NÍ YÀJÓYÀJÓ Agbébọn tó pa èèyàn mẹ́fà ló ń gba ìtọ́jú àrùn ọpọlọ lọ́wọ́ nílé ìwòsàn – Ọlọpàá

Copyright: Reuters

Kò dín ní ènìyàn
mẹ́fà, àwọn ọmọdé mẹ́ta àti òṣìsẹ́ mẹ́ta ti pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani
tó wáyé nílé ẹ̀kọ́ kan ní ìlú Nashville, Tennessee, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.

Ìròyìn ní akẹ́kọ̀ọ́jáde
ilé ẹ̀kọ́ Covenant ló wà nídìí ìṣekúpani náà.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí
iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní wọ́n bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ ni Evelyn Dieckhaus, Hallie Scruggs
àti William Kinney.

Tí Cynthia Peak,
Katherine Koonce àti Mike Hill sì jẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ náà tó pàdánù ẹ̀mí
wọn sínú ìkọlù náà.

Ilé ẹ̀kọ́ tó jẹ́
ti ẹ̀sìn ló ní akẹ́kọ̀ọ́ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ta sí ọdún méjìlá tó
fẹ́ẹ̀ tó igba.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
ní afurasí tó ṣekúpa àwọn ènìyàn náà, Audrey Hale ló jẹ́ ènìyàn tó ṣe àyípadà
ara rẹ̀ láti obìnrin sí ọkùnrin, tó sì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n.

Copyright: Metropolitan Nashville PD

Afurasí náà wá ọkọ̀
Honda lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà tó sì fi ìbọn fọ́ ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà tó wà ní títì pa wọlé
tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yìbọn mọ́ àwọn ènìyàn tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún.

Bí àwọn ọlọ́pàá ṣe
ń dé sí ilé ẹ̀kọ́ náà ni Hale tún kọjú ìbọn síwọn tí gíláàsì tó yìbọn mọ́ kan ṣe
ọlọ́pàá kan léṣe.

Èyí ló mú kí àwọn
ọlọ́pàá yìbọn bá òun náà tó sì gbabẹ̀ kú.

Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá
Nashville, John Drake ní àwọn tó ń ṣèwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàwárí àkọ́ọ́lẹ̀ bí Hale
ṣe gbèrò láti mú ìkọlù náà wáyé, ọ̀nà tí yóò gbà wọlé àti bí yóò ṣe jáde.

Bákan náà ni wọ́n
tún bá ìbọn mìíràn nínú ilé Hale yàtọ̀ sí mẹ́ta tó kó kọ́ra nígbà tó le ṣe ìkọlù
náà nígbà tí wan ṣe àbẹ̀wò sí ilé ìgbé rẹ̀.

Nínú àtẹ̀jáde kan,
Mayor Nashville, John Cooper ní ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ pé ìpínlẹ̀ àwọn ti wà lára
àwọn ìpínlẹ̀ tí ìṣekúpani bẹ́ẹ̀ ti wáyé.

Ààrẹ Amẹ́ríkà, Joe
Biden ní àwọn gbọ́dọ̀ wá ọ̀nà láti fòpin sí bí àwọn ènìyàn ṣe ń lo ìbọn láti fi
ṣiṣẹ́ ibi, tó sì rọ àwọn aṣòfin láti ṣòfin tí yóò dá lórí fífi òfin de ìbọn lílò.

Copyright: Reuters

Copyright: Getty Images