‘Àwa oníṣẹ̀ṣe kìí ṣe oníṣẹ́ ibi’

Àwọn oníṣẹ̀ṣe

Gbogbo ẹgbẹ oniṣẹṣe ipinlẹ Oyo ti rọ awọn agbofinro àti awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati ye fi oju ti ko tọ wo awọn mọ.

Aarẹ Iṣẹṣe ipinlẹ Oyo, Olukunmi Omikemi ninu ọrọ rẹ nibi ayẹyẹ ọdun Iṣẹṣe ti ipinlẹ Oyo to waye ninu Gbongan Mapo ni Ibadan ṣalaye wi pe, ọpọlọpọ igba to jẹ pe ti nnkan buruku bá ti ṣẹlẹ ni wọn maa n ro o si awọn oniṣẹṣe

Omikemi ni ti awọn naa ba niṣe pẹlu gige ẹya ara eniyan tabi ogun owo ni wọn maa n ro o pe awọn ni awọn wa nidii rẹ.

O ni ọpọ igba ni awọn eeyan maa n na ìka aleebu si awọn lori nnkan ti awọn ko ni mọwọ mẹsẹ le lori, tó si rọ awọn ara ilu lati maa ṣe iwadii ṣaaju ki wọn to naka aleebu si awọn oniṣẹṣe.

Omikemi dupẹ lọwọ gomina ipinlẹ Oyo fun anfaani to fun awọn oniṣẹṣe ipinlẹ Ọyọ lọdun yii to si tun rọ gomina Makinde lati fun awọn oniṣẹṣe ni aaye ninu iṣejọba rẹ kì wọn le gbe Aṣa ati ẹka Igbafẹ larugẹ nipinlẹ Oyo.

Mogaji Fayemi Fakayode ninu idanilẹkọọ to ṣe nibi eto ọhun ṣalaye wi pe Iṣẹṣe ni orisun ohun gbogbo to nisẹ pẹlu iran Oduduwa.

Fayemi ṣalaye wi pe Iṣẹṣe jẹ okun to so gbogbo iran Yoruba pọ, ti o si maa n mu ki iṣọkan wa laarin ẹbi àti gbogbo eniyan lawujọ.

O ni nipasẹ Ọdun Iṣẹṣe ọrọ aje ilu yoo ru gọgọ sii nitori wi pe awọn eniyan maa n ra orisirisi nnkan to nisẹ pẹlu asa ati ise Yoruba, bẹẹ gẹgẹ ni awọn arinrin-ajo lati ilẹ okeere máa ń wọ inu ilu wa, tí wiwa wọn si maa n mu ọrọ ajẹ ilu gberu ni gbogbo ọna.

Kọmiṣọna ipinlẹ Oyo fun Asa ati ere Igbafẹ, Wasiu Olatunbosun nigba ti o n bá awọn oniṣẹṣe sọrọ tẹmpẹlẹ mọ wí pe Ipinlẹ Oyo yoo faye gba awọn oniṣeṣe nipinlẹ naa.

Olatunbosun ni Gomina Makinde ti ṣetan lati gbe aṣa ilẹ Yoruba larugẹ, o rọ wọn lati maṣe dakẹ nipa ṣiṣe iwure fun ipinlẹ Oyo ati orilẹ ede Naijiria lapapọ.

Olatunbosun ṣalaye wi pe gbogbo ileri ti gomina Makinde ṣe fun awọn oniṣeṣe nigba eto ipolongo ni ó ti musẹ, O ní pẹlu bi Gomina Ipinlẹ Oyo ti ṣe fọwọsi ogunjọ gẹgẹ bi ọjọ iṣẹṣẹ, wọn gbọdọ bawọn nibi ti wọn ti n da ilu ru.

O gba wọn niyanju lati maṣe jẹ ki ọdun egungun ọdọọdun mu ija tabi ariyanjiyan lọwọ.

O fi kun pe ijọba ti gbe eto kan kalẹ pe gbogbo egungun ipinlẹ Oyo yoo maa fi oruko silẹ ṣaaju ki wọn to jade ki wọn le mọ wi pe ipinlẹ Oyo ni aṣa ti gbile julọ.

Ẹ kéde ìsinmi fún àwa náà – Àwọn oníṣẹ̀ṣe ní ìpínlẹ̀ Ekiti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Oyebanji

Awọn oníṣẹṣ ni ipinlẹ Ekiti rawọ ẹ̀bẹ̀ si Gómìnà Oyebanji láti kéde Ogúnjọ́ oṣù kẹjọ ọdọọdún fún Ọdún ìṣẹ̀ṣe.

Agbarijọ awọn oniṣẹṣe ni ipinlẹ Ekiti ràwọ ẹ̀bẹ̀ si ìjọba ipinlẹ naa lábẹ́ àkóso gómìnà Abiodun Oyebanji láti sọ gbogbo ogúnjọ́́ oṣù kẹjọ ọdọọdún di òfin fún wọn láti máa ṣe ayajọ ọdún ìṣese.

Àwọn ónìṣese ni ipinlẹ Ekiti ni wọn ko ara wọn jọ sí agbègbè Falegan n’ilu Ado-Ekiti tí wọn sì bẹ̀rẹ̀ ètò àdúrà náà pẹ̀lú òbí, iyọ̀, omi, àti ọtí gẹgẹ bí ìṣe wọn ní ọdọọdún.

Oloye Alaba Fajuwon otùrà ọba ifá kìíní tí ó ṣáájú ètò àdúrà náà ṣàlàyé pàtàkì Ọdún iṣẹṣe pe o wa fun láti má jẹ ẹ kí àṣà ilẹ Yorùbá parun.

O ni ó tún jẹ ayajọ ti gbogbo àwọn ólórísá maa parapọ̀ sọkàn láti ṣe àjọyọ̀ Ọdún.

Wọn panupọ láti ṣe àdúrà fún orilẹ-ede Naijiria, ipinlẹ Ekiti, àwọn Ọba ìlú, ìjọba ìbílẹ̀ àti gbogbo ìlú tó wà ní Ekiti pé kí ara tú gbogbo ènìyàn pẹlu bi ọ̀wọ́n gogo epo bẹntiroolu ṣe n ba ọpọ finra.

Olóyè Awiṣẹ, Dauda Lawal àti Famuyibo Kayode to jẹ Ọba Ọlọja Ìṣẹṣe Àgbáyé ní wọn rawọ ẹ̀bẹ̀ si ìjọba ipinlẹ Ekiti lórúkọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ ónìṣese kaakiri àgbáyé pé kí wọ́n maa kede ọjọ isinmi fun awọn naa.

Wọn ni o yẹ ki ijọba Ekiti wo awokọṣe àwọn akẹgbẹ wọn ní ìpínlè Èkó, Ọ̀yọ́ àti Ọsun láti kéde Ogúnjọ ọjọ́ nínú osu kẹjọ ọdọọdún láti máa ṣe ayẹyẹ Ọdún ìṣẹṣe fún itẹsiwaju àṣà ilẹ Yoruba.

Nínú ẹ̀bẹ̀ wọn si gómìnà Abiodun Oyebanji ni wọn tun beere fún idasilẹ igbimọ oniṣẹṣe nínú ìṣejọba fún ìdàgbàsókè ipinlẹ Ekiti.

Lẹ́yìn àdúrà yii ni wọn bẹ̀rẹ̀ ètò gbogbo pẹ̀lú ijo àti ayọ, tí wọn sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Elédùmarè tó jẹ́ kí ojú wọn rí ọdún yii.