Ta ló ń dá ìwé àṣẹ Falana láti sójú ìdílé Adegoke dúró? Ohun táa mọ̀ rèé

Timothy Adegoke ati Femi Falana

Ijọba ipinlẹ Osun ti dahun si awuyewuye to n lọ nita lori pe wọn ko fẹ buwọlu iwe aṣẹ to gbe agbara fun agbẹjọro agba Femi Falana lati ṣoju idile Timothy Adegoke.

Adegoke ni akẹkọọ fasiti OAU ti wọn lawọn kan ṣeku pa nile itura ni ile Ife ti mọlẹbi rẹ si ti n beere fun idajọ ododo lori iku rẹ.

Ọrọ yi jẹyọ ninu atẹjade kan ti Oluwafemi Akande,kọmisana feto igbẹjọ ni Osun fi sita.

Agbẹnusọ Gomina Ismail Omipidan lo fi esi yi ṣọwọ loju opo rẹ ni Facebook.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ijọba ti buwọlu iwe aṣẹ yiati pe lọwọ bayii, ileeṣẹ agbẹjọro Femi Falana lo wa ni ikapa lati ṣẹjọ Timothy Adegoke.

Atẹjade naa fidi ọrọ mulẹ pe ati mọlẹbi Adegoke ati ọfisi Falana lo jijọ kọwe si ijọba lori ẹni ti yoo ṣe olupẹjọ lori ọrọ iku Timothy Adegoke.

”Ni ọjọ Kini oṣu Krin Femi Falana kọwe si ọfisi agbẹjọro agba ipinlẹ Osun ki wọn jẹki awọn ṣe olupẹjọ ninu ẹjọ yi.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Lẹyin igba naa awọn mọlẹbi oloogbe kọ lẹta tiwọn naa si agbẹjọro agba ti wọn fi beere iyọnda fun Femi Falana lati gba akoso igbẹjọ yi”

Agbẹjọro agba ati Minisita feto idajọ yi tẹsiwaju pe awọn ko jafira lati bẹrẹ iṣ lori lẹta yi tawọn si ti buwọlu ohun ti mọlẹbi ati Falana beere fun.

”Ọfisi agbẹjọro agba Falana ti gba iwe aṣ lati ọdọ wa to fun wọn niyọnda ni kiakia lati jẹ olupẹjọ ninu ẹjọ yi.”

” Labẹ ofin Naijiria lonii, agbẹjọro agba Falana lo wa ni ikapa gẹg bi olupẹjọ ninu ẹjọ Timothy Adegoke.”

Ki lo fa fakinfa lori ẹni ti yoo ṣoju fun Adegoke ati mọlẹbi rẹ?

Ileeṣẹ ọlọpaa lo kọkọ bẹrẹ igbẹjọ Timothy Adegoke gẹgẹ bi olupẹjọ niile ẹjọ giga Abuja loṣu Kini ọdun yi.

Ko pe ni oṣu keji ni wọn yọwọ ninu ẹjọ yi lẹyin ti agbẹjọro Femi Falana SAN kọwe si ileeṣẹ ọlọpaa pe ki wọn gbe ẹjọ naa lọ si Osun ti wn ti daran naa.

Ni ọjọ Kẹtadinlogun oṣu Keji ọdun 2022 ni wọn gbe iwe ipẹjọ lọ sile ẹjọ giga ni Oshogbo.

Bi ẹjọ ṣe pada si Osogbo, Falana kọ iwe si agbẹjọro agba ipinlẹ Osun pe ki wọn jẹ ki oun ṣoju mọlẹbi Timothy Adegoke.

Ọrọ yi ṣe diẹ ko to niyanju tawọn iwe iroyin kan to kan si agbẹjọro agba Oluwafemi Akande si sọ pe oun n duro de aṣẹ lati ọd Gomina Oyetoila ni lori ọrọ ọhun.

Idi iduro de aṣẹ yi lawọn ololufẹ ati mọlẹbi to fi mọ oniroyin kan to fi ilu Ibadan ṣe ibujoko ke gbajare si ijọba pe ki wọn ma joko lori aṣẹ yi titi laelae.

Aṣẹyinwa aṣẹyinbọ ni esi wa pada jade lọdọ agbẹjọro agba to tun jẹ Minisita feto idajọ pe Falana lo laṣẹ bayii lati ṣoju ipẹjọ fun molẹbi Adegoke.