Ẹ san N30m owo ‘gbà má bínú’ fún Ọlọ́kadà tí Amotekun mọ̀ọ́mọ̀ yìnbọn lù – Iléejọ́

Ọkunrin ti wọn yinbọn lu

Oríṣun àwòrán, Amotekun

Ileẹjọ giga nipinlẹ Ondo ti paṣẹ pe ki ijọba ipinlẹ Ondo ati ileeṣẹ eto aabo, Amotẹkun san ọgbọn miliọnu naira gẹgẹ bi owo gba ma binu fun arakunrin kan ti Amotekun yinbọn lu lọna aitọ.

Oluṣẹgun Oluwarotimi, to jẹ ọlọkada, lo gbe ijọba ati Amọtẹkun lọ si ileẹjọ lẹyin ti o di ẹlẹṣẹ kan nitori Amotẹkun yinbọn lu.

Ileẹjọ ni arakunrin ẹni ọdun mẹrindinlogoji naa ni Amotẹkun yinbọn lu ni ọna aitọ.

Isẹlẹ ibọn yinyin naa lo waye ni ọjọ kẹsan, oṣu kẹjọ ọdun 2021 ni Ilu Akure.

“Ẹ san N20m bii owo gba ma binu ati N10m mii bii owo itanran fun ọlọkada naa lati kọ ara yoku lọgbọn”

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Adejumo ni bi wọn ṣe yinbọn lu ọlọkada naa tako ẹtọ rẹ gẹgẹ bi ọmọ eniyan.

‘’Nitori naa, ileẹjọ paṣẹ ki awọn ti wọn fi ẹsun kan naa san ogun milion naira gẹgẹ bi owo gba mabinu.

Ẹ tun san milion mẹwaa naira mii fun gẹgẹ bi owo itanran lati fi kọ ara iyoku bii tiyin lọgbọn.’’

Amọ ileẹjọ fagile ibeere olupẹjọ naa pe ki ijọba tọrọ aforiji lọwọ oun ninu iwe iroyin to gbajumọ lorilẹede Naijiria, adajọ ni ko si ohun to jọ bẹẹ.

‘’Mo dupẹ fun idajọ yii nitori Amotẹkun sọ mi di ẹlẹṣẹ kan pẹlu iyawo ati ọmọ meji’’

Agbẹjọro fun olupẹjọ wa dupẹ lọwọ adajọ pe wọn da idajọ ododo lori iṣẹlẹ naa, to si ni oun mọ pe gomina Akeredolu yoo gbọ aṣẹ ileẹjọ.

O ni bio tilẹ jẹpe o dara bi wọn ṣe da Amotẹkun silẹ amọ wọn ko gbọdọ ṣi iṣẹ ṣe tabi yinbọn lu araalu lọna aitọ.

Ninu ọrọ rẹ, arakunrin to gbe ijọba ati Amotẹkun lọ si ileẹjọ, ni inu oun dun pe idajọ ododo bori lori iṣẹlẹ naa.

O ni igbagbọ oun ni pe awọn ọmọ oun mejeeji ti ko lọ si ileekọ mọ nitori oun ko le san owo ileẹkọ wọn yoo pada si ileẹkọ laipẹ ti ijọba ba ti san owo gba ma binu ọhun.

Oluwarotimi sọ bi Amotẹkun ṣe sọ ohun di ẹlẹṣẹ kan

Arakunrin Oluwarotimi ni oͅloͅkada ni oun ti oun si n gbe eniyan wa si agbegbe Araromi ni ilu Akure.

‘’Ibi ti mo ti n wa bi mo se feͅ fun eͅni ti mo gbe ni senji, ni mo ti gboͅ ti awoͅn eniyan beͅreͅ si ni sa kitakita kiri pe Amoͅteͅkun ti de.’’

‘’Ki n to wo eͅyin, ni oͅkan lara awoͅn Amoteͅkun naa doju iboͅn koͅ mi, to si nipe ki n doju boleͅ abi ki oun foͅ eͅseͅ oun.’’

‘’Ki a to wi ki a to foͅ, woͅn ti yinboͅn lu mi ni eͅseͅ, ti eͅjeͅ si beͅreͅ si ni yoͅ, ti mo si wa ninu irora.’’

‘’Leͅyin naa ni woͅn gbe mi loͅ si agoͅ woͅn, ti woͅn si fi mi sileͅ ninu irora.’’

Ọlọkada naa wa tẹsiwaju pe leͅyin naa ni woͅn gbe oun loͅ si ile iwosan ni Owo.

Amoͅ o ni awoͅn dokita ile iwosan FMC nilu Owo naa ti beͅreͅ iyanseͅlodi, ti oun si wa ni iroͅra fun oͅjoͅ marun un.

‘’Awoͅn moͅleͅbi mi to ti n wa mi lo sawari mi ni ileewosan naa, ti eͅseͅ naa si ti n jeͅra.’’

‘’Nigba ti a de ileewosan aladani woͅn ni oͅna abayoͅ ni ki woͅn ge eͅseͅ naa, ki oun fi le wa laaye.’’