Ẹ̀ wo ayàwòrán tó kọ́ ilé rẹ̀ bíi ‘’camera’’ tó sì sọ àwọn ọmọ rẹ̀ ní orúkọ àwọn ‘’camera’’

Ẹ̀ wo ayàwòrán tó kọ́ ilé rẹ̀ bíi ‘’camera’’ tó sì sọ àwọn ọmọ rẹ̀ ní orúkọ àwọn ‘’camera’’

Aworan

Arakunrin Ravi Hongai to jẹ ayaworan lorilẹede India to ti mu ifẹ rẹ fun iṣẹ to yan laayo lọ si ipele miran.

Hongai to ni afojusun oun fun ọjọ to ti pẹ ni ki oun kọ ile to ri bi ẹrọ ayaworan, ‘’Camera’’ to si se bẹẹ gẹgẹ.

Ile nla to kọ naa ni o dabi camera, to si ri gbogbo awọn ẹya Camera lara.

Ko tan sibẹ, arakunrin ayaworan naa to bi ọmọ mẹta, tun sọ orukọ awọn ọmọ mẹtẹẹta ni awọn orukọ Camera to lamilaaka bi Nikkon, Epson ati Canon.

Ẹ wo fidio yii fun ẹkunrẹrẹ ohun miran ti awọn mọlẹbi n ṣe pẹlu iṣẹ ayaworan ti wọn yan laayo…

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí