Ìdí tí àwọn ólóyún kan fí fẹ́ràn láti bí ọmọ sọdọ àwọn ìyá Àbíyé rèé…

Aworan Oloyun

Itọju to pe tí awọn iya agbẹbi ma fun awọn oloyun jẹ ìdí kan pataki ti Christiana Indukari Peter fi ma lọ forukọ silẹ fun itọju.

Ọmọ meji ni Christiana tí bí, to si tun wa ninu oyun oṣu mẹfa pẹlu ọmọ kẹta sugbọn ni gbogbo igba, o maa lọ ọdọ Iya Ayenmiye Onini, iya abiye ẹni aadọrun ọdun ni ẹgbẹ omi Afikpo niluu Port Harcourt.

Christiana sọ fun BBC pe Iya Ayenmiye lo sọ oun pe ki oun forukọ silẹ nitori oloyun nílo itọju to peye ni ile iwosan.

Aworan Oloyun

“Awọn ile iwosan yii dara pupọ nitori bi wọn ṣe fun eeyan ni abẹrẹ, ni wọn ṣe ayẹwo ti wọn si tun ṣe ifunpa sugbọn iya yii ma fi ọwọ tẹ gbogbo ara mi. Wọn yoo tun yẹ oyun inu wo lati ri pe ibi to yẹ ko wa lo duro si, eyi ni idi ti mo fi kundun lati ma lọ si ibẹ pe ki wọn ba mi wo ara mi dada.”

O fikun pe ọdọ Iya abiye yii ni oun ti bí awọn ọmọ oun meji nitori aṣalẹ ni oyun ma mu oun ti yoo si nira fun lati lọ ile wosan sugbọn ọdọ Iya abiye wa ni tosi.

Eyi lo jẹ ko gba ọdọ Iya abiye lọ lasiko to ni oyun ẹlẹkẹta

Nnkan kan naa lo jẹ lọdọ Ukeme Oto ti oun naa wa ninu oyun oṣu mẹfa.

O ni ti ara ba n ro oun ti o si lọ ile wosan, wọn yoo fun ogun sugbọn ara riro naa ko ni lọ ayafi to ba lọ sí ọdọ Iya abiye ti wọn ba fi ọwọ tẹ gbogbo ara rẹ.

“Lẹyin ti Iya ba tẹ gbogbo ara mi tán,ara riro yoo lọ. Titẹ naa dara pupọ.”

Iya Ayenmiye ma tẹ gbogbo ara lati ori de ẹsẹ nitori o ni gbogbo ara lo wa pẹlu arawọn.

Aworan bí wọn ṣe tẹ ara oloyun

Ẹbun ni titẹ ara ati itọju oloyun ninu mọlẹbi mi

Aworan Oloyun

Fun Iya Ayenmiye, ẹbun Ọlọrun ni titẹ ara ati sise itọju awọn oloyun lati bímọ pẹlu irọnu.

O ni ọdun 1979 ni oun mọ pe oun ni ẹbun yìí nigba to ran oloyun ti oun mu lojiji lọwọ lati bi ọmọ rẹ.

O tẹsiwaju pe Baba ati Iya ni ẹbun naa ti wọn si gbe fun oun naa sugbọn ọdọ kọ lo kọ isẹ naa.

“Ẹbun Ọlọrun, a ko le fi owo ra tabi ki a lọ kọ, o ma wa ba eeyan ni. Fun àpẹẹrẹ, ninu mọlẹbi mi, ki ṣe gbogbo awọn ẹgbọn ati aburo mi lo ni ẹbun yii sugbọn emi ni. Ọdọ awọn ọmọ mi gan an, ki ṣe gbogbo wọn lo ṣe ìsẹ yii.”

Awọn Iya abiye nilo idanilẹkọọ

Iya Ayenmiye ni oun naa ti gba idanilẹkọọ lọwọ ijọba to si ran lọwọ ninu bí o ṣe gba ẹbi awọn oloyun.

“Níbi idanilẹkọọ naa ni wọn ti sọ fun wa o ni bi oloyun yoo se wa tí a ní lati sọ fun pe ko ma lọ ile wosan lati doola ẹmi iya ati ọmọ nitori ti oloyun ba ku si ọdọ wa, Ọlọpaa yoo gbe wa. Idi ti mo fi kí awọn oloyun lọ forukọ silẹ ni ile wosan ijọba nìyẹn.

“Ti oloyun ba de ọdọ mi, ma ni kí o lọ sí ile wosan ijọba lọ forukọ silẹ. N ko fẹ ni oku eeyan lọrun. Lati igba ti mo ti n gba ẹbi, iya tabi ọmọ ko ku lọwọ mi rí.”

O ni idanilẹkọọ ti oun lọ gbẹyin ni ti ìjọba ìpinlẹ Bayelsa gbe kalẹ lọdun 2013, ti wọn si pín awọn irinsẹ igbalode fun awọn.

Bakan naa lo rọ ìjọba lati ma dẹkun sise idanilẹkọọ ati iranlọwọ fun ìya abiye lati le sisẹ wọn daada.

“Idanilẹkọọ tí Dokita fun wa se iranlọwọ pupọ lati mọ ibi tí a ku si ati awọn nnkan ti a le se.

“Yoo dara pupọ tí ìjọba ba tun tẹsiwaju pẹlu idanilẹkọọ paapaa fun ewe to n sẹsẹ bọ lẹyin wa lati oye sì “