Oríṣun àwòrán, Twitter/Portable/Manny Monie

Ni ọjọ Isẹgun ni olorin takasufee nni, Habeeb Okikiola, tọpọ mọ si Portable figbe bọnu pe awọn osisẹ ọlpaa fẹ mu oun nile ijo oun.

Ninu fidio kan to gbe soju opo Instagram rẹ bi isẹlẹ naa se n waye, lo se afihan ọpọ igbesẹ to gbe lati di awọn osisẹ ọlọpa naa lọwọ lati mu.

Ninu fidio naa si lo ti n pariwo pe ta lo fi ẹjọ oun sun awọn ọlọpaa, iru ẹsẹ wo si ni wọn ni oun sẹ, ki awọn ọlọpaa naa se wa mu oun.

Bi o tilẹ jẹ pe ileesẹ ọlọpaa ko darukọ ẹni to wa fi ẹjọ Portable sun ni agọ wọn amọ ẹnikan ti jade sita pe oun ni oun lọ fi ẹ́ẹjọ akọrin naa sun awọn ọlọpaa.

Ọkan lara awọn ọmọlẹyin Portable tẹlẹ, Manny Monie, ninu fidio kan to gbe sooju opo Instagram rẹ lo fidi ọrọ naa mulẹ.

O ni oun ni oun fi ẹsun kan Portable nile iṣẹ ọlọpaa, ti wọn se fẹ fi panpẹ ofin mu.

Ki ni Portable se, ti Manni Money se fi ẹjọ rẹ sun ọlọpaa?

Aworan Manny Monie ati Portable

Oríṣun àwòrán, Instagram/Manny Monie

Portable pe mi ni ọmọ Yahoo, ba irinsẹ orin mi jẹ – Manny Monie

Emmanuel Oluwafemi, ti awọn ololufẹ rẹ mọ si Manny Monie, lo jẹ ọkan lara ọmọ olorin labẹ ileeṣẹ orin Zeh Nation, to jẹ ti Portable tẹlẹ, ki ija to waye laarin wọn.

O fi ẹsun kan Portable pe o pe oun ni ole ati onijibiti lori ayelujara, ti ọpọ mọ si YahooYahoo ati awọn ẹsun miiran to jẹ mọ bi Portable ṣe lo agbara lati gba irinsẹ rẹ to to ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin naira.

Ninu fọnran kan to fi sita lẹyin isẹlẹ naa to waye ni ile ọti Portable, Manny Monie salaye pe irọ to jina si ootọ ni Portable pa mọ oun pe ọmọ yahoo ni oun lẹyin ti awọn ọlọpaa se abẹwo sọdọ Portable.

Manny Monie ni ọpọ igba ni ileeṣẹ ọlọpaa ti fi iwe abẹwo ransẹ si Portable sugbọn to kọ lati da wọn lohun.

Fidio isalẹ yii ni Mannie Money gbe soju opo Instagram rẹ lati salaye ohun to pa oun ati Portable pọ. Ẹ fọwọ kan-an

“Portable ati awọn ọmọ ẹlẹyin rẹ lu mi ni ilu bara”

Manny Monie tẹsiwaju pe oun mu ẹjọ Portable lọ si ileeṣẹ ọlọpaa nitori Portable n dunkoko mo oun, to si tun ran awọn tọọgi kan lati ba fiya jẹ oun.

Ninu iwe ti Manny Monie kọ si ileeṣẹ ọlọpaa, o ni awọn tọọgi Portable da oun lọna, ti wọn si wọ oun lọ iwaju Portable nibi to ti ni ki wọn lu oun ni ilu ibara.

O fikun pe Portable n fi afọku igo le oun kiri, ti oun si rapala kuro ni ile itura kan ni agbeagbe ilugbo ni ijọba ibilẹ Ewekoro.

“Ẹgbọn ati awọn mọlẹbi mi lo gbe mi lọ si ile wosan nibi ti mo ti gba itọju.”

Aworan Iwe ẹsun Portable

Oríṣun àwòrán, Instagram/Manny Monie

“Irinsẹ mi to to 844k ni Portable gba lọwọ mi”

Manny Monie ni lasiko ti ibasepọ oun ati Portable gun rege, oun ra irinsẹ orin to le ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin Naira fun Ile orin Portable.

Sugbọn Manny Monie ni Portable kọ lati gbe irinsẹ naa silẹ nigba ti ija waye.

O ni ko si adehun kankan laarin oun ati Portable sugbọn oun ba a sisẹ pupọ ki oun to kuro ati ipe fun iwe adehun gan lo fa ija laarin awọn mejeeji.

“Portable na mi, o fiya jẹ mi, gba irinsẹ mi lọwọ mi.

“Lati ọdun to kọja ni oṣu kejila ni a ti kọ iwe ẹsun naa si ileeṣẹ ọlọpaa.

“Portable tun parọ mọ mi lori ayelujara lori nnkan ti n ko se rara.”

Aworan iwe ọja

Oríṣun àwòrán, Instagram/Manny Monie

Portable sẹ sofin pẹlu iwa rẹ, a si fiya to tọ jẹ ẹ labẹ ofin – Ileeṣẹ Ọlọpaa

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọrọ sita lẹyin ti Habeeb Okikiola ti ọpọ mo si Portable kọ lati tẹle awọn ọlọpaa to se abẹwo si ile ọti rẹ niluu Sango Otta.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan to fisita.

Oyeyemi ni bi Portable se ja ara rẹ si ihoho ati bi o se kuna lati tẹle ofin orilẹede Naijiria ni o lodi sofin .

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe ni igba marun un ọtọtọ ni awọn ransẹ si Portable, to si kọ lati yọju si awọn,ko le wa wi tẹnu rẹ.

“A ransẹ pe Baba rẹ pe ko ba wa pe sugbọn sibẹ ko da wa lohun rara.

“Lẹyin ti a ko ri, ni a mori le ileẹjọ, ti a si gba asẹ lati lọ gbe Portable ni ile rẹ.

“Kete ti ikọ ọlọpaa wa de si ọdọ Portable, ni o ja ara rẹ si ihoho, to si bẹrẹ si ni ma pariwo fun awọn ọlọpaa naa.”