Wọ́n ní wọ́n ti ń mú ‘kinní’áwọn ọkùnrin Ghana mọ́ wọn lára láàrin ọjá áti ígboro

Aworan ọwọ ti wọn fi ṣẹkẹṣẹkẹ si

Oríṣun àwòrán, Getty Image

Lati nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni ariwo ti n gbode kan lawọn agbegbe kan ni Ghana, pe wọn n mu ‘kinni’ awọn ọkunrin mọ wọn lara laarin ọja ati nigboro.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, awọn agbegbe tiṣẹlẹ naa ti n ṣẹlẹ ju ni Kasoa ati Madina.

A gbọ pe nnkan ọkunrin yoo ṣadeede poora lara wọn ni, bawọn to n mu kinni naa ba ti le fọwọ kan wọn laarin ọja tabi nigboro.

Ninu awọn fidio kan to gbilẹ lori ayelujara, awọn kan ti wọn ni nnkan ọmọkunrin awọn ti poora han nibẹ.

Bẹẹ ni wọn n lu ọmọkunrin kan pe ko jẹwọ ẹṣẹ rẹ.

Wọn loun lo mu ohun tawọn fi n jẹ ọkunrin lọ.

Agbegbe Kasoa yii jẹ ibi kan ti iwa ọdaran oriṣiiriṣii gbilẹ si ni Ghana.

Ibẹrubojo si ti gba ọkan ọpọ eeyan niluu naa pẹlu ohun ti wọn lo n ṣẹlẹ yii.

Igbimọ ilu ni ko sohun to jọ bẹẹ

Igbimọ kan ti wọn n pe ni Ewutu Senya ni Ghana, to n ri si idari awọn agbegbe naa, sọ pe ko sẹni kan ti wọn mu ‘kinni’ rẹ lọ ninu awọn ọkunrin ilu awọn.

Atẹjade ti wọn fi sita ṣalaye pe ko si ẹri kan lati ileewosan to tọka nnkan ọmọkunrin to sọnu laduugbo awọn.

“ Kẹnikẹni ma ṣe gba iroyin ofege to n lọ nipa nnkan ọmọkunrin to n sọnu gbọ, irọ gbuu ni.

“ A ko ti i ri ileewosan kan to fidi iṣẹlẹ bẹẹ mulẹ lagbegbe wa yii, ẹ ma gba irọ gbọ o.”

Bayii ni igbimọ Ewutu Senya fi ọkan awọn eeyan rẹ balẹ.

Ṣugbọn pẹlu ohun ti wọn wi yii, awọn eeyan ṣi n fẹsun mimu nnkan ọmọkunrin kan ara wọn lawọn agbegbe naa.

Ọlọpaa ko eeyan mẹsan-an,wọn ni wọn purọ pe wọn mu nnkan awọn

O kere tan,eeyan mẹsan-an ni wọn ti ko sakolo ọlọpaa bayii lori esun naa, gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe wi.

Kaakiri awọn agbegbe mi-in ti ariwo iṣẹlẹ yii ti n waye ni wọn ti ṣa awọn eeyan mẹsan naa.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn purọ pe wọn ti mu kinni awọn lọ, nigba ti kinni ọhun ṣi wa nibẹ digbi, to n gberi.

‘’Sisọ ohun ti ko ṣẹlẹ le ko ipaya ba awọn eeyan, o si le da omi alaafia ilu ru.

Iwadii ati esi latọdọ awọn ileewosan ti fidi ẹ mulẹ pe irọ lawọn eeyan yii n pa.”

Bẹẹ ni atẹjade ọlọpaa wi.

Ninu awọn mẹsan-an to wa lakolo ọlọpaa yii, mẹfa wa ni Kasoa, (Aarin gbungbun)meji wa ni Ashaiman, ni Accra, nigba ti ẹnikẹsan-an wa ni Nkawkaw, lapa Ila Oorun Ghana.

Ki lawọn dokita wi nipa pipoora nnkan ọmọkunrin?

Alaye awọn eleto ilera nipa ki nnkan ọkunrin poora ni pe o ṣoro ki wọn fọwọ kan nnkan ọmọkunrin eeyan ko si poora.

Dokita Albert Sedohia, onimọ nipa ọpọlọ, ṣalaye pe ero ọkan eeyan nigba to ba ti rẹ eeyan gan-an le jẹ ko ronu ohun ti ko ṣẹlẹ.

“ O ṣee ṣe kawọn eeyan yii ni idaamu ọkan kan, o si ṣee ṣe ki wọn ronu pe nnkan ọmọkunrin awọn gberi”

‘’Nigba mi-in, wọn le sọ pe nnkan ọmọkunrin awọn kere si i, to ba si ya, yoo tun pada si bo ṣe yẹ.

“ Eeyan kan o le fọwọ kan nnkan ẹlomi-in ko waa poora,ero ọkan lasan ni’’

Bẹẹ ni Dokita Sedohia wi.

Ẹ o ranti pe iroyin nnkan ọmọkunrin pipoora yii ti gbode kan lorilẹ-ede Naijiria naa ri, ko too dohun to lọ sokun igbagbe bayii.