‘Àwọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá nílò láti múra kí ìṣẹ̀ṣe má ti ọwọ́ wọn parun’

Awọn oniṣẹṣe

Arọwa ti lọ sọdó awọn Ọba alade nilẹ Yoruba lati maa ṣe amojuto, ki wọn si kiyesi ara lati ma jẹ ẹ ki aṣa Yoruba ti ọwọ wọn parun.

Ààrẹ àwọn Oníṣẹ́se nipinle Osun lo gba àwọn Ọba Aládé nimọran bẹẹ pé kí wọ́n sọra gidigidi láti má sọ àṣà àti ìṣe Yorùbá nù nípasẹ̀ dídá si ọ̀rọ̀ Òṣèlú.

Àràbà awo ti ìlú Osogbo, Ifayemi Elebuibon nínú ọ̀rọ̀ tirẹ naa ni ọ̀pọ̀ àwọn ọba Yorùbá ni wọn kò fẹ́ fi ààyè gba àṣà ati Ìṣẹ̀ṣe láàyè ni ilu ati ni gbogbo àgbègbè won.

O ni ti wọn ko ba tete wa wọrọkọ fi ṣàdá lori ọrọ yii, awọn ọba yoo tẹ aṣa àti iṣe Yoruba ri lai kiyesi.

Bákan náà ni Asiwaju Awo Àgbáyé, Ifagbenusola Atanda tí sọ̀rọ̀ lórí ìjà ń tọ lọ lọ́wọ́ nílùú Ilorin nipinle Kwara pé kí wọ́n kó gba àlàáfíà láyé kí ìjọba Ìpínlẹ̀ ṣe idajọ tó tọ́ kí àlàáfíà lè jọba nílùú Ilorin.

Ọ̀rọ̀ láti orí ìtẹ́ èyí tí Ifá sọ fún tọdun yìí láti ẹnu àwọn Olupena Awo ni pé ìrètí wá fún Orile-ede Naijiria pé yóò dára.

Ifá tún sọ̀rọ̀ fún gbogbo olùgbé ipinle Osun pé kí wọ́n kó sọra fún ìwà ìwọra àti imọ tara ẹni nìkan.

Ifá tún bá Gómìnà Ìpínlẹ̀ Osun Ademola Adeleke sọ̀rọ̀ pé kí ó máa sọra, pé ojú lalakan fi n ṣọrí.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ẹni tí Kọmiṣanna fún eto àṣà àti Ibùdó Ìgbáfẹ́, Ojo Bamimole ṣoju fun sọ pé ìjọba tí ṣe tán láti gbé aṣa lárugẹ nipa fifọwọ sowọpọ pẹlu àwọn Oníṣẹ́se nipinle Osun.

Òní ni àyájọ́ ọjọ́ Ìṣẹ̀ṣe nílẹ̀ Yorùbá

Àwọn oníṣẹ̀ṣe

Gbogbo ogúnjọ́ oṣù Kẹjọ ọdọọdún jẹ́ àyájọ́ ọjọ́ tí àwọn oníṣẹ̀ṣe máa ń ṣàmì ayẹyẹ ọdún wọn ní gbogbo ilẹ̀ Káàárọ̀ o ò jíire.

Ó jẹ́ ọjọ́ tí àwọn oníṣẹ̀ṣe pátá yálà eléégún ni tàbí olórìṣà máa ń fi ṣe ayẹyẹ àṣekágbá láti fi ohunkóhun tí wọ́n bá ń sìn.

Ó máa ń jẹ́ àyájọ́ ijó, ẹ̀yẹ, àfihàn ìṣe àwọn oníṣẹ̀ṣe wọ̀nyí.

Ní àwọn ìpínlẹ̀ tó jẹ́ ti ilẹ̀ Yorùbá bíi Ogun, Osun, Eko, Ekiti, Ondo àti Oyo tó fi mọ́ àwọn apá ibìkan ní ìpínlẹ̀ Kwara àti Kogi ni ayẹyẹ yìí ti máa ń wáyé.

Yàtọ̀ sí àwọn tó wà ní Nàìjíríà, àwọn ọmọ Yorùbá tó jẹ́ oníṣẹ̀ṣe tó wà ní ilẹ̀ òkèrè náà máa ń darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn wọn láti ṣàmí ayájọ́ yìí.

Òní ọjọ́ ọjọ́ Àìkú, ọgúnjọ́ oṣù Kẹjọ, ọdún 2023 ni ọjọ́ Ìṣẹ̀ṣe ti ọdún yìí.

Lára àwọn ohun tó máa ń wáyé níbi ayẹyẹ náà ni àdúrà, ijó jíjó àti pípèsè ẹbọ fún àwọn òrìṣà.

Ṣaájú àkókò yìí ni àwọn oníṣẹ̀ṣe ti máa ń rọ ìjọba àpapọ̀ àtàwọn ìjọba ìpínlẹ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ tó jẹ́ ti Yorùbá láti máa ya ogúnjọ́ oṣù Kẹjọ sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe tí àwọn mùsùlùmí tàbí ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ bá ń ṣọdún.

Ẹ̀wẹ̀, ní ọdún 2013 ni gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Rauf Aregbesola gbé ìgbésẹ̀ akin láti kéde gbogbo ogúnjọ́ oṣù Kẹjọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ láti fi ààyè gba àwọn oníṣẹ̀ṣe láti ṣọdún wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìwé òfin Nàìjíríà.

Láti ọdún 2014 ni wọ́n sì ti ń lọ fún ìsinmi ní àyájọ́ ọjọ́ yìí ní ìpínlẹ̀ Osun, tí kò sì ní òṣìṣẹ́ ìjọba tàbí àwọn ilé ìfowópamọ́ àti ilé ẹ̀kọ́ lẹ́nu iṣẹ́.

Tí àyájọ́ ọjọ́ yìí bá bọ́ sí òpin ọ̀sẹ̀, ìjọba máa ń kéde ọjọ́ ìsinmi fún àwọn òṣìṣẹ́.

Ní báyìí, yàtọ̀ sí ìpínlẹ̀ Osun, ọ̀pọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ tọ jẹ́ ti ilẹ̀ Yorùbá ni àwọn náà ti ya ogúnjọ́ oṣù Kẹjọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́.

Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun àti Oyo náà ti buwọ́lu ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ ní àyájọ́ ọjọ́ Ìṣẹ̀ṣe láti fi gbé àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Yorùbá ga.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹjọ náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde ọjọ́ Ajé ọjọ́ Kọkànlélógún gẹ́gẹ́ bí ọja ìsinmi láti fi bá àwọn oníṣẹ̀ṣe ṣayẹyẹ tí yóò wáyé lọ́jọ́ Àìkú.

Bí ètò ọdún Ìṣẹ̀ṣe bá ṣe ń lọ káàkiri ilẹ̀ Yorùbá ni a ó máa mú wá fún-un yín.