Ọdún Ìṣẹ̀ṣe: Ogun, Oyo, Osun, Eko kéde Ọjọ́ Ajé gẹ́gẹ́ bi ọjọ́ ìsinmi

Àwọn oníṣẹ̀ṣe

Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ti kéde ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkànlélógún gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ láti fi ṣayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ Ìṣẹ̀ṣe ni àgbáyé.

Àtẹ̀jáde kan tí Kọmíṣọ́nà fétò ìròyìn ìpínlẹ̀ Osun, Kolapo Alimi fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ni gómìnà ti kéde bẹ́ẹ̀.

Nígbà tó ń kí àwọn oníṣẹ̀ṣe kú ayẹyẹ ọdún, gómìnà Adeleke pàrọwà síwọn láti lo àkókò ọdún náà láti fi gbàdúrà fún ìlọsíwájú ìpínlẹ̀ Osun àti orílẹ̀ èdè Nàijíríà lápapọ̀.

Adeleke ní ìjọba tó ń fẹ́ ìṣọ̀kan láàárín gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn ni òun ṣe kéde ìsinmi náà.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti kéde ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkànlélógún gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ láti fi ṣayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ Ìṣẹ̀ṣe ni àgbáyé.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí akọ̀wé ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo, Ọ̀jọ̀gbọ́n Olanike Adeyemo fi síta ni wọ́n ti kéde ọ̀rọ̀ náà.

Àtẹ̀jáde náà ní gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti buwọ́lù ú pé gbogbo ogúnjọ́ oṣù Kẹjọ ni wọn yóò máa yà sọ́tọ̀ láti fi ṣàmì àyájọ́ ọjọ́ Ìṣẹ̀ṣe ní ìpínlẹ̀ Oyo.

Adeyemo ni fún ìdí èyí ni ìjọba ṣe ya ọjọ́ Ajé fún ìsinmi nígbà tí ogúnjọ́ oṣù yìí ti bọ́ sí òpin ọ̀sẹ̀.

Bákan náà ló ní gómìnà rọ àwọn oníṣẹ̀ṣe láti lo àkókò ayẹyẹ ọdún náà láti fi gbàdúrà fun ìṣọ̀kan àti àlàáfíà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀.

Ọdún Ìṣẹ̀ṣe: Gómínà Dapọ Abiọdun kede Ọjọ́ Ajé, Mọnde gẹ́gẹ́ bi ọjọ́ ìsinmi

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti kede ọjọ Aje tii ṣe Mọnde gẹgẹ bi ọjọ ọlude fun gbogbo awọn araalu lati fi saami ayẹyẹ ayajọ ọdun iṣẹṣe.

Ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii ni Gomina Abiọdun sọ pe ọjọ Mọnde naa, iyẹn ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun ti a wa yii bi ọjọ isinmi fun gbogbo awọn oniṣẹṣe patapata.

Ṣaaju asiko yii ni gbogbo awọn oniṣẹṣe patapata lorileede Naijiria, paapaa nilẹ Yoruba ti n pe fun ogunjọ, oṣu kẹjọ, ọdọọdun gẹgẹ bi ọjọ ti wọn yoo maa ṣe ọdun iṣẹṣe, eyi ti wọn ti ya sọtọ tipẹtipẹ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Lekan Adeniran fi sita, Abiọdun gbe oriyin fun gbogbo awọn oniṣẹṣe patapata n’ipinlẹ Ogun fun ifọwọsowọpọ wọn, ati bi wọn ṣe ṣe ara wọn ni oṣuṣu-ọwọ.

O ni ipinnu naa ni lati bu ọwọ to tọ fun ẹsin abalaye ati mimu ki ibaṣepọ to dan mọnran wa laaarin awọn ẹlẹsin mẹtẹẹta to wa ni ipinlẹ naa.

Bakan naa ni Gomina Abiọdun tun fi erongba rẹ han si gbigbaruku ti ati bibu ọla fun gbogbo ẹsin patapata to wa ni ipinlẹ naa.

Siwaju sii lo parọwa si gbogbo awọn ẹlẹsin iṣẹṣe naa lati ṣajọyọ naa ni irọwọ-irọsẹ, ki wọn si yago fun awọn iwa to le da alaafia ipinlẹ naa laamu..

Ìṣẹṣe Day 2023: Ìpínlẹ̀ Eko kéde ọjọ́ Ajé gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹnu ìṣẹ̀ fún àwọn Òṣìṣẹ́ Ìjọba

Aworan Gomina Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Google

Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti darapọ mọ awọn gomina ipinlẹ Yoruba lati kede ọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun gẹgẹ bii ọjọ ìsinmi lẹnu isẹ fun awọn osisẹ ìjọba lati se ayajọ ọdun Ìṣẹṣe 2023.

Ayajọ Ọdun Ìṣẹṣe ti wọn ya sọ to nipinlẹ Eko lati ba awọn ẹlẹsin ibilẹ ṣe ayẹyẹ ọdun to ma waye ogunjọ oṣu kẹjọ ni ọdọọdun.

Eyi lo wa ninu atẹjade tí olori osisẹ nipinlẹ Ek, Hakeem Muri-Okunola buwọlu fun awọn akọroyin.

O fikun pe igbesẹ yii lo da le lori ileri ijoba Gomina Babajide Sanwo-Olu lati se atilẹyin fun awọn ẹlẹsin ibilẹ ati lati gbe asa ati ise Yoruba larugẹ nipinlẹ Eko.

Ipinlẹ Eko ti darapọ mọ ipinlẹ Osun, Ogun, Oyo lati kede ọjọ ìsinmi lẹnu isẹ fun ayajọ ọdun Ìṣẹṣe.

Ti a ko ba gbagbe, ṣíṣe ọdun Ìṣẹṣe yii lo ti fa ọpọlọpọ awuyewuye ati rogbodiyan niluu Ilorin to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara