Báwo ni ohun ìjà olóró Iran ṣe lágbára tó sí ti Israel?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ado oloro ti Iran ju lati fi kọlu Israel, eyi to bẹrẹ lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtala, oṣu kẹrin tun ti gbe ibẹrubojo sọkan awọn eeyab ni aarin gbungbun Ila-Oorun.

Bo tilẹ jẹ pe ko si awọn to farapa pupọ to bẹẹ ni Israel, ṣugbọn awọn ado oloro wọnyi ti jẹ ko di mimọ pe Iran kaju oṣuwọn lati ṣe ikọlu lati ọna to jin.

Eyi ni wọn lo jẹ ikunsinu to ti wa nilẹ tipẹ, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe awọn ẹgbẹ kan ti wọn sọ pe ọmọ Iran ni wọn ṣe ikọlu si Israel, ati pe awọn ikọlu miran to tun waye ni Iran ni wọn fi ẹsun rẹ kan Israel.

Israel ti fi ara jin si ogun to n ṣẹlẹ ni Gaza, bẹẹ si lo tun n koju ija to n fi gbogbo igba pọ si lẹnubode pẹlu awọn ẹgbẹ ogun Hezbollah lati Lebanon.

Olori awọn oṣiṣẹ ologun nilẹ Israel, Lt Colonel Herzei Halevi ti sọ pe orileede oun yoo da ikọlu ti wọn ṣe wọn lọjọ Satide pada, bo tilẹ jẹ pe ko sọrọ pupọ lori eyi.

Ṣugbọn ṣa, igbakeji minisita fọrọ ilẹ okeere, Ali Bagheri Kani, ti sọ fawọn akọroyin ileeṣẹ amohunmaworan orileede naa pe awọn yoo da ikọlu Israel pada laarin iṣẹ-aaya, kii ṣe wakati rara

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn wo ló ni agbára báyìí?

BBC ti ṣagbelewọn ibeere yii nipa lilo awọn ibi aritọkasi to wa nisalẹ yii, bo tilẹ jẹ pe awọn orileede yii ni wọn ni awọn ohun ti wọn n wo

Ajọ International Institute for Strategic Studies (IISS) ṣapejuwe agbara awọn ohun ija oloro ileeṣẹ ologun orileede mejeeji yii nipa lilo ọrọ awọn agbẹnusọ, ati awọn miran to ṣee tọka si lati fi gbe abajade wọn sita.

Awọn ileeṣẹ miran, bii Stockholm International Peace Research Institute, naa tun ṣagbeyẹwo loriṣiriṣi, ṣugbọn ti wọn ko tii le sọ pato eyi ti wọn yoo fidi rẹ mulẹ

Ju gbogbo rẹ lọ, Nicholas Marsh lati Peace Research Institute Oslo (PRIO), sọ pe IISS ni wọn ri gẹgẹ bi ibi aritọkasi lati mọ bi agbara awọn oṣiṣẹ ologun kaakiri agbaye ṣe gbe iwọn si.

Aworan

IISS sọ pe Israel maa n na owo gidi si ẹka eto aabo wọn ju Iran lọ.

IISS ṣalaye pe eto iṣuna eto aabo ilẹ Iran lọdun 2022 ati 2023 jẹ biliọnu meje le diẹ owo dọla ($7.4b), nigba ti Israel ni ilọpomeji eto iṣuna yii, to si to biliọnu mọkandinlogun dọla ($19b).

Aworan F-35 plane

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọna igbalode ti wọn n lo

Akọsilẹ IISS jẹ ko di mimọ pe Israel ni awọn ọkọ baluu ologun to le ni ọọdunrun (340 military aircraft) nilkẹ lati fi koju ogun, eyi to fun wọn anfaani ati agbara lati gbe ogun dide nigbakugba.

Lara awọn ọkọ baluu ija ologun naa ni F-15-planes to le ran ogun niṣẹ lọ si ọna to jin, F-35s-high tech “stealth” planes to le da ikọlu duro – ati awọn baluu agberapa ti wọn le fi koju ogun pajawiri.

IISS ṣalaye pe Iran ni to ẹgbẹrun lọna ọọdunrun le ni ogun (320) awọn baluu oju ogun.

Awọn baluu yii ni wọn ti wa lati ọdun 1960s, lara rẹ si ni F-4s, F-5s ati F-14s.

Ṣugbọn Nicholas Mars ti ileeṣẹ PRIO sọ ninu ọrọ rẹ pe awọn ko le pato iye awọn baluu to le fo ninu awọn wọnyi, nitori pe ọna lati tun wọn ṣe yoo ṣoro pupọ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ohun ija Iron Dome ati Arrow

Awọn ohun ija oloro ti wọn pe ni Iron Dome ati Arrow systems ni ẹṣọ ologun Israel gbojule

Mẹkaniiki awọn ohun ija oloro ti Missile, Uzi Rubin nlo da ileeṣẹ Missile Defense Organization ti ilẹ Israel silẹ.

Ni bayii, ọkan lara awọn oluwadii agba ni Jerusalem Institute for Strategy and Security, sọ fun BBC nipa bi ọkan oun ṣe balẹ lori aabo nigba toun ri bi wọn ṣe n lo Iron Dome pẹlu iranlọwọ awọn oluranlọwọ agbaye, lati fi koju awọn ohun ija oloro ti Iran fi ranṣẹ si Israel pada lọjọ Satide.

“Ọkan mi balẹ, inu mi si dun…ọna ara ọtọ ni wọn fi n lo lati fi koju awọn ohun ija oloro to ba n bọ. Ko si lẹlẹgbẹ si ti awọn orileede miran.”

Aworan

Oríṣun àwòrán, Amir Cohen / Reuters

Bawo ni Iran ṣe jina si Israel?

O le ni ẹgbẹrun meji kilomita to wa laarin Iran si Israel. Ado oloro nikan ohun ija ti wọn le kọlu orilẹede naa, Tim Ripley, to jẹ ọga iwe iroyin Defence Eye.

Map showing Iran, Israel and neighbouring countries

Ado oloro to wa lati Iran ni igbagbọ wa pe ohun lo tobi ju ni ẹkun Middle East.

Ni ọdun 2022, Ọgagun Kenneth McKenzie ti ileeṣẹ ologun US Central ni Iran ni o le ni ẹgbẹrun mẹta ado oloro.

Gẹgẹ bii CSIS Missile Defense Project, Israel ti kọ awọn ado oloro wọle lati awọn orilẹede mii.

Aworan

Oríṣun àwòrán, EPA

Awọn Ado oloro Iran

Iran ni gbe awọn igbesẹ lori iṣeTo ado oloro wọn lati aye wọn pẹlu orilẹede Iraq , eyi to waye ni ọdun 1980 si ọdun 1988.

Wọn ti sẹda awọn ohun ija kekere ati nal, to jẹ si je pe lara wọn ni wọn fi ranṣẹ si Isael

Awọn oniwadii ṣe iwadi lori awón ado oloro ti ikọ agbebọn Houthi fi kọlu Saudi Arabia, to si jẹ orilẹede Iran ni wọn ti wa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters