Mọ̀ nípa Tunde Onakoya tó fi ìtàn GWR balẹ̀ lórí eré Chess

Tunde Onakoya nibi idije Chess

Oríṣun àwòrán, TUNDE ONAKOYA

Ọmọ orilẹede Naijiria, Tunde Onakoya ti fi itan Guinness World Record balẹ lori gbigba ere Chess fun wakati to pọ julọ lagbaye.

Tunde Onakoya lo fidi iroyin loju opo ayelujara x

O ni, “A ti ṣe.

“A si n lọ ọgọta wakati. A ko ti duro rara. Ẹ jẹ ka tẹsiwaju.

“A si n lepa owo ti a n da jọ fun eto ẹkọ awọn ọmọde ni ilẹ Afrika ni gbogbo agbaye. Idi kan ti a fi n ṣe eyi niyẹn.

“Ẹ jẹ ka fihan agbaye irufẹ agbara ti ifẹ ni. Pẹlu ajọṣepọ wa, eyi ma wa si imusẹ.

Onakoya ti ni bori wakati ti awọn ọmọ orilẹede Norway, Hallvard Haug Flatebo ati Sjur Ferkinstad, to gba ere Chess fun wakati mẹrindinlọgọta ni ọdun 2018.

Bawo ni irinajo naa ṣe bẹrẹ?

Ní ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 ni èèkàn nídìí eré ìdárayá ‘Chess’, Tunde Onakoya fi sórí ayélujára pé òun fẹ́ gba àmì Guiness World Record fún ẹni tó díje fún Chess fún wákàtí tó pọ̀ jùlọ.

Onakoya ní wákàtí méjìdínlọ́gọ́ta ni òun fẹ́ fi ṣe ìdíje Chess láì ní pàdánù rárá àti pé ní gbàgede Times Square ní New York City ni ìdíje náà yóò ti wáyé.

Ó ní nítorí àwọn ọmọdé tọ wà ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí wọn kò ní àǹfàní láti kàwé ni òun ṣe ń ṣe ìdíje náà.

Mílíọ̀nù kan dọ́là ni Onakoya ń gbìyànjú láti kó jọ láti fi ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀kọ́ chess káàkiri àgbàyé.

Ó ní òun gbàgbọ́ pé gbogbo àwọn ènìyàn tó ti ń ṣe àtìlẹyìn fún òun láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni wọ́n tún máa dúró ti òun lórí èyí tí òun gbé dání yìí bákan náà.

Tunde Onakoya nibi idije Chess

Oríṣun àwòrán, TILTIFY/TUNDE ONAKOYA

“A nílò láti jẹ́ kí gbogbo àgbàyé mọ̀ pé ẹ̀mí ìṣe tó wà nínú ọmọ Nàìjíríà le koko àti pé a lè ṣe ohun ńlá níbi tí a bá fi ọkàn wa sí.”

Òdú ni Tunde Onakoya, kìí ṣe àìmọ̀ fún olóko nídìí eré ìdárayá Chess ní ẹkùn Áfíríkà àti òkè òkun.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó fi mọ́ igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà, Atiku Abubakar, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo, Tony Elumelu, gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, BabaJIDE Sanwo-Olu àtàwọn míì ni wọ́n ti ń kọrin àtìlẹyìn fún Tunde Onakoya lórí ohun tó gbé dání.

Ní aago mẹ́wàá òwúrọ̀ ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kẹrin ni ìdíje náà bẹ̀rẹ̀, tó sì wá sí òpin ní aago mẹ́jọ alẹ́ ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Kẹrin.

Ta ni Tunde Onakoya?

Tunde Onakoya

Oríṣun àwòrán, Tunde Onakoya

Tunde Onakoya ni olùdásílẹ̀ ‘Chess in slums Africa’.

Agbo tálákà ni Tunde Onakoya ti dàgbà kó tó di wí pé o rí ọ̀nà Chess gẹ́gẹ́ bí ohun tó le mu kúrò nínú ìṣẹ́ àti ìyà.

Èyí ló mu dá Chess in Slums kalẹ̀ lọ́dún 2018. Tunde ní ìdí tí òun fi da kalẹ̀ ni pé gbogbo ọmọdé lọ yẹ kọ ní àǹfàní sí ìgbé ayé tó dára.

Nínú ìwé kan tó kọ nípa eré Chess èyí tí Bloomsbury bá a tẹ̀ jáde lọ́dún 2019, Tunde sọ níbẹ̀ pé ìgbágbọ́ òun ló mú òun gbé ọ̀nà kan kalẹ̀ nípa eré Chess láti fi máa gbé agbára wọ àwọn ọmọdé tó wá láti ìdílé tálákà nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àti ìrònùjinlẹ̀ tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ lọ́jọ́ ọ̀la.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ àti àjọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ bíi tòun ni wọ́n ń fi eré Chess ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́.

Ó ní inú òun dùn pé òun nìkan kọ́ ni chess mú ìgbé ayé òun yí padà, pé òun ní àǹfàní láti ran ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn míì lọ́wọ́.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni Tunde Onakoya ti mú ìgbé ayé yí padà àmọ́ èyí tó gbajúmọ̀ jùlọ ni Fawaz Adeoye tó jẹ́ agbèrò ọkọ̀ tẹ́lẹ̀ ní Eko àmọ́ tó ti di ògbóǹtarìgì nídìí Chess báyìí.